Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Lè Kẹ́dùn?

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Lè Kẹ́dùn?

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Lè Kẹ́dùn?

ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́ 2:11-18

ÀWA èèyàn aláìpé máa ń kábàámọ̀ nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń kẹ́dùn nígbà tá a bá mọ̀ pé a ti ṣàṣìṣe. Ó yani lẹ́nu láti mọ̀ pé Bíbélì sọ pé Jèhófà náà lè kẹ́dùn. Àmọ́, o lè sọ pé, ‘Ẹni pípé ni Ọlọ́run kẹ̀. Kì í ṣàṣìṣe!’ Báwo ni Ọlọ́run ṣe lè kẹ́dùn? Ìdáhùn ìbéèrè yìí lè jẹ́ ká lóye ohun àgbàyanu kan, ìyẹn ni pé: Ó ní bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jèhófà àti pé ohun tá a bá ṣe lè dùn ún. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́ 2:11-18.

Àwọn ìtàn inú ìwé Àwọn Onídàájọ́ tó wà nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ àkókò tí nǹkan ò rọrùn nínú ìtàn ìgbésí ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Orílẹ̀-èdè yìí ti wà ní Kénáánì, ìyẹn lórí ilẹ̀ tí Ọlọ́run búra láti fún Ábúráhámù. Ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àti ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà náà rèé: Wọ́n pa ìjọsìn Ọlọ́run tì, àwọn ọ̀tá tẹ̀ wọ́n lórí ba, wọ́n rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run, Ọlọ́run sì dá wọn nídè. a

Wọ́n pa ìjọsìn Ọlọ́run tì. Àwọn ọmọ Kénáánì ṣi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà, wọ́n sì “pa Jèhófà tì,” wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn ọlọ́run míì, ní pàtàkì, “wọ́n . . . bẹ̀rẹ̀ sí sin Báálì àti àwọn ère Áṣítórétì.” b Ìpẹ̀yìndà gbáà lèyí jẹ́. Abájọ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì “fi mú Jèhófà bínú,” ìyẹn Ọlọ́run tó dá wọn nídè kúrò ní Íjíbítì!—Ẹsẹ 11-13; Àwọn Onídàájọ́ 2:1.

Àwọn ọ̀tá tẹ̀ wọ́n lórí ba. Jèhófà bínú, èyí sì yẹ bẹ́ẹ̀, nítorí náà, ó fawọ́ ààbò rẹ̀ sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó ti kẹ̀yìn sí i. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣubú “sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn,” àwọn tó wá sí ìlú wọn, tí wọ́n sì kó ìlú náà ní ìkógun.—Ẹsẹ 14.

Wọ́n rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run. Nígbà tí ìnira bá ti pọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n á ronú pìwà dà ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n á sì bẹ Ọlọ́run pé kó ran àwọn lọ́wọ́. “Ìkérora wọn nítorí àwọn tí ń ni wọ́n lára” ló fi hàn pé wọ́n ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀. (Ẹsẹ 18) Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kan lára nǹkan tí wọ́n ṣe láṣetúnṣe nínú ìgbésí ayé wọn. (Àwọn Onídàájọ́ 3:9, 15; 4:3; 6:6, 7; 10:10) Báwo ni Ọlọ́run ṣe dá wọn lóhùn?

Ọlọ́run dá wọn nídè. Jèhófà máa ń gbọ́ ìkérora àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì máa ń “kẹ́dùn” nítorí wọn. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí “kẹ́dùn” tún lè túmọ̀ sí “yí ọkàn pa dà.” Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Ìkérora wọn máa ń mú kí àánú wọ́n ṣe Jèhófà, á wá yí ìpinnu rẹ̀ láti fìyà jẹ wọn pa dà, á sì dá wọn nídè.” Àánú máa ń mú kí Jèhófà “gbé àwọn onídàájọ́ dìde,” táá dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.—Ẹsẹ 18.

Ǹjẹ́ o mọ ohun tó mú kí Ọlọ́run kẹ́dùn tàbí yí ọkàn pa dà? Bí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe yí ìwà wọn pa dà ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Rò ó wò ná: Bàbá onífẹ̀ẹ́ kan lè bá ọmọ kan wí nítorí ohun tó ṣe, bóyá nípa fífi àwọn àǹfààní kan dù ú. Àmọ́ tí bàbá náà bá rí i pé ọmọ náà ti ronú pìwà dà, á dáwọ́ ìyà tó fi ń jẹ ẹ́ dúró.

Kí la rí kọ́ nípa Jèhófà nínú ìtàn yìí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá máa ń múnú bí i, ìrònúpìwàdà àtọkànwá máa ń mú kó fi àánú hàn. Ó bani nínú jẹ́ láti mọ̀ pé ohun tá a bá ṣe máa ń dun Ọlọ́run. O ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè mú “ọkàn-àyà [Jèhófà] yọ.” (Òwe 27:11) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní kábàámọ̀ láé.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ohun tó wà nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́ 2:11-18 jẹ́ ara àkópọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ìtàn bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbé ìgbé ayé wọn, àwọn orí yòókù sì jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ọ̀nà ìgbésí ayé wọn.

b Báálì ni òrìṣà tó gba iwájú jù lọ tí àwọn ọmọ Kénáánì ń sìn, Áṣítórétì sì ni wọ́n gbà pé ó jẹ́ ìyàwó rẹ̀.