Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Rán Àwọn Míṣọ́nnárì Lọ sí “Apá Ibi Jíjìnnà Jù Lọ ní Ilẹ̀ Ayé”

A Rán Àwọn Míṣọ́nnárì Lọ sí “Apá Ibi Jíjìnnà Jù Lọ ní Ilẹ̀ Ayé”

Ayẹyẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Kíláàsì Kẹtàdínláàádóje Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

A Rán Àwọn Míṣọ́nnárì Lọ sí “Apá Ibi Jíjìnnà Jù Lọ ní Ilẹ̀ Ayé”

JÉSÙ pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti jẹ́ ẹlẹ́rìí òun “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Ọwọ́ pàtàkì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú àṣẹ yìí.

Ó ti lé ní ọdún márùndínláàádọ́rin [65] táwọn míṣọ́nnárì tó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè tó lé ní igba [200]. Àwọn òjíṣẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56] míì tí wọ́n ti nírìírí nínú iṣẹ́ ìwàásù ṣe ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege lọ́jọ́ Saturday, September 12, 2009, lẹ́yìn tí wọ́n ti lo oṣù márùn-ún láti fi gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ míṣọ́nnárì tó wà ní Patterson, New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Agbára Tí Ojú Inú Rẹ Ní

Arákùnrin Stephen Lett tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó tún jẹ́ alága ayẹyẹ náà, bá kíláàsì náà sọ̀rọ̀. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Lo Ojú Inú Rẹ Lọ́nà Tó Dáa.” Ó sọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà nípa ọ̀nà mẹ́rin tí wọn kò gbọ́dọ̀ gbà lo ojú inú wọn. Ọ̀nà mẹ́ta àkọ́kọ́ tó sọ rèé: (1) Má ṣe fojú inú wò ó pé ohun ìní tara lè fúnni láàbò tó máa wà pẹ́ títí; (2) má ṣe fojú inú wo ṣíṣe ìṣekúṣe; àti (3) yẹra fún àníyàn àṣejù, má sì máa fojú inú wò ó pé ọjọ́ ọ̀la mà lè burú. (Òwe 18:11; Mátíù 5:28; 6:34) Arákùnrin Lett sọ̀rọ̀ lórí kókó kẹta pé, ẹni tó ń ṣàníyàn àṣejù máa ń kó àníyàn ti àná àti ti ọ̀la, à wá kó gbogbo ẹ̀ pa pọ̀ mọ́ tòní. Ó sọ pé: “Ẹrù yẹn á ti wúwo jù.” Lẹ́yìn náà, ó sọ ọ̀nà kẹrin, ó ní (4) kí wọ́n ṣọ́ra kí wọ́n má ṣe máa fojú inú wò ó pé ìgbésí ayé wọn kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì dára ju ti ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà lọ. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á mú kí wọ́n pàdánù ayọ̀ wọn níbi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn wọ́n sí.

Arákùnrin Lett wá gba kíláàsì náà níyànjú láti lo agbára ojú inú wọn ní ọ̀nà mẹ́rin tó dára. Ó sọ pé: (1) Fojú inú rẹ rí nǹkan tó lè ṣàkóbá fún ìlera rẹ àtèyí tó lè ba àjọṣe ìwọ àti Ọlọ́run jẹ́; (2) fojú inú rẹ wo ohun tó ò ń kà nínú Bíbélì, kó o sì wò ó pé o wà níbi tí nǹkan náà ti ń ṣẹlẹ̀; (3) fojú inú rẹ wò ó pé ẹnì kọ̀ọ̀kan tó ò ń wàásù fún níbi tí wọ́n yàn ẹ́ sí máa di olùjọsìn Jèhófà; àti (4) pé kó o ní ẹ̀mí ìfọ̀ràn ro ara ẹni wò, kó o máa fojú inú wò ó pé ìwọ ló wà nípò àwọn tó ò ń wàásù fún.—Òwe 22:3.

Àǹfààní Dídá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́

Arákùnrin David Splane tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Nǹkan wọ̀nyí ni kí o fi lé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́wọ́,” èyí tó fà yọ látinú 2 Tímótì 2:2. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún Tímótì ní ìtọ́ni láti dá àwọn olùṣòtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ohun tó ní lọ́kàn ni pé kì í ṣe pé kí Tímótì fìdí òtítọ́ múlẹ̀ lọ́kàn wọn nìkan ni, àmọ́ kó tún gbà wọ́n níyànjú láti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ fún kíláàsì náà pé a nílò àwọn ọkùnrin tó máa mú ipò iwájú nínú ìgbòkègbodò Kristẹni. Báwo la ṣe máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, ìgbà wo la sì máa ṣe é? Arákùnrin Splane gba àwọn míṣọ́nnárì yìí níyànjú láti bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn ọkùnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ láti ìgbà tí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Báwo gan-an làwọn míṣọ́nnárì ṣe lè dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè jẹ́ olùṣòtítọ́ táwọn ẹlòmíì á máa wo àpẹẹrẹ wọn? Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe é. Ó ní, àwọn míṣọ́nnárì ní láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọ́n máa múra sílẹ̀ fún ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n ń kọ́. Lẹ́yìn náà, nígbà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé ìjọ, wọ́n ní láti mọ bá a ṣe ń múra àwọn ọ̀rọ̀ sílẹ̀ látinú ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì tá a máa jíròrò nípàdé. Arákùnrin Splane sọ pé, “bí ẹnì kan kò bá lè dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò ní lè kọ́ àwọn ẹlòmíì.” Ó tún sọ pé àwọn míṣọ́nnárì lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti tètè máa dé sípàdé, kí wọ́n máa fowó ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn, kí wọ́n sì máa ṣègbọràn sáwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ Ọlọ́run. Ó sọ pé ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà kọ́ wọn làwọn ẹ̀kọ́ yìí ni pé káwọn míṣọ́nnárì fúnra wọn fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀.

Àǹfààní Jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí

Arákùnrin Guy Pierce tóun náà jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí náà sọ̀rọ̀, ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ‘Ẹ Ó Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Mi,’ èyí tó dá lórí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Ìṣe 1:8. Ó rán kíláàsì náà létí pé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pàdánù àǹfààní jíjẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà. Ọlọ́run wá gbé àǹfààní náà fún orílẹ̀-èdè táá máa mú èso Ìjọba náà jáde. (Mátíù 21:43) Ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló wá di orílẹ̀-èdè náà. Olùbánisọ̀rọ̀ náà wá fa ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù yọ pé “orílẹ̀-èdè mímọ́” ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yóò máa “polongo káàkiri” nípa àwọn ìtayọlọ́lá Jèhófà. (1 Pétérù 2:6-9) Nítorí náà, Jésù kò sọ pé àwọn Kristẹni máa jẹ́ ẹlẹ́rìí òun nìkan, tí wọn ò sì ní jẹ́ ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Ó ṣe tán “Ẹlẹ́rìí Aṣeégbíyèlé” ni Bíbélì pe Jésù. (Ìṣípayá 1:5; 3:14) Jésù ló gbawájú jù lọ nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun sì ni àwòṣe tá a ó máa tẹ̀ lé.—1 Pétérù 2:21.

Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ fún kíláàsì náà pé, ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Ìṣe 1:8 ti wá ní ìtúmọ̀ tó gbòòrò gan-an lóde òní. Kí nìdí? Ìdí ni pé, apá pàtàkì kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìṣípayá 11:15 ti nímùúṣẹ! A ti fìdí Ìjọba Ọlọ́run tí Mèsáyà yóò ṣàkóso múlẹ̀. A ti rí i ní báyìí pé a ti ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà “dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Arákùnrin Pierce tẹnu mọ́ ọn pé iṣẹ́ ìwàásù nípa Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ ni àwọn míṣọ́nnárì ń ṣe, kì í ṣé ìwàásù nípa ara wọn tàbí ìgbésí ayé tí wọ́n gbé tẹ́lẹ̀, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn àti orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá. Ó gba kíláàsì náà níyànjú láti kọ́ “ọ̀pọ̀ èèyàn bó ba ṣe lè pọ̀ tó ní àkókò tó ṣẹ́ kù yìí.”

Àwọn Kókò Míì Nínú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà

Arákùnrin Alex Reinmueller, tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tó sọ pé “Jèhófà Yóò Fún Ẹ Nígboyà.” Ó sọ pé, bí àwọn míṣọ́nnárì bá gbára lé agbára Jèhófà, yóò jẹ́ kí wọ́n mọ ibi tí agbára wọ́n mọ, kí wọ́n mọ kùdìẹ̀-kudiẹ wọn, á sì jẹ́ kí wọ́n lè borí ìbẹ̀rù wọn kí wọ́n sì lè sìn ín lọ́nà tó dára jù lọ.

Arákùnrin Sam Roberson àti William Samuelson tí wọ́n jẹ́ olùkọ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run tún bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ̀rọ̀. Arákùnrin Roberson sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Mo Wà Pẹ̀lú Rẹ,” tó dá lórí ìwé Aísáyà 41:10. Ó sọ pé àwọn míṣọ́nnárì yóò ní ayọ̀ tó pọ̀. Wọ́n yóò sì ní ìṣòro pẹ̀lú. Wọ́n á lè fara dà á tí wọ́n bá fara wé Dáfídì tó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Bàbá rẹ̀ onífẹ̀ẹ́. (Sáàmù 34:4, 6, 17, 19)Nínú àsọyé tí Arákùnrin Samuelson sọ, ó tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ káwọn míṣọ́nnárì máa lo agbára ìmọnúúrò wọn nìṣó. Ó ní, àwọn tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ kò ní máa bara jẹ́ nígbà táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ wọn láìdáa, wọn ò sì ní tètè máa bínú pé ẹnì kan ṣẹ àwọn.—Òwe 2:10, 11.

Arákùnrin Jim Mantz tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn arákùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, ọ̀kan láti orílẹ̀-èdè Georgia, èkejì láti ilẹ̀ Honduras, ó sì tún fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu arákùnrin kan tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-èdè Tajikistan. Àwọn arákùnrin onírìírí wọ̀nyí fún àwọn míṣọ́nnárì nímọ̀ràn lórí bí wọ́n á ṣe sọ àwọn tó fẹ́ máa ṣàtakò dọ̀rẹ́ wọn nípa fífi “ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:21) Arákùnrin Mark Noumair, tóun náà jẹ́ olùkọ́ fún kíláàsì náà sọ̀rọ̀ tó ń tani jí nípa ìrírí táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní sáà tí wọ́n ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń múni ronú jinlẹ̀, ìyẹn “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣèrànwọ́?”

Alága ayẹyẹ náà parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà nípa fífa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé orin tuntun tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Yóò Di Tuntun.” Gbogbo ẹgbẹ̀rún mẹ́fà, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé mẹ́sàn-án [6,509] èèyàn tó wá síbẹ̀ pa dà lọ pẹ̀lú ìpinnu tó lágbára pé àwọn á máa jẹ́rìí nípa Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ nìṣó “dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”

[Àtẹ ìsọfúnni/​Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 31]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ

8 Iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá

56 iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́

28 iye àwọn tọkọtaya

33.6 ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn

18.3 ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti ṣèrìbọmi

13.6 ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún

[Àwòrán ilẹ̀]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

A rán kíláàsì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege yìí lọ sí orílẹ̀-èdè méjìlélógún tó wà nísàlẹ̀ yìí

IBI TÁ A RÁN ÀWỌN MÍṢỌ́NNÁRÌ LỌ

JÀMÁÍKÀ

HAITI

NICARAGUA

COSTA RICA

PANAMA

CURAÇAO

GUYANA

PERU

BÒLÍFÍÀ

PARAGUAY

CHILE

MOLDOVA

SERBIA

ALIBÉNÍÀ

CÔTE D’IVOIRE

KÓŃGÒ, ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA

UGANDA

BÙRÚŃDÌ

TANZANIA

MÒSÁŃBÍÌKÌ

NEPAL

KÀǸBÓDÍÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Kíláàsì Kẹtàdínláàádóje Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, ńṣe la to nọ́ńbà ìlà kọ̀ọ̀kan láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Marshall, T.; Prudent, L.; Mashburn, A.; Rosenström, S.; Testa, A.; Takeyama, M.; Sisk, M.

(2) Grooms, K.; Miura, S.; Camacho, M.; Rozas, S.; Burch, M.; Meza, I.; Young, G.; Geraghty, S.

(3) Bonilla, C.; Knaller, D.; Parrales, R.; Hotti, S.; Takada, A.; Tournade, M.; Sopel, C.

(4) Miura, Y.; Parrales, K.; Prudent, K.; Colburn, S.; Willis, L.; Vääränen, A.; Sisk, B.; Takada, R.

(5) Grooms, J.; Vääränen, M.; Geraghty, B.; Stackhouse, R.; Wilson, A.; Bonell, E.; Camacho, D.; Meza, R.; Bonell, M.

(6) Takeyama, S.; Testa, G.; Colburn, T.; Mashburn, C.; Willis, W.; Tournade, L.; Burch, J.; Stackhouse, J.

(7) Wilson, J.; Young, J.; Marshall, E.; Rozas, M.; Knaller, J.; Hotti, N.; Rosenström, A.; Sopel, J.; Bonilla, O.