Ṣé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì?
Ṣé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì?
“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 TÍMÓTÌ 3:16, 17.
Ọ̀RỌ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa bí Bíbélì ṣe níye lórí tó yìí mà lágbára gan-an o! Ó dájú pé àwọn ìwé Bíbélì tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ̀ nígbà yẹn ló ń sọ, ìyẹn àwọn ìwé táwọn èèyàn sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn kan gbogbo ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] tó wà nínú Bíbélì, títí kan èyí táwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni.
Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ǹjẹ́ ìwọ náà ń fojú iyebíye wo Bíbélì? Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run mí sí àwọn tó kọ Bíbélì lóòótọ́? Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní gbà pé ó rí bẹ́ẹ̀. Ìgbàgbọ́ yẹn kò mì fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tó tẹ̀ lé e. Bí àpẹẹrẹ, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìnlá, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ John Wycliffe sọ pé Bíbélì jẹ́ “ìlànà òtítọ́ tí kò láṣìṣe.” Ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, ìyẹn The New Bible Dictionary, sọ nípa ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tá a fàyọ níbẹ̀rẹ̀ pé, “ìmísí [Ọlọ́run] ló fìdí gbogbo ohun tí Bíbélì sọ múlẹ̀ pé ó jóòótọ́.”
Àwọn Èèyàn Ti Ń Kẹ̀yìn sí Bíbélì
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé mọ́ nínú àṣẹ Bíbélì. Ìwé àmọ̀ràn kan nípa ẹ̀sìn, ìyẹn The World’s Religions, sọ pé, “Gbogbo Kristẹni [ṣì] máa ń sọ ọ́ lẹ́nu pé àwọn gbà pé Bíbélì ní àṣẹ lórí ìwà àti ẹ̀kọ́
ìgbàgbọ́ àwọn.” Àmọ́ nínú ìwà wọn, èyí kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn nísinsìnyí ló ń wo Bíbélì pé ó jẹ́ “ẹ̀kọ́ èèyàn tí kò ṣeé gbára lé.” Bí wọ́n tilẹ̀ gbà pé àwọn tó kọ Bíbélì ní ìgbàgbọ́ gan-an, wọ́n kà wọ́n sí aláìpé tó ń sapá láti ṣàlàyé òtítọ́ tó jinlẹ̀ àmọ́ tí wọn kò ní ìmọ̀ àti ìlàlóye tá a ní lónìí.Ká sòótọ́, àwọn èèyàn díẹ̀ ló gbà pé kí ìlànà Bíbélì máa darí èrò àti ìṣe wọn lónìí. Bí àpẹẹrẹ, ṣó o máa ń gbọ́ lọ́pọ̀ ìgbà táwọn èèyàn máa ń sọ pé ìlànà Bíbélì nípa ìbálòpọ̀ kò bóde mu mọ́ àti pé kò wúlò mọ́? Ó yá ọ̀pọ̀ èèyàn lára láti bẹnu àtẹ́ lu òfin àti ìlànà inú Bíbélì tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa wọ́n tì pátápátá nígbà tí wọ́n bá rò pé ó fẹ́ dí àwọn lọ́wọ́. Àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni máa ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí ohun tí Bíbélì sọ nípa àgbèrè, panṣágà, àìṣòótọ́ àti ìmutíyó kẹ́ri.—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.
Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ní nǹkan tó lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, Alàgbà Charles Marston tó jẹ́ awalẹ̀pìtàn sọ ìdí kan ṣoṣo tó fà á nínú ìwé rẹ̀ The Bible Is True. Ó sọ pé àwọn èèyàn tètè máa ń “gba èrò àwọn òǹkọ̀wé òde òní láìjanpata,” ìyẹn àwọn tó ń ṣàtakò pé ọ̀rọ̀ Bíbélì kò jóòótọ́. Ṣé irú ìyẹn náà ń ṣẹlẹ̀ lónìí? Ojú wo ló yẹ kó o máa fi wo èrò àti àbá àwọn ọ̀mọ̀wé tí wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán Bíbélì mọ́? Wo ohun tí àpilẹ̀kọ tó kàn máa sọ nípa èyí.