Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ẹ̀rí wo ló wà yàtọ̀ sí ti Bíbélì pé Jésù gbé ayé rí?

Àwọn kan tó ń kọ ìwé tí kì í ṣe ti ìsìn tí wọ́n gbé ayé lákòókò tí kò jìnnà sí àkókò Jésù sọ àwọn ohun kan pàtó nípa rẹ̀. Ara wọn ni Ọ̀gbẹ́ni Cornelius Tacitus, tó ṣàkọsílẹ̀ ìtàn ìlú Róòmù táwọn olú ọba ń ṣàkóso. Ọ̀gbẹ́ni Tacitus sọ pé àwọn èèyàn ń sọ ọ́ kiri pé Olú Ọba Nero ló fa jàǹbá iná kan tó sun ìlú Róòmù ní ọdún 64 Sànmánì Kristẹni. Ọ̀gbẹ́ni Tacitus sọ pé Nero gbìyànjú láti di ẹ̀bi jàǹbá náà ru àwùjọ kan tí wọ́n ń pè ní Kristẹni. Tacitus kọ̀wé pé: “Christus ẹni tá a yọ orúkọ [àwọn Kristẹni] látinú orúkọ rẹ̀, ni Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ajẹ́lẹ̀ wa pa nígbà tí Tìbéríù wà lórí oyè.”—Annals, XV, 44.

Òpìtàn Júù náà, Flavius Josephus tún sọ̀rọ̀ nípa Jésù. Nígbà tí Josephus ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ìgbà ikú Festus, gómìnà Róòmù tó ṣàkóso ní Jùdíà ní nǹkan bí ọdún 62 Sànmánì Kristẹni àti nípa Albinus tó bọ́ sípò lẹ́yìn rẹ̀, ó sọ pé Àlùfáà Àgbà Ananúsì (Ánásì) “pe àwọn onídàájọ́ Sànhẹ́dírìn jọ, ó sì mú ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jákọ́bù wá síwájú wọn, ìyẹn arákùnrin Jésù tí wọ́n ń pè ní Kristi, àtàwọn kan.”—Jewish Antiquities, XX, 200 (ix, 1).

Kí nìdí tá a fi pe Jésù ní Kristi?

Àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ pé nígbà tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì fara han Màríà láti kéde pé yóò lóyún, ó sọ fún obìnrin náà pé kí ó pe ọmọ rẹ̀ yìí ní Jésù. (Lúùkù 1:31) Orúkọ yìí wọ́pọ̀ láàárín àwọn Júù nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Òpìtàn Júù náà, Josephus kọ̀wé nípa àwọn méjìlá tó ń jẹ́ orúkọ yẹn yàtọ̀ sí àwọn tí Bíbélì sọ nípa wọn. Àmọ́ “ará Násárétì,” ni wọ́n ń pe ọmọ Màríà yìí kí wọ́n bàa lè dá a mọ̀ pé òun ni Jésù tó wá láti Násárétì. (Máàkù 10:47) Wọ́n tún mọ̀ ọ́n sí “Kristi,” tàbí Jésù Kristi. (Mátíù16:16) Kí lèyí túmọ̀ sí?

Ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì náà, “Christ” wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, Khri·stosʹ, tó ní ìtumọ̀ kan náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Hébérù náà, Ma·shiʹach (Mèsáyà). Àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí túmọ̀ sí “Ẹni Àmì Òróró.” Ṣáájú Jésù, àwọn kan wà tí wọ́n ń pè ní ẹni àmì òróró lọ́nà tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n pe Mósè, Áárónì àti Dáfídì Ọba ní ẹni àmì òróró, tó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run yàn wọ́n sípò àṣẹ àti àbójútó. (Léfítíkù 4:3; 8:12; 2 Sámúẹ́lì 22:51; Hébérù 11:24-26) Jésù tó jẹ́ Mèsáyà tá a sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ló ta yọ jù lọ nínú àwọn aṣojú Jèhófà. Nítorí náà, Jésù gan-an lẹni tó tọ́ láti máa jẹ́ orúkọ náà, “Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”—Mátíù 16:16; Dáníẹ́lì 9:25.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Bí ayàwòrán kan ṣe ya Flavius Josephus