Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Òkè Ẹfun Gàgàrà Lójú Òfuurufú

Òkè Ẹfun Gàgàrà Lójú Òfuurufú

Lẹ́tà Láti Orílẹ̀-èdè Papua New Guinea

Òkè Ẹfun Gàgàrà Lójú Òfuurufú

NÍ DÉÉDÉÉ aago márùn-ún ìdájí lọ́jọ́ Tuesday, ojú ọjọ́ kò gbóná jù kò sì tutù jù nílùú Lae, lórílẹ̀-èdè Papua New Guinea (PNG) tá à ń gbé. Láàárọ̀ ọjọ́ náà, èmi àti ìyàwó mi ń múra láti rìnrìn àjò lọ sí abúlé Lengbati, tó wà ní orí òkè ńlá Rawlinson ní Àgbègbè Morobe láti lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé níbẹ̀.

Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ni ìrìn àjò náà gbà wá nínú ọkọ̀ òfuurufú tí ń gbé èrò mẹ́rin, ẹ́ńjìnnì kan ṣoṣo ló sì ní. Mo sábà máa ń jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ awakọ̀ tá a bá ti ń rìnrìn àjò náà. Nítorí ariwo ńlá tí ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ náà máa ń pa, ńṣe la máa ń gbé ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ sétí ká tó lè bára wa sọ̀rọ̀. Awakọ̀ náà nawọ́ sí àwọn ohun tí wọ́n fi ń darí ọkọ̀ náà, ó sì sọ bí wọ́n ṣe ń lò wọ́n, ó ṣàwàdà, ó sì sọ pé tí nǹkan bá ṣe òun, èmi ni mo máa wa ọkọ̀ òfuurufú náà. Lójú ẹsẹ̀, mo rántí ìtàn òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá sí orílẹ̀-èdè PNG yìí nígbà kan rí. Nígbà tí awakọ̀ tó gbé òjíṣẹ́ náà dákú lójú òfuurufú, ọkọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí pòòyì kiri fúnra rẹ̀ títí dìgbà tí awakọ̀ náà fi jí tó sì wa ọkọ̀ náà balẹ̀ síbi gbalasa. A dúpẹ́ pé ọkọ̀ òfuurufú tá a gbé lọ gúnlẹ̀ láyọ̀, kò sì sí ìyọnu.

Bá a ṣe ń fò ní téńté orí òkè ńlá náà, lójijì, a jáde nínú kùrukùru, a sì gba apá kan lára òkè náà kọjá, èyí tí ọkọ̀ òfuurufú wa fi ga ju òkè yìí kò ju nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mítà lọ. Abúlé Lengbati wà níwájú wa, ojú kan làwọn ilé tó wà níbẹ̀ wà, àwọn ohun èlò látinú igbó ni wọ́n fi kọ́ wọn, koríko ni wọ́n sì fi bo orí àwọn ilé náà. Awakọ̀ náà wo ibi gbalasa kan tí ọkọ̀ òfuurufú lè balẹ̀ sí bá a ṣe ń rà bàbà lójú òfuurufú, láti rí i pé kò sí àwọn ọmọdé tó ń gbá bọ́ọ̀lù lórí pápá náà. Ó tún wò ó bóyá kòtò wà níbẹ̀ èyí tó ṣeé ṣe káwọn ẹlẹ́dẹ̀ ti gbẹ́ síbẹ̀ lẹ́yìn tó wá kẹ́yìn. Bó ṣe ń bọ̀ wálẹ̀ sínú àfonífojì náà, ó sọ pé, “Kò séwu, ẹ jẹ́ ká balẹ̀.” A bẹ̀rẹ̀ sí yí po, a sì bà sórí ilẹ̀ níbi gbalasa kan táwọn ará abúlé náà ṣe sẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè ńlá náà tí wọ́n fi òkúta ẹfun tó gé látara òkè náà tẹ́.

Nígbà tá a kọ́kọ́ wá síbí, mo wo òkúta ẹfun tó fọ́ sílẹ̀ náà, mo sì ronú lórí iye ọdún tí òkè ńlá yìí ti wà níbẹ̀. Ẹ fojú inú wo bí ipá tó ti òkè ẹfun gàgàrà yìí jáde látinú òkun ti máa lágbára tó, òkè náà gùn tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà, ó sì fi kìlómítà mẹ́rin ga sókè lójú òfuurufú! Bá a ṣe ń bọ́ sílẹ̀ látinú ọkọ̀ òfuurufú, orí ohun tí mo pè ní òkè ẹfun gàgàrà lójú òfuurufú la bọ́ sí.

Àwọn ará abúlé náà sáré wá láti ibi tí wọ́n wà nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró ọkọ̀ òfuurufú tó balẹ̀ sí abúlé wọn, bí wọ́n sì ṣe máa ń ṣe nìyẹn. Bí awakọ̀ náà ṣe paná, mo rí ọkùnrin kan tó jáde wá látinú ọ̀pọ̀ èèyàn náà, ó sì ń bọ̀ níbi tí ọkọ̀ náà wà. Zung ni orúkọ rẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n yàn pé kó máa bójú tó iṣẹ́ ìdálẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lábúlé yẹn. Ẹni tó ń gbé ìgbésí ayé tó mọ́, olóòótọ́ àti ẹni tó ṣeé fọkàn tán làwọn èèyàn rẹ̀ mọ̀ ọ́n sí. Ó ní, àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì tí òun ń fi sílò ló ran òun lọ́wọ́ láti máa gbé ìgbésí ayé òun lọ́nà bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tá a ti bọ ara wa lọ́wọ́, tá a sì kí ara wa, àwa, Zung àtàwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ rìn díẹ̀ lọ sí ọwọ́ ìsàlẹ̀ òkè náà. Àwọn ọmọdé ń tẹ̀ lé wa, wọ́n ń bára wọn du ẹrù wa pé ta ló máa gbé e.

A dé ilé kékeré kan táwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lábúlé náà figi kọ́, ibẹ̀ ni òjíṣẹ́ tó máa ń wá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà-mẹ́fà máa ń dé sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ olóoru ni orílẹ̀-èdè PNG, abúlé yìí tutù nítorí orí òkè ló wà. Tá a bá tan àtùpà wa lálẹ́, mo sábà máa ń rí kùrukùru tó ti ń gòkè bọ̀ díẹ̀díẹ̀ látinú àfonífojì náà ní ọ̀sán, táá wá gba inú àlàfo tó wà lára ilẹ̀kùn wọlé. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé a ní láti wọ aṣọ tó nípọn nítorí òtútù ibí yìí, kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ńṣe là ń làágùn yọ̀bọ̀ nínú oorun tó ń mú lágbègbè etíkun ní wákàtí mélòó kan sẹ́yìn.

Ní nǹkan bí ọdún 1986, ọkùnrin kan láti abúlé yìí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú Lae. Nígbà tó pa dà wá sílé, òun àtàwọn mélòó kan kọ́ ilé kékeré kan tí wọ́n á ti máa ṣèpàdé, ilé náà sì gbayì. Nígbà tó yá, pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì Luther tó wà lábúlé yẹn àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ dáná sun ilé ìpàdé náà. Àwọn bàsèjẹ́ tó dáná sun ilé yìí sọ pé àwọn ẹlẹ́sìn Luther nìkan ni wọ́n ń fẹ́ lágbègbè yìí. Látìgbà yẹn, pẹ̀lú bí àwọn èèyàn náà kò ṣe dá inúnibíni tí wọ́n ń ṣe dúró, àwọn Ẹlẹ́rìí ti kọ́ ilé ìpàdé míì, iye wọ́n sì ti pọ̀ sí i tó nǹkan bí àádọ́ta [50] èèyàn tó ń fi ìtara wàásù ìhìn rere lábúlé náà. Ní báyìí, àwọn kan tó ń ta ko iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tẹ́lẹ̀ rí ti wá ń fi ìtara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà.

Àwọn tó wà lábúlé yìí ti wá ń fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè báyìí láti máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn díẹ̀ lè kàwé lábúlé náà, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lábúlé yìí ló ti kọ́ béèyàn ṣe lè kàwé kí wọ́n bàa lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn tó tó igba [200] ló máa ń wá sí ìpàdé tí wọ́n ń ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

Kò sí iná mànàmáná. Lálaalẹ́, gbogbo wa máa ń jókòó yí ká iná nínú búkà tí wọ́n ti ń se oúnjẹ. Gbogbo wá jọ máa ń jẹun, a jọ máa ń sọ̀rọ̀, a sì jọ máa ń rẹ́rìn-ín. Nídìí iná tó rọra ń jó yìí, ńṣe ni ayọ̀ tó wà nínú sísin Jèhófà máa ń hàn lójú àwọn ọ̀rẹ́ wa bí wọ́n ṣe ń rẹ́rìn-ín. Nígbà tó yá, tí ilẹ̀ ti túbọ̀ ń ṣú, àwọn kan yọ àwọn ètùfù tó ń jó látinú iná náà, èyí tí wọ́n gbà pé á rọra máa jó kí wọ́n bàa lè ríran bí wọ́n ṣe ń sáré gba ojúgbó lọ sílé.

Bá a ṣe ń pa dà lọ sílé, a rí i bí agbègbè yìí ṣe máa ń dákẹ́ rọ́rọ́. Gbogbo àyíká wa ni a ti ń gbọ́ ohùn àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run. Lẹ́ẹ̀kan sí i, a tún wo ojú ọ̀run tó mọ́ rokoṣo ká tó sùn, ìyàlẹ́nu ló sì jẹ́ fún wa bí àwọn ìràwọ̀ tá a lè rí látorí òkè ńlá yìí ti pọ̀ tó.

Ká tó pajú pẹ́, ọ̀sẹ̀ kan ti parí, a sì ń rétí ọkọ̀ òfuurufú náà lọ́la. A ṣì ní alẹ́ kan láti lò lábúlé Lengbati tójú ọjọ́ ibẹ̀ tutù yìí, lẹ́yìn náà, ká wá pa dà sínú ooru àti ọ̀rinrin tó wà lágbègbè etíkun.