Ohun Tí Jésù Kọ́ni Nípa Ìjọba Ọlọ́run
Ohun Tí Jésù Kọ́ni Nípa Ìjọba Ọlọ́run
“Ó ń rin ìrìn àjò lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù . . . ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.”—LÚÙKÙ 8:1.
A FẸ́RÀN láti máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣe pàtàkì sí wa, tá a sì mọyì rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Jésù fúnra rẹ̀ ṣe sọ, “lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mátíù 12:34) Tá a bá wo àwọn nǹkan tí Jésù sọ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, a máa rí i pé ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ṣe pàtàkì sí Jésù gan-an.
Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Ìjọba jẹ́ àkóso kan tí ọba ń ṣe olórí rẹ̀. Torí náà, Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso kan tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀. Jésù sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run gan-an, òun ni ìwàásù rẹ̀ dá lé. Ó lé ní ìgbà àádọ́fà [110] tí ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ Jésù kò fi ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan kọ́ni. Ìṣe rẹ̀ tún kọ́ni lóhun tó pọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tí ìjọba náà máa ṣe.
Ta ni Ọba Ìjọba náà? Kì í ṣe àwọn èèyàn ló yan Ọba Ìjọba Ọlọ́run sípò. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló yan Alákòóso yìí sípò. Jésù fi hàn nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, òun ni Ọlọ́run yàn láti jẹ́ Ọba náà.
Jésù mọ̀ pé Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà tá a ṣèlérí máa ṣàkóso lórí Ìjọba àìnípẹ̀kun. (2 Sámúẹ́lì 7:12-14; Dáníẹ́lì 7:13, 14; Mátíù 26:63, 64) Rántí pé Jésù fi hàn ní kedere pé òun ni Mèsáyà tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀. Jésù tipa báyìí jẹ́rìí sí i pé òun ni Ọba tí Ọlọ́run yàn náà. (Jòhánù 4:25, 26) Nítorí náà, ó bá a mu gan-an bí Jésù ṣe máa ń lo gbólóhùn náà “ìjọba mi” láwọn ìgbà kan tó bá ń sọ̀rọ̀.—Jòhánù 18:36.
Jésù tún kọ́ni pé àwọn kan máa wà tó máa bá òun ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 22:28-30) Ó pe àwọn tó máa bá a ṣàkóso yìí ní “agbo kékeré,” torí pé wọ́n máa kéré níye. Ó sọ nípa wọn pé: “Baba yín ti tẹ́wọ́ gba fífi ìjọba náà fún yín.” (Lúùkù 12:32) Ìwé tó gbẹ̀yìn nínú Bíbélì fi hàn pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] èèyàn ló máa láǹfààní láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi.—Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1.
Ibo ni Ìjọba náà wà? Jésù sọ fún alákòóso Róòmù náà Pọ́ńtù Pílátù pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Kì í ṣe àwọn èèyàn ló máa ṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ ìdarí Kristi. Lemọ́lemọ́ ni Jésù máa ń pe Ìjọba Ọlọ́run ní “ìjọba ọ̀run.” a (Mátíù 4:17; 5:3, 10, 19, 20) Torí náà, Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso kan ní ọ̀run.
Lẹ́yìn àkókò tí Jésù ti lò lórí ilẹ̀ ayé, a retí Jòhánù 14:2, 3.
pé kó pa dà sí ọ̀run. Ó sọ pé òun máa “pèsè ibì kan sílẹ̀” níbẹ̀, èyí tó máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú òun láti wá bá òun.—Kí ni Ìjọba náà gbé ṣe? Jésù kọ́ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ láti máa gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Wọ́n ti ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lọ́run. Ìjọba yìí ni Ọlọ́run máa lò láti fi mú ohun tó fẹ́ ṣe fún ilẹ̀ ayé ṣẹ. Kí èyí tó lè ṣeé ṣe, Ìjọba yìí máa ṣàtúnṣe tó kàmàmà lórí ilẹ̀ ayé.
Kí ni Ìjọba náà máa ṣe lórí ilẹ̀ ayé? Jésù kọ́ni pé Ìjọba Ọlọ́run máa mú ibi kúrò, bó sì ṣe máa ṣe é ni pé á pa àwọn tó kọ̀ láti jáwọ́ nínú ìwà ibi run. (Mátíù 25:31-34, 46) Èyí ló sì máa fòpin sí onírúurú ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ibi. Jésù kọ́ni pé, “àwọn onínú tútù,” olóòótọ́, aláàánú, “ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà” àti ẹlẹ́mìí àlàáfíà ló máa kún ilẹ̀ ayé.—Mátíù 5:5-9.
Ṣé inú ayé táwọn èèyàn ti lò bà jẹ́ yìí làwọn olóòótọ́ yẹn á máa gbé? Rárá! Jésù ṣèlérí pé, àyípadà tó yani lẹ́nu máa bá ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ọkùnrin kan tí wọ́n fẹ́ pa tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù sọ pé: “Jésù, rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Jésù dá a lóhùn, ó ní: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:42, 43) Dájúdájú, Ìjọba Ọlọ́run máa yí ayé yìí pa dà di Párádísè, bí ọgbà Édẹ́nì.
Kí tún ni Ìjọba náà máa ṣe fún aráyé? Kì í ṣe ìlérí ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe nìkan ni Jésù sọ. Ó tún fi ohun tí ìjọba náà máa ṣe hàn. Jésù fi iṣẹ́ ìyanu wo ọ̀pọ̀ àìlera sàn, Mátíù 4:23.
ìyẹn sì jẹ́ àpẹẹrẹ ráńpẹ́ nípa ohun ńlá tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú nígbà tó bá ń ṣàkóso Ìjọba náà. Àkọsílẹ̀ àwọn ìwé Ìhìn Rere tí Ọlọ́run mí sí sọ nípa Jésù pé: “Ó lọ yí ká jákèjádò Gálílì, ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà, ó sì ń ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú òkùnrùn àti gbogbo onírúurú àìlera ara láàárín àwọn ènìyàn.”—Jésù wo onírúurú àrùn sàn. Ó “la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú.” (Jòhánù 9:1-7, 32, 33) Jésù rọra fọwọ́ kan ọkùnrin alárùn ẹ̀tẹ̀ kan, ó sì wo ẹ̀tẹ̀ tó ń kóni nírìíra náà sàn. (Máàkù 1:40-42) Nígbà tí wọ́n mú “ọkùnrin adití kan tí ó sì ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ” wá sọ́dọ̀ Jésù, ó fi hàn pé òun lè mú kí “àwọn adití gbọ́ràn, kí àwọn aláìlèsọ̀rọ̀ sì sọ̀rọ̀.”—Máàkù 7:31-37.
Ọba tí Ọlọ́run yàn yìí tún lágbára lórí ikú. Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù jí òkú dìde. Ó jí ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí opó kan bí dìde, ó sì jí ọmọbìnrin ọmọ ọdún méjìlá kan àti Lásárù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ dìde.—Lúùkù 7:11-15; 8:41-55; Jòhánù 11:38-44.
Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ìrètí àgbàyanu tó wà níwájú fún àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, ó tipasẹ̀ àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 1:1; 21:3, 4) Fojú inú wo ayé kan tí kò ti ní sí omijé ìbànújẹ́, ìrora àti ikú! Ìgbà yẹn ni àdúrà náà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run máa ní ìmúṣẹ tó kún rẹ́rẹ́.
Ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa dé? Jésù kọ́ni pé ìgbà tí òun máa bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba máa jẹ́ àkókò kan náà pẹ̀lú ìgbà tó pè ní ìgbà “wíwàníhìn-ín” òun. Jésù sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó máa fìgbà wíwàníhìn-ín rẹ̀ nínú agbára ìṣàkóso rẹ̀ hàn. Ìṣòro lá máa ṣẹlẹ̀ kárí ayé lákòókò náà, tó fi mọ́ ogun, àìtó oúnjẹ, ìsẹ̀lẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn àti ìwà àìlófin tó ń pọ̀ sí i. (Mátíù 24:3, 7-12; Lúùkù 21:10, 11) Èyí àti ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan míì tí Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ wọn ló ti ń ṣẹlẹ̀ láti ọdún 1914, ìyẹn ọdún tí Ogun Àgbáyé Kìíní wáyé. Láti ìgbà yẹn ni Jésù ti ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba. Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run máa dé, ó sì máa mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé. b
Kí ni dídé Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún ẹ? Ọwọ́ ẹ̀ ni gbogbo ìyẹn kù sí àti bó o bá ṣe ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gbólóhùn náà “ìjọba ọ̀run” fara hàn nínú ìwé Ìhìn Rere Mátíù ní nǹkan bí ìgbà ọgbọ̀n.
b Fún àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ lórí bá a ṣe mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé, ka orí 9, tó sọ pé “Ṣé ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn’ La Wà Yìí?,” nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.