Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbà Wo Ni Aráyé Máa Ní Ojúlówó Àlàáfíà àti Ààbò?

Ìgbà Wo Ni Aráyé Máa Ní Ojúlówó Àlàáfíà àti Ààbò?

Àkànṣe Àsọyé Fún Gbogbo Èèyàn

Ìgbà Wo Ni Aráyé Máa Ní Ojúlówó Àlàáfíà àti Ààbò?

Láti ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún sẹ́yìn làwọn èèyàn ti ń wá àlàáfíà àti ààbò lójú méjèèjì. Àmọ́ ọwọ́ wọn ò tíì tẹ ojúlówó àlàáfíà. Kí nìdí? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìdí pàtàkì méjì ló wà tí àlàáfíà fi di àléèbá fún ẹ̀dá èèyàn. Àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ míì tún wà nínú Bíbélì tó fini lọ́kàn balẹ̀ pé, Ọlọ́run ti ṣèlérí ojúlówó àlàáfíà àti ààbò tó máa kárí ayé tó sì máa wà pẹ́ títí fún ẹ̀dá èèyàn.

Báwo ni àlàáfíà àti ààbò yìí ṣe máa ṣeé ṣe, ìgbà wo sì ni? Kí ni o ní láti ṣe kó o bàa lè jàǹfààní ìbùkún yìí? A máa gbọ́ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Ìgbà Wo Ni Aráyé Máa Ní Ojúlówó Àlàáfíà àti Ààbò?” Kárí ayé ní ilẹ̀ tó ju ọgbọ̀n lé ní igba [230] lọ la ti máa sọ àkànṣe àsọyé yìí. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, inú Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ti máa sọ àsọyé yìí ní ọjọ́ Sunday, April 18, 2010. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ máa dùn láti sọ àkókò àti ibi tí wọ́n ti máa ṣe é fún ẹ. A fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà pè ẹ́ pé kó o wá.