Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nípa Ìjọsìn Tòótọ́

Nípa Ìjọsìn Tòótọ́

Ohun Tá A Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù

Nípa Ìjọsìn Tòótọ́

Ṣé gbogbo ìsìn ni Ọlọ́run fọwọ́ sí?

▪ Àánú àwọn èèyàn tí ìsìn èké ti ṣì lọ́nà ṣe Jésù. Ó kìlọ̀ pé kí wọ́n ṣọ́ra “fún àwọn wòlíì èké tí ń wá sọ́dọ̀ [wọn] nínú aṣọ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n jẹ́ ọ̀yánnú ìkookò.” (Mátíù 7:15) Ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé àwọn èèyàn kan máa ń fi ìsìn bojú láti ṣe ibi?

Jésù sọ nínú àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Nítorí náà, Ọlọ́run ò fọwọ́ sí ìjọsìn tó ta ko òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Ìyẹn ló mú kí Jésù lo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti fi bá àwọn ẹlẹ́sìn kan tí wọ́n jẹ́ alágàbàgebè wí, ó ní: “Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni bí ẹ̀kọ́.”—Mátíù 15:9.

Ǹjẹ́ ìsìn tòótọ́ wà?

▪ Nígbà tí Jésù pàdé obìnrin ará Samáríà kan tí wọ́n ti fi ìsìn èké tàn jẹ, ó sọ fún un pé: “Ẹ̀yin ń jọ́sìn ohun tí ẹ kò mọ̀ . . . Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun.” (Jòhánù 4:22, 23) Ó dájú pé èèyàn lè rí ìsìn tòótọ́.

Jésù sọ pé: “Èmi kò ṣe nǹkan kan ní àdáṣe ti ara mi; ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.” Nítorí náà, ó dá Jésù lójú pé ìsìn tóun ń kọ́ni nípa rẹ̀ nìkan ni ìsìn tòótọ́. (Jòhánù 8:28) Ìyẹn ló mú kó sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Níwọ̀n bí àwọn olùjọsìn tòótọ́ ti máa ń fi ìṣọ̀kan ké pe Bàbá, wọ́n gbọ́dọ̀ wà ní ìṣọ̀kan nínú ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo.

Báwo lo ṣe lè dá àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ mọ̀?

▪ Kristẹni lẹ́ni tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀nà mẹ́rin tá a fi lè dá àwọn tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù mọ̀.

1. Nínú àdúrà tí Jésù Kristi gbà sí Jèhófà, ó sọ pé: “Mo . . . ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀.” (Jòhánù 17:26) Àwọn Kristẹni tòótọ́ náà máa ń sọ orúkọ Ọlọ́run fáwọn èèyàn.

2. Jésù wàásù nípa Ìjọba Jèhófà, ó sì tún rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé káwọn náà wàásù fáwọn èèyàn láti ilé dé ilé. Ó sọ pé: “Ìlú ńlá tàbí abúlé èyíkéyìí tí ẹ bá wọ̀, ẹ wá ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn.” Nígbà tó yá, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 10:7, 11; 28:19) O lè tètè dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ lónìí, nítorí pé wọ́n ṣì ń bá iṣẹ́ yìí nìṣó.

3. Jésù kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú òṣèlú. Ìyẹn ló mú kó sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:14) Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ mọ̀ pé àwọn olùjọsìn tòótọ́ kì í lọ́wọ́ sí òṣèlú.

4. Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tọkàntara. Ó sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń ran ara wọn lọ́wọ́, wọn kì í sì í lọ́wọ́ sí ogun.

Àǹfààní wo ni ìsìn tòótọ́ lè ṣe fún ẹ?

▪ Kó o tó lè máa ṣe ìsìn tòótọ́, o ní láti kọ́kọ́ mọ Jèhófà dáadáa. Ìmọ̀ nípa Ọlọ́run á jẹ́ kó o máa gbé ìgbé ayé rere, yóò sì mú kó o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run dáadáa. Jèhófà ṣèlérí ìyè tí kò nípẹ̀kun fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ìyẹn ló mú kí Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú.”—Jòhánù 17:3.

Fún àlàyé síwájú sí i wo orí 15 nínú ìwé, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

“Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tí ń wá sọ́dọ̀ yín nínú aṣọ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n jẹ́ ọ̀yánnú ìkookò.”—Mátíù 7:15