Ìdí Tí O Fi Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Inú Bíbélì
Ìdí Tí O Fi Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Inú Bíbélì
“Wọ́n jẹ́ àṣeyọrí ńláǹlà. Wọ́n ti mú káwọn èèyàn ṣe fíìmù tó ná wọn ní ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó . . . àtàwọn èyí tó tà jù lọ lórí àtẹ . . . àwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn Kristẹni ti mú wọn lò. Wọ́n ti fi wọ́n dá àwọn ẹ̀sìn sílẹ̀, wọ́n sì ti fi wọ́n gbé àwọn ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ kalẹ̀.”—ÌWÉ ÌRÒYÌN ILẸ̀ BRAZIL KAN, SUPER INTERESSANTE.
KÍ LÓ fa gbogbo ọ̀rọ̀ amóríyá yìí? Ohun tí ìwé ìròyìn yẹn ń sọ nípa rẹ̀ ni ìfẹ́ táwọn èèyàn ní sí àkójọ àwọn ayédèrú ìwé ìhìn rere, àwọn lẹ́tà àtàwọn ìwé ìṣípayá tí wọ́n rí nílùú Nag Hammadi àti láwọn ibòmíì nílẹ̀ Íjíbítì ní àárín ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún. Àwọn èèyàn sábà máa ń pe àwọn ìwé yìí àtàwọn irú wọn ní ìwé Gnostic tàbí àwọn ìwé Àpókírífà. a
Ṣé Ọ̀tẹ̀ Ni?
Nínú sànmánì tá a wà yìí, àwọn èèyàn sábà máa ń ṣàríwísí Bíbélì àtàwọn ẹ̀sìn, ó jọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló tẹ́wọ́ gba àwọn ìwé Gnostic tàbí Àpókírífà. Àwọn ìwé yìí ti ní ipa púpọ̀ lórí ojú tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo ẹ̀kọ́ Jésù Kristi àti ẹ̀sìn Kristẹni fúnra rẹ̀. Ìwé ìròyìn kan sọ pé: “Ìwé Ìhìn Rere Tọ́másì àtàwọn ìwé àpókírífà míì sọ̀rọ̀ tó wọ àwùjọ àwọn èèyàn kan tó ń pọ̀ sí i lóde òní lọ́kàn, ìyẹn àwùjọ àwọn tó fẹ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run àmọ́ tí wọn kò fọkàn tán ẹ̀sìn.” Wọ́n fojú bù ú pé nílẹ̀ Brazil nìkan “ó kéré tán ọgbọ̀n àwùjọ ló wà, tí wọ́n gbé ìgbàgbọ́ wọn karí ìwé Àpókírífà.”
Wíwá tí wọ́n wá àwọn ìwé yìí kàn, ti jẹ́ kí èrò kan táwọn èèyàn ní tàn kálẹ̀ gan-an pé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin Sànmánì Kristẹni (S.K.), Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì bo òtítọ́ nípa Jésù mọ́lẹ̀, pé àwọn àkọsílẹ̀ kan nípa ìgbésí ayé rẹ̀, èyí tó wà nínú ìwé Àpókírífà ni wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ àti pé àyípadà ti bá ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin tó wà nínú Bíbélì lóde òní. Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ẹ̀sìn tó ń jẹ́ Elaine Pagels sọ ọ̀rọ̀ náà báyìí pé: “Ìsinsìnyí
la wá rí i pé orí àwọn ìwé tí kò tó nǹkan ni wọ́n gbé ẹ̀sìn Kristẹni kà, ìyẹn ìlànà ẹ̀kọ́ Kristẹni, nígbà tó sì jẹ pé ọ̀pọ̀ ìwé ló wà.”Èrò àwọn ọ̀mọ̀wé bíi Pagels ni pé inú Bíbélì nìkan kọ́ ni ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn Kristẹni ti wá, àwọn ìwé mìíràn tún wà, irú bí ìwé Àpókírífà. Bí àpẹẹrẹ, ètò kan tí ilé iṣẹ́ ìròyìn BBC pè ní ohun ìjìnlẹ̀ Bíbélì, ìyẹn Bible Mysteries, gbé àkòrí kan jáde tí wọ́n pè ní “Ẹni Tó Jẹ́ Màríà Magidalénì Gangan.” Ètò náà jẹ́ ká mọ̀ pé ìwé Àpókírífà sọ pé Màríà Magidalénì jẹ́ “olùkọ́ àti atọ́nà tẹ̀mí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù. Obìnrin yìí kì í ṣe ọmọ ẹ̀yìn lásán; àpọ́sítélì fún àwọn àpọ́sítélì ló jẹ́.” Nígbà tí Juan Arias ń sọ̀rọ̀ nípa ipa tí wọ́n ní Màríà Magidalénì kó, ó sọ nínú ìwé ìròyìn Brazil náà, O Estado de S. Paulo pé: “Lónìí ohun gbogbo ló mú ká gbà pé ìjọ Kristẹni tí Jésù dá sílẹ̀ jẹ́ ti ‘ajàfẹ́tọ̀ọ́ obìnrin,’ nítorí pé ilé àwọn obìnrin ni wọ́n fi ṣe ṣọ́ọ̀ṣì àkọ́kọ́, níbi táwọn obìnrin ti ń ṣe ìsìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àti bíṣọ́ọ̀bù.”
Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, ọ̀rọ̀ inú àwọn ìwé Àpókírífà ṣe pàtàkì ju ti àwọn ìwé Bíbélì lọ. Àmọ́ ṣá o, ọ̀rọ̀ yìí gbé ìbéèrè pàtàkì kan síni lọ́kàn pé, Ṣé orí ìwé Àpókírífà ló yẹ kí ìgbàgbọ́ Kristẹni dá lé? Nígbà táwọn ẹ̀kọ́ yẹn bá ta ko ẹ̀kọ́ Bíbélì, èwo ló yẹ ká gbà gbọ́, ṣé Bíbélì ni àbí àwọn ìwé Àpókírífà? Ṣé lóòótọ́ ni àwọn èèyàn dìtẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin káwọn èèyàn má bàa mọ̀ nípa àwọn ìwé yìí àti láti yí àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin pa dà, kí wọ́n sì mú àwọn ohun pàtàkì nípa Jésù, Màríà Magidalénì àtàwọn míì kúrò nínú Bíbélì? Láti lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀kan lára àwọn ìwé Ìhìn Rere inú Bíbélì yẹ̀ wò, ìyẹn ìwé Ìhìn Rere Jòhánù.
Ẹ̀rí Látinú Ìwé Ìhìn Rere Jòhánù
Wọ́n rí àjákù ìwé Ìhìn Rere Jòhánù nílẹ̀ Íjíbítì nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún ń parí lọ, wọ́n sì ń pè é ní Papyrus Rylands 457 (P52). Ohun tó wà nínú Jòhánù 18:31-33, 37, 38 nínú Bíbélì òde òní ló wà nínú rẹ̀, wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ sí ilé ìkówèésí ti John Rylands Library, ní Manchester, nílẹ̀ England. Èyí ni àjákù ìwé àfọwọ́kọ tó tíì pẹ́ jù lọ lára Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó ṣì wà. Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé gbà pé nǹkan bí ọdún 125 Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ ọ́, ìyẹn jẹ́ nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lẹ́yìn ikú Jòhánù. Ohun tó yani lẹ́nu gan-an ni pé gbogbo ọ̀rọ̀ tó wà nínú àjákù yìí ló fẹ́rẹ̀ẹ́ bá ohun tó wà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n kọ lẹ́yìn ìgbà yẹn mu tán. Bí àdàkọ ìwé Ìhìn Rere Jòhánù ṣe wà káàkiri títí dé ilẹ̀ Íjíbítì níbi tí wọ́n ti rí àjákù ìwé àfọwọ́kọ náà jẹ́ ẹ̀rí pé ìwé Ìhìn Rere Jòhánù la ti kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni àti pé Jòhánù fúnra rẹ̀ ló kọ ọ́ gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe fi hàn. Nítorí náà, ẹni tí ọ̀rọ̀ ṣojú rẹ̀ ló kọ ohun tó wà nínú ìwé Jòhánù.
Àmọ́ ní ti àwọn ìwé Àpókírífà, ọgọ́rùn-ún ọdún kejì ni wọ́n kọ wọ́n, ìyẹn ọgọ́rùn-ún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lẹ́yìn tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n kọ sínú wọn ti ṣẹlẹ̀. Àwọn ògbógi onímọ̀ kan sọ pé orí àwọn ìwé tàbí àwọn ẹ̀kọ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n gbé àwọn ìwé Àpókírífà kà, àmọ́ kò sí ẹ̀rí tó tì í lẹ́yìn. Níbi tí ọ̀rọ̀ dé yìí, ìbéèrè náà ni pé, Èwo lo máa gbà gbọ́ gan-an, ṣé ẹ̀rí ẹni tí ọ̀ràn ṣojú rẹ̀ ni àbí tàwọn èèyàn tó gbé láyé ní b
ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé? Ìdáhùn náà kò mù.Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ pé wọ́n ti yí àwọn ìwé Ìhìn Rere inú Bíbélì pa dà káwọn èèyàn má bàa mọ àwọn ohun kan nípa ìgbésí ayé Jésù ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ẹ̀rí wà pé wọ́n ti yí ìwé Ìhìn Rere Jòhánù pa dà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin kí wọ́n lè yí òtítọ́ po? Ká tó dáhùn ìbéèrè yìí, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ọ̀kan lára ìwé pàtàkì tí wọ́n fi ṣe Bíbélì òde òní ni ìwé àfọwọ́kọ ti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin tó ń jẹ́ Vatican 1209. Bí Bíbélì tá à ń kà báyìí bá ní àwọn ìyípadà tí wọ́n ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin, á jẹ́ pé àwọn ìyípadà náà máa wà nínú ìwé àfọwọ́kọ Vatican 1209 nìyẹn. Ó dùn mọ́ni pé ìwé àfọwọ́kọ míì tó ń jẹ́ Bodmer 14, 15 (P75), tó ní ẹ̀rí pé wọ́n kọ ọ́ ní àárín ọdún 175 Sànmánì Kristẹni sí 225 Sànmánì Kristẹni ní ọ̀pọ̀ lára ohun tó wà nínú ìwé Lúùkù àti Jòhánù nínú. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ògbógi onímọ̀ ti wí, àwọn ọ̀rọ̀ inú wọn sún mọ́ ti ìwé àfọwọ́kọ Vatican 1209 gan-an. Ohun tá à ń sọ ni pé kò sí ìyípadà ńlá kankan tó dé bá àwọn ìwé Ìhìn Rere inú Bíbélì, ìwé àfọwọ́kọ Vatican 1209 ló fẹ̀rí èyí hàn.
Kò sí ẹ̀rí kankan, bóyá látinú àkọsílẹ̀ kan tàbí ní ibòmíì tó fi hàn pé àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Jòhánù tàbí ti àwọn ìwé Ìhìn Rere yòókù yí pa dà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin. Lẹ́yìn àyẹ̀wò àkójọ àjákù ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n rí ní Oxyrhynchus, nílẹ̀ Íjíbítì, Ọ̀mọ̀wé Peter M. tó jẹ́ Ọ̀gá Yunifásítì Cambridge kọ̀wé pé: “Tá a bá sọ ọ́ lọ, sọ ọ́ bọ̀, àwọn ìwé àfọwọ́kọ yìí jẹ́rìí sí i pé ìwé àfọwọ́kọ onílẹ́tà gàdàgbàgàdàgbà tí wọ́n kọ láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin síwájú ni wọ́n lò láti fi ṣe àwọn ìwé àfọwọ́kọ èdè Gíríìkì àtijọ́ tá à ń lò lóde òní. Kò sí ohun kankan tó ṣòroó lóye lára àwọn ọ̀rọ̀ inú [Májẹ̀mú Tuntun] ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ tó wà fún wa.”
Kí Wá Ni Èrò Wa?
Ó kéré tán, láti àárín ọgọ́rùn-ún ọdún kejì làwọn Kristẹni kárí ayé ti tẹ́wọ́ gba àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin tó ní ìmísí Ọlọ́run, ìyẹn Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù. Ọ̀gbẹ́ni Tatian kọ ìwé kan láàárín ọdún 160 sí ọdún 175 Sànmánì Kristẹni, àwọn èèyàn sì ń lo ìwé náà káàkiri. Wọ́n ń pe ìwé náà ní, Diatessaron (ìyẹn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “látinú mẹ́rin”), orí ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin tó ní ìmísí Ọlọ́run ló gbé ìwé rẹ̀ yìí kà, kò gbé e ka èyíkéyìí lára àwọn ayédèrú ìwé ìhìn rere ti Gnostic. (Wo àpótí náà, “Bí Wọ́n Ṣe Gbèjà Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Nígbà Láéláé.”) Ọ̀gbẹ́ni Irenaeus tó gbé ayé ní apá ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kejì tún ṣe àkíyèsí kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó ní ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin ló gbọ́dọ̀ wà, bí ayé ṣe pín sí apá mẹ́rin tó sì ní àwọn afẹ́fẹ́ mẹ́rin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn ṣì lè kọminú sí ọ̀rọ̀ tó sọ yìí, síbẹ̀, ohun tó sọ kín kókó náà lẹ́yìn pé kìkì ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin ló wà tó ní ìmísí Ọlọ́run ní àkókò yẹn.
Kí ni gbogbo àwọn òtítọ́ yìí fi hàn? Ohun tó fi hàn ni pé Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì títí kan ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin tá à ń lò lónìí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kejì sí ìgbà yìí. Kò sí ìdí kankan tó lè múni gbà gbọ́ pé ọ̀tẹ̀ wáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin láti yí apá kan Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí pa dà tàbí
láti má ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó wà nínú rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀mọ̀wé nípa Bíbélì, Bruce Metzger kọ̀wé pé: “Nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kejì fi máa parí, . . . àwọn onígbàgbọ́ ti fara mọ́ apá tó pọ̀ jù lọ lára Májẹ̀mú Tuntun, kì í ṣe àwọn onígbàgbọ́ àtàwọn ìjọ tó wà káàkiri Mẹditaréníà nìkan ló fara mọ́ ọn, àmọ́ àwọn tó wà ní àgbègbè ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì títí dé Mesopotámíà ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Pétérù mú ipò iwájú nínú gbígbé òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lárugẹ. Àwọn méjèèjì kìlọ̀ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe tẹ́wọ́ gba ohunkóhun tàbí nígbàgbọ́ nínú ohunkóhun tó bá yàtọ̀ sóhun tí wọ́n ti kọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì pé: “Ìwọ Tímótì, máa ṣọ́ ohun tí a tò jọ ní ìtọ́júpamọ́ sọ́dọ̀ rẹ, yẹra fún àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́ àti fún àwọn ìtakora ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’ Nítorí ní ṣíṣe àṣehàn irúfẹ́ ìmọ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn kan ti yapa kúrò nínú ìgbàgbọ́.” Pétérù jẹ́rìí sí i pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, kì í ṣe nípa títẹ̀lé àwọn ìtàn èké àdọ́gbọ́nhùmọ̀ lọ́nà àrékendá ni àwa fi sọ yín di ojúlùmọ̀ agbára àti wíwàníhìn-ín Olúwa wa Jésù Kristi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nípa fífi tí a fi ojú rí ọlá ńlá rẹ̀.”—1 Tímótì 6:20, 21; 2 Pétérù 1:16.
Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run mí sí wòlíì Aísáyà láti sọ pé: “Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ; ṣùgbọ́n ní ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Aísáyà 40:8) Ó dá wa lójú pé Ẹni tó mí sí àwọn Ìwé Mímọ́ ló tún pa wọ́n mọ́ láti àìmọye ọdún wá ká lè “gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:4.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ọ̀rọ̀ yìí, “Gnostic” àti “Àpókírífà” wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì, èyí àkọ́kọ́ tọ́ka sí “ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀,” èkejì sì túmọ̀ sí “ohun tá a rọra fi pa mọ́.” Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n fi ń pe àwọn ìwé tí kò ní ìmísí Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ ayédèrú ìwé Ìhìn Rere, Ìṣe, àwọn lẹ́tà àtàwọn ìṣípayá tí wọ́n wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.
b Ìṣòro míì tó bá àwọn ìwé Àpókírífà ni pé ìwọ̀nba díẹ̀ ló ṣẹ́ kù nínú ẹ̀dà rẹ̀. Ìwé ìhìn rere Gospel of Mary Magdalene, tí wọ́n dọ́gbọ́n sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣẹ́ kù ìwé àjákù méjì péré, èyí tó gùn jù tó jẹ́ ìkẹta sì ti sọ nù. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ọ̀rọ̀ àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó ṣẹ́ kù náà kò bára wọn mu.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
Papyrus Rylands 457 (P52), jẹ́ àjákù ìwé Ìhìn Rere Jòhánù ti ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni tí wọ́n kọ ní ohun tó lé lógún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n kọ ẹ̀dà ìpilẹ̀ṣẹ̀
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Bí Wọ́n Ṣe Gbèjà Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Nígbà Láéláé
Ó ti pẹ́ gan-an táwọn alárìíwísí ti ń gbógun ti àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni pé àwọn ìwé Ìhìn Rere ta ko ara wọn, nítorí náà, kò yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé ohun tó wà nínú wọn. Òǹkọ̀wé ará Síríà náà, Tatian (tó gbé ayé ní nǹkan bí ọdún 110 sí 180 Sànmánì Kristẹni) gbèjà àwọn ìwé Ìhìn Rere. Èrò tiẹ̀ ni pé, téèyàn bá fọgbọ́n kó àwọn ìwé Ìhìn Rere jọ, tó sì sọ wọ́n di ọ̀kan ṣoṣo, gbogbo ìtakora tó wà nínú wọn ló máa pòórá.
Ọ̀gbẹ́ni Tatian dáwọ́ lé ohun tó ní lọ́kàn yìí. Kò sẹ́ni tó mọ̀ bóyá èdè Gíríìkì tàbí Síríákì ló fi kọ ọ́. Èdè yòówù kó lò, ní nǹkan bí ọdún 170 Sànmánì Kristẹni, Ọ̀gbẹ́ni Tatian parí ìwé tó ń kọ náà, orúkọ rẹ̀ ni Diatessaron, ìyẹn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “látinú mẹ́rin.” Kí nìdí tó fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ sí ìwé tí Ọlọ́run kò mí sí yìí?
Ní ọgọ́rùn-ún kọkàndínlógún, àwọn alárìíwísí bẹ̀rẹ̀ sí gbé èrò kan lárugẹ pé kò sí èyíkéyìí lára àwọn ìwé Ìhìn Rere tí wọ́n kọ ṣáájú àárín ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni. Nítorí náà, wọn kì í ṣe ìtàn téèyàn lè gbára lé. Àmọ́ ṣá o, àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́, ìyẹn Diatessaron tí wọ́n rí látìgbà náà wá fún wa ní ẹ̀rí tó ṣe pàtó pé ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin, àní mẹ́rin péré ni àwọn èèyàn mọ̀ káàkiri ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni tí wọ́n sì gbà pé ó jẹ́ àkójọ ìwé tó níye lórí.
Bí wọ́n ṣe ṣàwárí ìwé Diatessaron àtàwọn àlàyé lórí rẹ̀ lédè Árábíìkì, Améníà, Gíríìkì àti Látìn mú kí ọ̀mọ̀wé nípa Bíbélì, Alàgbà Frederic Kenyon kọ̀wé pé: “Àwọn àwárí yìí ti mú gbogbo iyè méjì èyíkéyìí kúrò nípa ìwé Diatessaron, wọ́n sì fẹ̀rí hàn pé ní nǹkan bí ọdún 170 Lẹ́yìn Ikú Olúwa wa, àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin tí Ọlọ́run mí sí ti lágbára ju gbogbo àwọn ìwé yòókù tí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ìtàn ìgbésí ayé Olùgbàlà wa.”
[Àwọn àwòrán]
Tatian
Diatessaron Lédè Árábíìkì
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
33 S.K.
Jésù kú
nǹkan bí ọdún 41
ni wọ́n kọ Mátíù
nǹkan bí ọdún 58
ni wọ́n kọ Lúùkù
nǹkan bí ọdún 65
ni wọ́n kọ Máàkù
nǹkan bí ọdún 98
ni wọ́n kọ Jòhánù
125
Rylands 457 (P52)
nǹkan bí ọdún 140
ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ àwọn ìwé Àpókírífà
nǹkan bí ọdún 175
Bodmer 14, 15 (P75)
Ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin
Vatican 1209
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Vatican 1209
Ìwé àfọwọ́kọ Vatican 1209, tí wọ́n kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin jẹ́rìí si pé àtúnṣe tó bá ìwé Ìhìn Rere kò tó nǹkan
[Credit Line]
Látinú ìwé tó ń jẹ́ Bibliorum Sacrorum Graecus Codex Vaticanus, 1868
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
© The Trustees of the Chester Beatty Library, Dublin