Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé “kò sí ẹni tí í fi wáìnì tuntun sínú àwọn ògbólógbòó àpò awọ”?

Ó jẹ́ àṣà àwọn èèyàn láti máa tọ́jú wáìnì sínú awọ ẹran lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. (Jóṣúà 9:13) Awọ àwọn ẹran agbéléjẹ̀ bí ewúrẹ́ tàbí ti ọmọ rẹ̀ ni wọ́n fi ń ṣe ìgò awọ. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é ni pé, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti pa ẹran náà, wọ́n á gé orí àtàwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, wọ́n á wá rọra bó awọ ẹran náà kí ikùn rẹ̀ máa bàa luhò. Wọ́n á sá awọ náà, wọ́n á sì wá rán ojú àwọn ibi tí wọ́n gé náà àyàfi ọrùn tàbí ọ̀kan lára ẹsẹ̀ ẹran náà nítorí ibẹ̀ ni wọ́n fi ń ṣe ọrùn ìgò. Wọ́n máa ń fi nǹkan dí ojú ibi tí wọn kò rán náà tàbí kí wọ́n fi okùn so ó.

Tó bá yá, awọ náà máa ń gan paali, kò sì ní lè fẹ̀ mọ́. Nítorí náà, ògbólógbòó àpò awọ kò ní ṣeé tọ́jú wáìnì tuntun pa mọ́ sí, torí bí ọtí bá ṣe ń pẹ́ ni á máa lágbára sí i. Bó ṣe ń lágbára sí yẹn sì lè bẹ́ awọ tó ti gbó. Àmọ́ awọ tuntun ní tiẹ̀ ṣì rọ̀, wáìnì tuntun ò sì lè tètè bẹ́ ẹ. Nítorí ìdí yìí, ohun tí Jésù sọ jẹ́ òótọ́, àwọn èèyàn sì mọ̀ nípa èyí dáadáa ní ọjọ́ rẹ̀. Ó sọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ téèyàn bá fi wáìnì tuntun sínú ògbólógbòó àpò awọ, ó ní: “Nígbà náà wáìnì tuntun yóò bẹ́ àwọn àpò awọ náà, yóò sì dà sílẹ̀, àwọn àpò awọ náà yóò sì bàjẹ́. Ṣùgbọ́n wáìnì tuntun ni a gbọ́dọ̀ fi sínú àwọn àpò awọ tuntun.”—Lúùkù 5:37, 38.

Àwọn wo ni “àwọn ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró” tí wọ́n mẹ́nu kàn nígbà táwọn ará Róòmù mú Pọ́ọ̀lù?

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó wà nínú ìwé Ìṣe inú Bíbélì ṣe sọ, nígbà rúkèrúdò kan ní tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù, ọ̀gágun ará Róòmù fi àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sínú àhámọ́ nítorí èrò rẹ̀ ni pé Pọ́ọ̀lù ni olórí “ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àwọn ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró,” tí wọ́n ń dìtẹ̀ sí ìjọba. (Ìṣe 21:30-38) Kí làwọn èèyàn mọ̀ nípa àwọn ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró yìí?

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró” wá látinú ọ̀rọ̀ Látìn tó ń jẹ́ àwọn Síkárì tó túmọ̀ sí “àwọn tó ń lo síkà,” tàbí ọ̀bẹ aṣóró. Òpìtàn ọ̀gọ́rùn-ún ọdún kìíní tó ń jẹ́ Flavius Josephus sọ pé àwọn Síkárì jẹ́ àwọn Júù onítara tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wọn bí nǹkan míì, alénimádẹ̀yìn ọ̀tá Róòmù ni wọ́n, tí wọ́n máa ń pa àwọn olóṣèlú.

Ọ̀gbẹ́ni Josephus ròyìn pé àwọn Síkárì “máa ń pa àwọn èèyàn ní ọ̀sán gan-gan, láàárín ìlú; wọ́n máa ń ṣe èyí, pàápàá nígbà àjọyọ̀, nígbà tí wọ́n bá kó sáàárín ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn, tí wọ́n á sì tọ́jú ọ̀bẹ aṣóró wọn sábẹ́ aṣọ wọn, ọ̀bẹ yẹn ni wọ́n fi ń gún àwọn ọ̀tá wọn.” Nígbà tẹ́ni tí àwọn Síkárì gún bá ṣubú lulẹ̀ tó sì kú, wọ́n máa ń díbọ́n bíi pé inú ń bí àwọn sẹ́ni tó pa ẹni náà, kí wọ́n má bàa fura sí wọn. Josephus fi kún un pé àwọn Síkárì ló múpò iwájú nínú ọ̀tẹ̀ táwọn Júù dì sáwọn ará Róòmù ní ọdún 66 sí 70 Sànmánì Kristẹni. Ìdí nìyẹn tí ọ̀gágun ará Róòmù náà kò fi fẹ́ dá ẹni táwọn èèyàn pè ní olórí irú àwọn èèyànkéèyàn bẹ́ẹ̀ sílẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ògbólógbòó àpò awo

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Bí ayàwòrán kan ṣe ya ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró rèé