Jẹ́ Kí N “Mu Díẹ̀ Sí I”
Jẹ́ Kí N “Mu Díẹ̀ Sí I”
ALLEN bẹ̀rẹ̀ sí í mu ọtí àmujù nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá. a Òun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ń ṣeré nínú igbó, wọ́n máa ń ṣe bí àwọn tí wọ́n ń wò nínú fíìmù. Allen àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ń mutí bíi tàwọn tí wọ́n ń wò nínú fíìmù bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ọtí gidi làwọn yẹn ń mu.
Nígbà tí Tony dọmọ ogójì [40] ọdún, ọtí tó ń mu bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i látorí ìfe kan tàbí méjì ní alaalẹ́ dórí ife márùn-ún tàbí mẹ́fà. Nígbà tó sì yá, kò mọ iye tó ń mu lóòjọ́ mọ́.
Allen ní káwọn èèyàn ran òun lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ọtí àmujù. Àmọ́ Tony ní tiẹ̀ kò gba ìrànwọ́ táwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún un. Tony ti kú lọ́dún bíi mélòó kan sẹ́yìn nínú jàǹbá ọkọ̀ lẹ́yìn tó ti mutí yó, àmọ́ Allen ní tiẹ̀ ṣì wà láàyè lónìí láti sọ ìrírí ara rẹ̀.
Bí ẹnì kan bá tiẹ̀ mutí yó pàápàá, àmujù rẹ̀ yìí kò lè ṣàì nípa lórí àwọn ẹlòmíì, àbájáde rẹ̀ sì máa ń burú jáì lọ́pọ̀ ìgbà. b Ọtí àmujù máa ń fa káwọn èèyàn máa bú ara wọn, ó ń dá ìjà sílẹ̀, ó ń fa ìwà ipá, ó ń yọrí sí ìpànìyàn, ó máa ń fa jàǹbá ọkọ̀ àti ìfarapa níbi iṣẹ́, ó sì tún máa ń fa onírúurú àìsàn. Yàtọ̀ sí ẹ̀dùn ọkàn tí ọtí àmujù máa ń fà fáwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, fáwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọmọ, ó tún máa ń ná àwọn èèyàn ní owó gọbọi lọ́dọọdún.
Àjọ Ìlera Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, “kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń mutí lójoojúmọ́ ló níṣòro ọtí mímu, kì í sì í ṣe gbogbo àwọn tó níṣòro ọtí mímu ló ń mutí lójoojúmọ́.” Ọ̀pọ̀ tí kì í ṣe ọ̀mùtí pàápàá ti dẹni tó ń mutí àmujù láìmọ̀. Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni àwọn kan máa ń mutí, àmọ́ iye tí wọ́n máa ń mu lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀hún ju kí wọ́n mutí nígbà márùn-ún lọ.
Tó o bá fẹ́ mutí, báwo lo ṣe máa mọ̀ bóyá èyí tó o fẹ́ mu ti pọ̀ jù? Báwo lo ṣe lè mọ̀ pé kò yẹ “kó o mu díẹ̀ sí i”? (Òwe 23:29, 30, Bíbélì Contemporary English Version) Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí máa jẹ́ ká mọ ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ lórí ọ̀ràn yìí.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
b Òótọ́ ni pé iye ọkùnrin tó ń mutí àmujù máa ń fi ìlọ́po mẹ́rin ju obìnrin lọ, àmọ́ àwọn ìlànà tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí wúlò fáwọn obìnrin pẹ̀lú.