Ohun Tí Jésù Kọ́ni Nípa Ara Rẹ̀
Ohun Tí Jésù Kọ́ni Nípa Ara Rẹ̀
“Jésù ò ṣiyè méjì rárá nípa ẹni tí òun jẹ́, ibi tí òun ti wá, ìdí tí òun fi wá sáyé àti ohun tí òun ń retí lọ́jọ́ iwájú.”—ÒǸṢÈWÉ TÓ Ń JẸ́ HERBERT LOCKYER.
KÁ TÓ lè nígbàgbọ́ nínú ohun tí Jésù kọ́ni, a ní láti mọ àwọn nǹkan kan nípa rẹ̀. Ta ni Jésù? Ibo ló ti wá? Kí nìdí tó fi wá sí ayé? A lè gbọ́ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí lẹ́nu Jésù fúnra rẹ̀ nínú ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù.
Ó ti wà láàyè tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó bí i sáyé Jésù sọ nígbà kan pé: “Kí Ábúráhámù tó wà, èmi ti wà.” (Jòhánù 8:58) Ábúráhámù ti gbé ayé ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù. Síbẹ̀, Jésù ti wà láàyè, àní kí Ábúráhámù olóòótọ́ tó gbé ayé. Àmọ́, ibo ni Jésù ti wà tẹ́lẹ̀? Jésù sọ pé: “Èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run.”—Jòhánù 6:38.
Ọmọ Ọlọ́run Jèhófà ní ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ọmọ rẹ̀. Àmọ́, Jésù yàtọ̀. Jésù sọ nípa ara rẹ̀ pé òun jẹ́, “Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run.” (Jòhánù 3:18) Ohun tó sọ yìí fi hàn pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló dá Jésù. Nípasẹ̀ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo yìí, Ọlọ́run dá gbogbo nǹkan yòókù.—Kólósè 1:16.
“Ọmọ Ènìyàn” Ọ̀rọ̀ yìí ni Jésù máa ń lò jù nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀. (Mátíù 8:20) Ohun tó sọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé òun kìí ṣe áńgẹ́lì tàbí ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ tó wá ń gbé lórí ilẹ̀ ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, èèyàn ni. Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, Ọlọ́run mú ìwàláàyè Ọmọ rẹ̀ lọ́run, ó sì fi sínú ilé ọlẹ̀ Màríà tó jẹ́ wúńdíá láyé kó lè lóyún rẹ̀. Àbájáde rẹ̀ ni pé, ó bí Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé, kò sì ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan.—Mátíù 1:18; Lúùkù 1:35; Jòhánù 8:46.
Mèsáyà Tá A Ṣèlérí Náà Obìnrin ará Samáríà kan sọ fún Jésù pé: “Mo mọ̀ pé Mèsáyà ń bọ̀.” Jésù dáhùn pé: “Èmi tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ ni ẹni náà.” (Jòhánù 4:25, 26) Ọ̀rọ̀ náà “Kristi” àti “Mèsáyà,” túmọ̀ sí “Ẹni Àmì Òróró.” Ọlọ́run ló fi òróró yan Jésù, kó bàa lè kó ipa pàtàkì nínú mímú àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣẹ.
Olórí ìdí tó fi wá sáyé Jésù sọ nígbà kan pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run . . . nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe ohun rere fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó nílò ìrànlọ́wọ́, síbẹ̀, wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run ni olórí ohun tó fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Tó bá yá, a máa jíròrò ohun tó kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run.
Ó ṣe kedere pé Jésù kì í ṣe èèyàn kan ṣákálá. a Bá a ṣe máa rí i, gbígbé tí Jésù gbé lọ́run ló jẹ́ kó máa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé iṣẹ́ tó jẹ́ máa ní ipa rere lórí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé síwájú sí i nípa Jésù àti ipa tó kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ, ka orí 4 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.