Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Ọtí Mímu?
Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Ọtí Mímu?
OHUN rere ni Ẹlẹ́dàá wa ń fẹ́ fún wa, kò ka mímú ọtí níwọ̀ntúnwọ̀nsì léèwọ̀. a Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fún èèyàn ní “ọti-waini ti imu inu enia dùn, ati ororo ti imu oju rẹ̀ dan, ati onjẹ ti imu enia li aiya le.” (Orin Dafidi 104:15, Bibeli Mimọ) Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jésù Kristi mú kí ayẹyẹ ìgbéyàwó kan lárinrin, ó sọ omi di “wáìnì àtàtà.”—Jòhánù 2:3-10.
Ó ṣe kedere pé Ẹlẹ́dàá wa mọ bí ọtí ṣe máa ń nípa lórí bí ara àti ọpọlọ wa ṣe ń ṣiṣẹ́. Nínú Bíbélì, Bàbá wa ọ̀run ‘kọ́ wa ká lè ṣe ara wa láǹfààní,’ ó sì kìlọ̀ fún wa gan-an pé ká má ṣe mu ọtí lámujù. (Aísáyà 48:17) Wo àwọn ìkìlọ̀ tó sojú abẹ níkòó yìí:
“Ẹ má ṣe máa mu wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí ìwà wọ̀bìà wà.” (Éfésù 5:18) “Kì í ṣe . . . àwọn ọ̀mùtípara . . . ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bẹnu àtẹ́ lu “mímu àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo, àti nǹkan báwọ̀nyí.”—Gálátíà 5:19-21.
Jẹ́ ká wá gbé díẹ̀ lára àwọn ewu tó wà nínú ọtí àmujù yẹ̀ wò.
Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Ọtí Àmujù
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọtí lè ṣe ara lóore, ó ní àwọn èròjà kan tó lágbára láti yí ọ̀nà tí ara àti ọpọlọ wa ń gbà ṣiṣẹ́ pa dà. Àmujù ọtí lè fa èyíkéyìí nínú àwọn ìṣòro tá a fẹ́ sọ yìí:
Ọtí àmujù máa ń da ọpọlọ èèyàn rú, kì í jẹ́ kéèyàn lè ronú bó ti tọ́. (Òwe 23:33) Allen, tó jẹ́ ọ̀mùtí tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí ṣàlàyé pé: “Ìmukúmu ọtí kì í ṣe àìsàn inú ara, inú ìrònú àti ìṣe èèyàn ni ó ti ń wá. Èyí kì í sì í jẹ́ kéèyàn kọbi ara sí ìpalára tó lè ṣe fáwọn ẹlòmíì.”
Ọtí àmujù tún lè mú kéèyàn gbé ìtìjú tà. Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ pé: “Wáìnì àti wáìnì dídùn ni Hóséà 4:11) Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Téèyàn bá ti mutí yó, àwọn ìrònú àtàwọn ohun téèyàn kì í gbà láyè tẹ́lẹ̀ lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í dà bí ohun tó tọ́ tàbí kéèyàn fàyè gbà á pàápàá. Ó sì tún lè ṣàkóbá fún ìpinnu tá a ti ṣe láti ṣe ohun tó tọ́. Ọtí àmujù lè mú ká hùwà tí kò yẹ ọmọlúwàbí, ìyẹn sì lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́.
ohun tí ń gba ète rere kúrò.” (Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ John, lọ́jọ́ kan, òun àti ìyàwó rẹ̀ jọ fa ọ̀rọ̀ kan, lẹ́yìn náà ó fìbínú gba ilé ọtí lọ. Lẹ́yìn tó ti mu ọtí bíi mélòó kan láti fi pàrònú rẹ́, obìnrin kan wá bá a. Lẹ́yìn tó sì tún mu ọtí díẹ̀ sí i, John bá obìnrin náà lọ, ó sì bá a lò pọ̀. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, John wá kábàámọ̀ gidigidi torí pé ọtí tó mu ti mú kó gbé ìtìjú tà, tó sì wá ṣe ohun tí kò rò tẹ́lẹ̀ láti ṣe.
Ọtí àmujù lè mú kéèyàn máa sọ̀rọ̀ kó sì máa hùwà láìníjàánu. Bíbélì béèrè pé: “Tani o ni ibanujẹ? Tani ó ni ìjà? Tani o ni asọ̀? Awọn ti o duro pẹ́ nibi ọti-waini.” (Owe 23:29, 30, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Àmujù ọtí lè máa ṣe èèyàn bí ẹni pé “ó dùbúlẹ̀ sí àárín òkun, àní bí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ sí orí òpó ìgbòkun ọkọ̀.” (Owe 23:34) Ẹni tó ti mutí yó lè jí kó sì rí i pé “òun ti fara pa yánnayànna tí kò sì ní rántí bó ṣe ṣẹlẹ̀.”—Òwe 23:35, Bíbélì The Contemporary English Version.
Ọtí àmujù lè ṣàkóbá fún ìlera. “Nikẹhin [ọtí] a buniṣán bi ejò, a si bunijẹ bi paramọ́lẹ̀.” (Owe 23:32, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Àwọn onímọ̀ ìṣègùn jẹ́rìí sí ọgbọ́n tó wà nínú òwe àtijọ́ yìí. Májèlé tó lágbára ni ọtí máa ń dà téèyàn bá ti mu ún ní àmujù, ó sì lè yọrí sí oríṣiríṣi àrùn jẹjẹrẹ, àrùn mẹ́dọ̀wú, ìsúnkì ẹ̀dọ̀, ó lè mú kí àmọ́ tó wà lára ìfun wú, ó máa ń fa oríṣi àrùn ìtọ̀ ṣúgà kan, ó tún máa ń fa àbùkù ara fún àwọn ọmọ látinú oyún, ó sì ń fa àrùn rọpárọsẹ̀ tàbí kí ọkàn èèyàn máa dá kú. Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára jàǹbá tí àmujù ọtí máa ń fà. Béèyàn bá tiẹ̀ mutí yó lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo pàápàá, ó lè mú kéèyàn dá kú tàbí kó kú pátápátá. Àmọ́, ewu tó burú jù lọ tí ọtí àmujù ń fà kò sí lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé ìmọ̀ ìṣègùn kankan.
Ewu tó burú jù lọ. Béèyàn kì í bá mutí yó pàápàá, mímu ọtí lọ́nà tí kò wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì lè ṣàkóbá fún àjọṣe èèyàn pẹ̀lú Ọlọ́run. Kedere ni Bíbélì sọ pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ kí wọ́n lè máa wá Aísáyà 5:11, 12.
kìkì ọtí tí ń pani kiri, àwọn tí ń dúró pẹ́ títí di òkùnkùn alẹ́ tí ó fi jẹ́ pé wáìnì mú wọn gbiná!” Kí nìdí? Aísáyà ṣàlàyé ewu tẹ̀mí tí mímu ọtí lọ́nà tí kò wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì lè fà, ó ní: “Ìgbòkègbodò Jèhófà ni wọn kò bojú wò, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sì ni wọn kò rí.”—Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká “má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri.” (Òwe 23:20) Bíbélì kìlọ̀ fáwọn àgbà obìnrin pé kí wọ́n má ṣe di “ẹrú fún ọ̀pọ̀ wáìnì.” (Títù 2:3) Kí nìdí? Ìdí ni pé, díẹ̀díẹ̀ làwọn èèyàn máa ń fi kún ìwọ̀n ọtí tí wọ́n ń mu láìmọ̀. Tó bá sì yá, ọ̀mùtí á sọ pé, “Ìgbà wo ni èmi yóò jí? Èmi yóò ṣì túbọ̀ máa wá a kiri.” (Òwe 23:35) Ọtí ti di bárakú fún ọ̀mùtí tí ojú rẹ̀ kì í dá àyàfi tó bá mu ọtí díẹ̀ sí i láàárọ̀ kí èyí tó ti mu lánàá lè dá lójú rẹ̀.
Bíbélì kìlọ̀ pé gbogbo àwọn tó bá ń lọ́wọ́ nínú “àṣejù nídìí wáìnì, àwọn àríyá aláriwo, ìfagagbága ọtí mímu . . . [máa] jíhìn fún ẹni tí ó ti múra tán láti ṣèdájọ́ àwọn tí ó wà láàyè àti àwọn tí ó ti kú.” (1 Pétérù 4:3, 5) Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò líle koko tá a wà yìí, ó kìlọ̀ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ [Jèhófà] yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.”—Lúùkù 21:34, 35.
Àmọ́, kí lẹni tí kì í mutí níwọ̀ntúnwọ̀nsì lè ṣe kó má bàa di ‘ẹni tó ń mutí yó kẹ́ri’?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bíà, ẹmu, wáìnì àtàwọn ọtí líle míì, irú bí ògógóró ni àpilẹ̀kọ yìí pè ní “ọtí.”
[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Ọtí àmujù lè fa onírúurú ìṣòro