Bó O Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro Àárín Ìwọ àti Àna Rẹ
Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Bó O Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro Àárín Ìwọ àti Àna Rẹ
Jenny a sọ pé: Ara kì í ti màmá Ryan, ọkọ mi, láti sọ̀rọ̀ burúkú sí mi. Àwọn òbí tèmi náà sì máa ń gbé e gbóná pẹ̀lú Ryan ọkọ mi tá a bá lọ sọ́dọ̀ wọn. Kódà, mi ò tíì rí i káwọn òbí mi hu irú ìwà àìlọ́wọ̀ bẹ́ẹ̀ sí ẹnì kankan rí! Wàhálà ni lílọ kí àwọn òbí wa máa ń dá sílẹ̀ fún wa.
Ryan sọ pé: Lójú màmá mi, kò sẹ́ni tó kúnjú ìwọ̀n láti fẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, ìyẹn ló fi jẹ́ pé látọjọ́ tó ti rí Jenny ni kò ti nífẹ̀ẹ́ sí i. Ojú táwọn òbí Jenny náà sì fi ń wò mí ni pé mi ò kúnjú ìwọ̀n, ìgbà gbogbo ni wọ́n ń fojú bù mí kù. Ìṣòro tó tún ń ti ibẹ̀ wá ni pé lẹ́yìn táwọn nǹkan yìí bá ti ṣẹlẹ̀, ńṣe ni kálukú wa máa ń gbèjà àwọn òbí tiẹ̀, tá a ó sì máa dá ara wa lẹ́bi.
ÀWỌN aláwàdà lè máa fi ìṣòro tó máa ń wáyé láàárín lọ́kọláya àti àna wọn ṣàwàdà, àmọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ àwàdà rárá. Ìyàwó kan tó ń jẹ́ Reena lórílẹ̀-èdè Íńdíà, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún ni ìyá ọkọ mi fi tojú bọ ọ̀rọ̀ èmi àti ọkọ mi. Ìgbà míì tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé ọkọ mi ni mo máa ń fìkanra mọ́ torí pé mi ò lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí ìyá rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì dà bíi pé kò mọ èyí tí ì bá ṣe, bóyá èmi ìyàwó rẹ̀ ló yẹ kó hùwà tó dáa sí tàbí ìyá rẹ̀.”
Kí nìdí táwọn àna kan fi máa ń tojú bọ ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ wọn tó ti ṣègbéyàwó? Jenny tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ sọ ohun kan tó lè fà á, ó ní: “Ọkàn wọn lè má balẹ̀ tí wọ́n bá rí i pé ẹnì kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ dàgbà tí kò sì tíì nírìírí lá máa tọ́jú ọmọbìnrin tàbí ọmọkùnrin wọ́n.” Ọ̀gbẹ́ni Dilip tó jẹ́ ọkọ Reena tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan fi kún un pé, “Ńṣe ló máa ń ṣe àwọn òbí tí wọ́n tọ́jú àwọn ọmọ wọn tí wọ́n sì jìyà nítorí wọn bíi pé àwọn ọmọ náà ti pa wọ́n tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Wọ́n tún lè máa ṣàníyàn pé àwọn ọmọ wọn kò tíì gbọ́n tó láti ṣàṣeyọrí nínú ìgbéyàwó wọn.”
Àmọ́ ká sòótọ́, ìgbà míì wà tó jẹ́ pé àwọn ọmọ ló máa ń pe àwọn òbí wọn sóhun tí kò yẹ kí wọ́n dá sí. Bí àpẹẹrẹ, ṣàyẹ̀wò ọ̀ràn tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Michael àti Leanne tí wọ́n ń gbé lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Michael sọ pé: “Inú ìdílé tí wọ́n ti ṣe ara wọn lóṣùṣù ọwọ̀, tí kálukú ti máa ń sọ èrò ọkàn rẹ̀ fàlàlà ni Leanne ti wá.
Nítorí náà, lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, ńṣe ló máa ń lọ fi ọ̀ràn lọ bàbá rẹ̀ lórí ìpinnu tó yẹ kí èmi àti ẹ̀ nìkan jọ ṣe. Bàbá rẹ̀ ní ọgbọ́n tó pọ̀ láti fi ran èèyàn lọ́wọ́ lóòótọ́, àmọ́ ó máa ń dùn mí pé ó lọ bá bàbá rẹ̀ dípò kó wá bá mi!”Kò sí àní-àní pé ìṣòro àárín lọ́kọláya àti àna wọn máa ń dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìdílé. Ṣé bí ọ̀rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Báwo ni àárín ìwọ àti àna rẹ ṣe rí? Jẹ́ ká wo ìṣòro méjì tó lè yọjú àtohun tó o lè ṣe sí i.
ÌṢÒRO ÀKỌ́KỌ́: Ó lè dà bíi pé wọléwọ̀de àárín ẹnì kejì rẹ àtàwọn òbí rẹ̀ ti pọ̀ jù. Ọkọ kan ní orílẹ̀-èdè Sípéènì tó ń jẹ́ Luis sọ pé: “Ìyàwó mi rò pé ńṣe lòun já àwọn òbí òun kulẹ̀ tí a kò bá gbé nítòsí wọn. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, nígbà tá a bí ọmọ wa ọkùnrin, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ọjọ́ kan táwọn òbí mi kì í wá sílé wa, èyí sì kó ìnira bá ìyàwó mi. Ìyẹn sì dá èdèkòyédè sílẹ̀ láàárín èmi àti ìyàwó mi.”
Bó ṣe yẹ kó rí: Nígbà tí Bíbélì ń ṣàlàyé nípa ètò ìgbéyàwó, ó sọ pé tó bá di àkókò kan “ọkùnrin yóò . . . fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Jíjẹ́ ara kan ju pé kí wọ́n kàn jọ máa gbé lọ. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé ọkọ àti aya yóò dá ìdílé tiwọn sílẹ̀, ọ̀ràn ìdílé tuntun yìí ló máa gba iwájú, kì í ṣe ìdílé tí wọ́n ti wá. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Àmọ́ ṣá o, tọkọtaya ṣì ní láti máa bọlá fún àwọn òbí wọn, èyí sì kan pé kí wọ́n máa fún wọn ní àfiyèsí lóòrèkóòrè. (Éfésù 6:2) Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ọwọ́ tí ẹnì kejì rẹ fi mú ọ̀ràn àwọn òbí rẹ̀ jẹ́ kó dà bíi pé ó pa ẹ́ tì ńkọ́?
Ohun tó o lè ṣe: Gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa, kó o má sì pọ̀n sí ọ̀nà kan. Ṣé òótọ́ ni pé ẹnì kejì rẹ ti jẹ́ kí ọ̀ràn àwọn òbí rẹ̀ gbà á lọ́kàn jù, àbí torí pé o kò nírú àjọṣe yìí pẹ̀lú àwọn òbí tìrẹ lo ṣe rò bẹ́ẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kì í ṣe bí ìdílé rẹ ṣe tọ́ ẹ dàgbà ló mú kó o máa wo ọ̀ràn náà bẹ́ẹ̀? Ṣé kì í ṣe pé ò ń jowú ni?—Òwe 14:30; 1 Kọ́ríńtì 13:4; Gálátíà 5:26.
Ó gba pé kéèyàn fi òótọ́ ọkàn ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀ kéèyàn tó lè dáhùn irú àwọn ìbéèrè yìí. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀ náà, tí ọ̀rọ̀ àwọn àna yín bá ṣì ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ, kì í ṣe ìṣòro àwọn àna lẹ ni, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni pé, ìgbéyàwó yín níṣòro.
Ohun tó máa ń dá ọ̀pọ̀ ìṣòro sílẹ̀ nínú ìgbéyàwó ni pé, èrò ẹni méjì kì í dọ́gba délẹ̀délẹ̀ lórí ọ̀ràn kan. Nítorí náà, ǹjẹ́ o lè gbìyànjú láti fi ojú tí ọkọ tàbí aya rẹ fi wo ọ̀ràn kan wò ó? (Fílípì 2:4; 4:5) Ohun tí ọkọ kan tó ń jẹ́ Adrián tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ṣe nìyẹn. Ó ní, “Inú ìdílé tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ níwà tó dáa ni wọ́n ti tọ́ ìyàwó mi dàgbà. Nítorí náà, mi ò fi bẹ́ẹ̀ sún mọ́ àwọn àna mi. Àmọ́ nígbà tó yá, mi ò tiẹ̀ wá sún mọ́ wọn mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Èyí dá èdèkòyédè sílẹ̀ láàárín èmi àti ìyàwó mi torí ó ṣì fẹ́ láti sún mọ́ àwọn òbí rẹ̀, àgàgà ìyá rẹ̀.”
Nígbà tó yá, Adrián tún èrò rẹ̀ pa lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ó ní, “Lóòótọ́, mo mọ̀ pé tí ìyàwó mi bá ń sún mọ́ àwọn òbí rẹ̀ jù, yóò ṣèpalára fún èrò rẹ̀, àmọ́ tí kò bá sún mọ́ wọn rárá, ìyẹn náà á dá ìṣòro sílẹ̀. Nítorí náà, mo ṣe gbogbo nǹkan tí mo lè ṣe láti rí i pé mo tún àárín èmi àti àwọn àna mi ṣe.” b
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Kí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ kọ èrò yín nípa àwọn àna yín sórí ìwé. Tó bá ṣeé ṣe, o lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ báyìí, “Mo rò pé . . .” Lẹ́yìn náà, ẹ pààrọ̀ ìwé tẹ́ ẹ kọ. Kẹ́ ẹ jọ wá ronú lórí ọ̀nà tó dára tẹ́ ẹ lè gbà bójú tó èrò ẹnì kọ̀ọ̀kan yín.
ÌṢÒRO KEJÌ: Àwọn àna yín sábà máa ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ìwọ àti ẹnì kejì rẹ, wọ́n sì máa ń gbà yín nímọ̀ràn láìjẹ́ pé ẹ pè wọ́n. Ìyàwó ilé kan tó ń jẹ́ Nelya ní orílẹ̀-èdè Kazakhstan sọ pé, “Ọ̀dọ̀ ìdílé ọkọ mi la ti lo ọdún méje àkọ́kọ́ lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èdèkòyédè máa ń wáyé lórí bá a ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wa, lórí bí mo ṣe ń se oúnjẹ àti bí mo ṣe ń ṣe
ìmọ́tótó ilé. Mo bá ọkọ mi àti ìyá ọkọ mi sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ ńṣe lèyí túbọ̀ dá èdèkòyédè sílẹ̀!”Bó ṣe yẹ kó rí: Tó o bá ti ṣègbéyàwó, o ò sí lábẹ́ àṣẹ àwọn òbí rẹ mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé, “orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin,” ìyẹn ọkọ rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Àmọ́ ṣá o, bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, àtọkọ àtìyàwó ló gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wọn. Kódà, ìwé Òwe 23:22 sọ fún wa pé: “Fetí sí baba rẹ tí ó bí ọ, má sì tẹ́ńbẹ́lú ìyá rẹ kìkì nítorí pé ó ti darúgbó.” Àmọ́, kí lo máa ṣe táwọn òbí rẹ tàbí òbí ẹnì kejì rẹ bá tojú bọ ọ̀rọ̀ yín, tí wọ́n sì ń fẹ́ kẹ́ ẹ gba èrò wọn tipátipá?
Ohun tó o lè ṣe: Fi ara rẹ sípò àwọn òbí yín, kó o sì ronú lórí ohun tó ṣeé ṣe kó fà á tí wọ́n fi dá sí ọ̀rọ̀ yín láìjẹ́ pé ẹ pè wọ́n. Ọ̀gbẹ́ni Ryan tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé, “Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn òbí máa ń fi hàn pé àwọn ṣì ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé àwọn ọmọ wọn.” Wọ́n lè ṣàì ní in lọ́kàn tẹ́lẹ̀ láti dá sí ọ̀rọ̀ ìdílé àwọn ọmọ wọn, tí ọ̀rọ̀ bá sì wá rí bẹ́ẹ̀, ẹ lè bójú tó o tẹ́ ẹ bá fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sílò, tó ní, “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.” (Kólósè 3:13) Àmọ́ tó bá ṣẹlẹ̀ pé dídá táwọn àna yín ń dá sí ọ̀rọ̀ yín ti wá le débi tó fi lè dá èdèkòyédè sílẹ̀ láàárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ ńkọ́?
Àwọn tọkọtaya kan ti fi ààlà tó yẹ sáàárín ọ̀rọ̀ wọn àti tàwọn òbí wọn. Èyí kò túmọ̀ sí pé kó o ṣòfin fún wọn. c Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó o kàn máa ṣe ni pé kó o jẹ́ kí wọ́n rí i kedere nínú ìṣe rẹ pé ọ̀rọ̀ ẹnì kejì rẹ ló jẹ ọ́ lógún ju ti ẹlòmíì lọ. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ kan lórílẹ̀-èdè Japan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Masayuki sọ pé: “Bí àwọn òbí rẹ bá tiẹ̀ sọ èrò wọn, má gbà pẹ̀lú wọn lójú ẹsẹ̀. Má gbàgbé pé ìwọ náà ti dá ìdílé tìẹ sílẹ̀. Nítorí náà, kọ́kọ́ wádìí èrò ẹnì kejì rẹ lórí ìmọ̀ràn tí wọ́n gbà ẹ́ yẹn.”
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Sọ fún ẹnì kejì rẹ ọ̀nà tó o rò pé dídá táwọn òbí yín ń dá sí ọ̀rọ̀ yín gbà ń fa èdèkòyédè nínú ìgbéyàwó yín. Kẹ́ ẹ wá kọ ibi tẹ́ ẹ fẹ́ káwọn òbí yín máa lọ́wọ́ nínú ọ̀rọ̀ yín dé sórí ìwé, kẹ́ ẹ sì tún kọ bẹ́ ẹ ṣe máa ṣe é tí wọn ò fi ní kọjá ibẹ̀, tẹ́ ẹ ó sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn lẹ́sẹ̀ kan náà.
Ọ̀pọ̀ èdèkòyédè tó máa ń wáyé láàárín àwọn àna àtàwọn ọmọ wọn tó ti ṣègbéyàwó ló máa dín kù bí tọkọtaya bá ń fara balẹ̀ ronú láti mọ ìdí táwọn òbí wọn fi dá sí ọ̀rọ̀ àwọn, tí wọn kò sì jẹ́ kí ìyẹn dá èdèkòyédè sílẹ̀ láàárín àwọn méjèèjì. Lórí kókó yìí, Jenny sọ pé: “Nígbà míì, ọ̀rọ̀ èmi àti ọkọ mi kì í wọ̀ nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn òbí wa, a sì ti rí i pé ọ̀pọ̀ ìrora la máa ń fà fún ara wa tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àìpé àwọn òbí wa. Nígbà tó yá, a kò fi kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn òbí wa na ara wa ní pàṣán mọ́, àmọ́ ìṣòro tó wà nílẹ̀ là ń bójú tó. Àbájáde èyí ni pé àárín èmi àti ọkọ mi wá gún régé sí i.”
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.
b Òótọ́ ni pé tí àwọn òbí kan bá ń hùwà tí kò dáa, àgàgà tí wọn bá ń bá a lọ láìronú pìwà dà, àárín àwọn àtàwọn ọmọ kò ní fi bẹ́ẹ̀ gún régé mọ́.—1 Kọ́ríńtì 5:11.
c Nínú àwọn ọ̀rọ̀ kan, ó lè gba pé kó o bá àwọn òbí rẹ tàbí àwọn àna rẹ sọ̀rọ̀ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Tọ́rọ̀ bá wá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o sọ èrò ọkàn rẹ fún wọn pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìwà tútù.—Òwe 15:1; Éfésù 4:2; Kólósè 3:12.
BI ARA RẸ PÉ . . .
▪ Àwọn ànímọ́ tó dáa wo làwọn àna mi ní?
▪ Báwo ni mo ṣe lè bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí mi tí mi ò sì ní pa ẹnì kejì mi tì?