Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Gbogbo Èèyàn Rere Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?

Ṣé Gbogbo Èèyàn Rere Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?

Ṣé Gbogbo Èèyàn Rere Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?

LẸ́YÌN oúnjẹ tí Jésù jẹ pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n pa á, ó ṣèlérí fún wọn pé òun máa fún wọn ní ibì kan ní ọ̀run tí yóò jẹ́ èrè wọn. Ó sọ pé: “Nínú ilé Baba mi, ọ̀pọ̀ ibùjókòó ni ń bẹ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi ì bá ti sọ fún yín, nítorí pé mo ń bá ọ̀nà mi lọ láti pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín.” (Jòhánù 14:2) Kí nìdí tí Jésù fi fẹ́ fún wọn ní ibì kan lọ́run? Kí ni wọ́n máa ṣe níbẹ̀?

Iṣẹ́ pàtàkì kan ni Jésù ní lọ́kàn láti gbé fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi; èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan.” (Lúùkù 22:28, 29) Ọlọ́run ti ṣèlérí pé Jésù ni Ọba tí yóò fún aráyé ní ohun pàtàkì tí wọ́n nílò jù lọ, ìyẹn ìjọba rere. Jésù máa gba àwọn èèyàn lọ́wọ́ ìpọ́njú, ó sì máa pa àwọn tó ń pọ́n wọn lójú run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba rẹ̀ máa wà títí “dé òpin ilẹ̀ ayé,” ọ̀run ni ìtẹ́ Jésù máa wà.—Sáàmù 72:4, 8; Dáníẹ́lì 7:13, 14.

Àmọ́ ṣá o, Jésù kò ní dá ṣàkóso. Nítorí náà, ó ṣèlérí láti fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní ibì kan ní ọ̀run. Àwọn ló kọ́kọ́ yàn láti jẹ́ ara àwọn tó máa “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.”—Ìṣípayá 5:10.

Àwọn mélòó ló ń lọ sọ́run? Gẹ́gẹ́ bó ti ṣe máa ń rí nínú ìjọba èèyàn, àwọn tó máa jẹ́ alákòóso Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run máa kéré níye sáwọn tí wọ́n máa ṣàkóso lé lórí. Jésù sọ fáwọn tí wọ́n jọ máa ṣàkóso pé: “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nítorí pé Baba yín ti tẹ́wọ́ gba fífi ìjọba náà fún yín.” (Lúùkù 12:32) “Agbo kékeré” yẹn ni iye rẹ̀ máa wá jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]. (Ìṣípayá 14:1) Iye yẹn kéré gan-an tá a bá fi wé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn olóòótọ́ tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.—Ìṣípayá 21:4.

Nítorí náà, kì í ṣe gbogbo èèyàn rere ló máa lọ sọ́run. Àpọ́sítélì Pétérù sọ kedere nípa Dáfídì tó jẹ́ Ọba rere, ó ní: “Dáfídì kò gòkè lọ sí ọ̀run.” (Ìṣe 2:34) Èèyàn rere ni Jòhánù Oníbatisí. Síbẹ̀, Jésù sọ pé kò ní láǹfààní láti lọ sọ́run kó lè ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba. Jésù sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, láàárín àwọn tí obìnrin bí, a kò tíì gbé ẹnì kan dìde tí ó tóbi ju Jòhánù Oníbatisí lọ; ṣùgbọ́n ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹni tí ó kéré jù nínú ìjọba ọ̀run tóbi jù ú.”—Mátíù 11:11.

Ṣé O Máa Rí Èrè Tó Wà Fáwọn Èèyàn Rere Gbà?

Kí lèèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó bàa lè gba èrè gbígbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé? Jésù sọ pé: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Kíyè sí i pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fún ayé ló mú kó fẹ́ fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun, àmọ́ àwọn tó ń “lo ìgbàgbọ́” nìkan ló máa rí èrè náà gbà.

Ìmọ̀ pípéye ló lè mú kéèyàn nígbàgbọ́. (Jòhánù 17:3) Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ láti mọ púpọ̀ nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún aráyé, ìyẹn á fi hàn pé o jẹ́ èèyàn rere. Jẹ́ kí ìgbàgbọ́ nínú ohun tó o kọ́ mú ẹ ṣe ohun tó yẹ. Wàá sì láǹfààní láti ní ìyè àìnípẹ̀kun.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Kí Ni Bíbélì Sọ?

Ìbéèrè:

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn rere tí wọ́n bá kú?

Ìdáhùn:

“Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.”ONÍWÀÁSÙ 9:5.

Ìbéèrè:

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn rere lọ́jọ́ iwájú?

Ìdáhùn:

“Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù] wọn yóò sì jáde wá.”JÒHÁNÙ 5:28, 29.

Ìbéèrè:

Ibo ni ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn rere máa gbé?

Ìdáhùn:

“Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, Wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”SÁÀMÙ 37:29.