Bí Iṣẹ́ Tí Jésù Kristi Jẹ́ Ṣe Kàn Ẹ́
Bí Iṣẹ́ Tí Jésù Kristi Jẹ́ Ṣe Kàn Ẹ́
“Èmi ti wá kí wọ́n lè ní ìyè, kí wọ́n sì ní in lọ́pọ̀ yanturu.” —JÒHÁNÙ 10:10.
JÉSÙ KRISTI wá sí ayé kó bàa lè fúnni ní nǹkan kì í ṣe kó bàa lè rí nǹkan gbà. Nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó fún ẹ̀dá èèyàn ní ẹ̀bùn tí owó kò lè rà, ìyẹn bó ṣe sọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. Ní báyìí, àwọn tó bá fetí sí iṣẹ́ tí Jésù jẹ́ lè gbádùn ìgbésí ayé tó dáa, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn Kristẹni tòótọ́ sì lè jẹ́rìí sí ìyẹn. a Àmọ́ ohun kan tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú iṣẹ́ tí Jésù jẹ́ ni ẹ̀bùn iyebíye tó fi fúnni, ìyẹn ìwàláàyè rẹ̀ pípé tó fi lélẹ̀ nítorí wa. Ohun tá a bá ṣe nípa apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú iṣẹ́ tí Jésù jẹ́ yìí ló máa pinnu àǹfààní tá a máa jẹ títí ayérayé.
Ohun tí Ọlọ́run àti Kristi fúnni Jésù mọ̀ pé òun ní láti kú ikú oró ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá òun. (Mátíù 20:17-19) Àmọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tá a mọ̀ dáadáa tó wà nínú Jòhánù 3:16, ó sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Jésù tún sọ pé òun wá “fi ọkàn [tàbí ẹ̀mí òun] fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Kí nìdí tó fi sọ pé òun máa fi ẹ̀mí òun fúnni dípò kó sọ pé wọ́n á gba ẹ̀mí òun?
Ìfẹ́ tó ga jù lọ tí Ọlọ́run ní ló mú kó pèsè ohun tó gba ẹ̀dá èèyàn lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún àti àbájáde rẹ̀, ìyẹn àìpé àti ikú. Bí Ọlọ́run ṣe ṣe èyí ni pé, ó rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sí ayé láti kú ikú ìrúbọ. Jésù gbà tọkàntọkàn, ó sì fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé lélẹ̀ nítorí wa. Ohun tó ṣe yìí là ń pè ní ìràpadà, ìyẹn ẹ̀bùn tó ga jù lọ tí Ọlọ́run fún ẹ̀dá èèyàn. b Ẹ̀bùn tó lè jẹ́ kéèyàn ní ìyè àìnípẹ̀kun ni.
Ohun tó yẹ kó o ṣe Ṣé ẹ̀bùn ìràpadà yìí wà fún ìwọ náà? Ọwọ́ ẹ ló kù sí. Àkàwé kan rèé: Ká sọ pé ẹnì kan na ẹ̀bùn tó dì sínú bébà kan sí ẹ. Ó dájú pé ẹ̀bùn náà kò tíì di tìẹ àyàfi tó o bá nawọ́ tó o sì gbà á. Bákan náà, Jèhófà ti na ìràpadà sí ẹ, àmọ́ kò tíì di tìẹ títí dìgbà tó o bá tẹ́wọ́ gbà á. Lọ́nà wo lo máa gbà tẹ́wọ́ gbà á?
Jésù sọ pé àwọn tó bá ń “lo ìgbàgbọ́” nínú òun ló máa gba ìyè àìnípẹ̀kun. Bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa ló máa fi hàn bóyá a ní ìgbàgbọ́. (Jákọ́bù 2:26) Lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù túmọ̀ sí pé kéèyàn mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ wà níbàámu pẹ̀lú àwọn nǹkan tí Jésù kọ́ni àtàwọn ohun tó ṣe. Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti mọ Jésù àti Baba rẹ̀ dáadáa. Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] sẹ́yìn, Jésù Kristi jẹ́ iṣẹ́ kan tó ti yí ìgbésí ayé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé pa dà. Ṣé wàá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa iṣẹ́ tí Jésù jẹ́ yìí àti bí ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ ṣe lè jàǹfààní nínú rẹ̀, nísinsìnyí àti títí láé? Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Àwọn àpilẹ̀kọ tó kàn máa túbọ̀ jẹ́ kó o mọ̀ nípa Jésù Kristi, ìyẹn ọkùnrin tó jẹ́ iṣẹ́ kan tó lè yí ìgbésí ayé rẹ pa dà títí láé.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kì í ṣe gbogbo àwọn tó sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni ló jẹ́ ọmọlẹ́yìn tòótọ́ fún Kristi. Àwọn tó ń gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó bá òtítọ́ tí Jésù kọ́ni nípa Ọlọ́run àti ìfẹ́ rẹ̀ mu nìkan ni ọmọlẹ́yìn tòótọ́ fún Jésù.—Mátíù 7:21-23.
b Fún àlàyé síwájú sí i lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ kọ́ni nípa ìràpadà, ka orí 5, tó sọ pé, “Ìràpadà—Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fúnni,” nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.