Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Wàásù “Ìhìn Rere” Ní Àwọn Erékùṣù Jíjìnnà Réré Ní Àríwá Ọsirélíà

A Wàásù “Ìhìn Rere” Ní Àwọn Erékùṣù Jíjìnnà Réré Ní Àríwá Ọsirélíà

A Wàásù “Ìhìn Rere” Ní Àwọn Erékùṣù Jíjìnnà Réré Ní Àríwá Ọsirélíà

JÉSÙ sọ pé, “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mátíù 24:14) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù yìí, a sì ń sapá láti mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn, láìka ibi tí wọ́n ń gbé sí. (Mátíù 28:19, 20) A máa ń yọ̀ọ̀da ara wa láti ṣe iṣẹ́ náà, nígbà míì, pẹ̀lú ìfaradà àti ìnáwónára.

Bí àpẹẹrẹ, Nathan àti Carly, ṣètò ara wọn kí wọ́n bàa lè wàásù fún àwọn tó ń gbé ní àwọn Erékùṣù Torres Strait tí wọ́n wà níbi tó jìnnà réré. Ní ọdún 2003, aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà pè wọ́n, ó ní kí wọ́n ṣí lọ sí Erékùṣù Thursday láti máa bá ìjọ ibẹ̀ ṣiṣẹ́. Erékùṣù yìí jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ àwọn erékùṣù tó wà káàkiri Òkun Pàsífíìkì tó la orílẹ̀-èdè Ọsirélíà àti New Guinea láàárín.

Lọ́dún 2007, ìdílé wọn ra ọkọ̀ ojú omi kan tí wọ́n figi gbẹ́ tí wọ́n ń pè ní Teisan-Y. Owó ara wọn ni wọ́n fi tún inú ọkọ̀ náà ṣe rèǹtèrente, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi rìnrìn àjò láti máa wàásù fún àwọn tó ń gbé ní àwọn erékùṣù mẹ́wàá lára àwọn erékùṣù tó jìnnà réré, wọ́n sì fi Erékùṣù Thursday ṣe ibi tí wọ́n á máa dé sí. Àkọsílẹ̀ nípa díẹ̀ lára ìrìn àjò wọn rèé:

January 2008: Lónìí, mo gbé ọkọ̀ ojú omi kékeré kan lọ sí erékùṣù Bamaga tó jẹ́ ìrìn ọgọ́rin [80] kìlómítà ní àlọ àtàbọ̀ láti lọ gbé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́fà ní àdúgbò yẹn. Ní báyìí, a ti wà nínú ọkọ̀ Teisan-Y, tí à ń lọ sí erékùṣù Warraber àti Poruma. Àgbá epo ọkọ̀ náà kún fún epo àádọ́ta lé ní egbèje [1,450] gálọ́ọ̀nù, dọ́là mẹ́jọ [$8.00] owó ilẹ̀ Ọsirélíà sì ni wọ́n ń ta epo gálọ́ọ̀nù kan. Ọkọ̀ náà kò yára rárá, kìlómítà mẹ́wàá ló ń rìn ní wákàtí kan. Àmọ́, ojú ọjọ́ náà dára gan-an ni, ńṣe ni ojú òkun ń ṣẹ́ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́.

Nígbà tá a débẹ̀, a so ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀ ní etí omi, àwa àtàwọn tó ní ìbátan ní erékùṣù Warraber gbé ọkọ̀ kékeré náà, a sì lọ bá ọ̀kan lára aláṣẹ erékùṣù náà láti gba àṣẹ kí á lè wàásù níbẹ̀. Pásítọ̀ ni aláṣẹ yìí jẹ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò náà, ṣùgbọ́n ó gbà wá láyè láti bá àwọn tó ń gbé ibẹ̀ sọ̀rọ̀. Ohun kan náà la ṣe nígbà tá a dé Poruma, wọ́n sì gbà wá láyè láti wàásù níbẹ̀. Àwọn èèyàn tẹ́wọ́ gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì fẹ́ láti ka àwọn ìwé wa. A bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀.

April 2008: A wéwèé láti lọ sí erékùṣù Dauan, Saibai àti Boigu, àwọn yìí ni erékùṣù mẹ́ta tó jìnnà jù lọ, tí wọ́n wà létí ẹnu ààlà orílẹ̀-èdè Papua New Guinea. Ojú ọjọ́ kò dára rárá, kàkà kí á tẹ̀síwájú, ńṣe la forí lé Erékùṣù Mabuiag. Erékùṣù Mabuiag wà ní àádọ́rin [70] kìlómítà sí ilé wa ní èbúté. Àmọ́, ogóje [140] kìlómítà la máa rìn bá a ṣe ń gba ibi kọ́lọkọ̀lọ àárín àwọn àpáta inú omi náà lọ.

Ìgbì òkun tó lágbára kan gbé ọkọ̀ kékeré kúrò nínú ọkọ̀ Teisan-Y, ó sì gbé e lọ. A ṣẹ́rí ọkọ̀ ńlá wa pa dà láàárín omi láti lọ gbé ọkọ̀ kékeré náà pa dà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tá a jọ wà nínú ọkọ̀ ló ń ṣàìsàn nítorí ìrugùdù omi.

Ní erékùṣù Mabuiag, a gba àṣẹ láti wàásù níbẹ̀, àwọn èèyàn ibẹ̀ sì fọ̀yàyà kí wa káàbọ̀ tá a fi gbàgbé gbogbo ìnira tó bá wa. Inú obìnrin kan dùn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ nígbà tó gbọ́ iṣẹ́ tí à ń jẹ́, èyí sì mú kó gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kún èyí tó ti gbà tẹ́lẹ̀ kó bàa lè fi í sílé ìkàwé àdúgbò tó ti ń ṣiṣẹ́.

May sí October 2008: Nítorí ojú ọjọ́ tí kò dára yìí, a kò lè dé àwọn erékùṣù náà. A lo àkókò yìí láti wàásù ládùúgbò ibi tá a wà, a ṣiṣẹ́ ajé, a sì tún ọkọ̀ wa ṣe.

Ọkọ̀ náà nílò àtúnṣe tó pọ̀, nítorí náà a rìnrìn àjò lọ sí ìlú Weipa tó wà lórí ilẹ̀, a sì fi ọkọ̀ àjàgbé gbé ọkọ̀ ojú omi náà kúrò nínú omi wá sórí ilẹ̀. Èyí kò rọrùn rárá o! Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ìjọ àdúgbò yẹn yọ̀ọ̀da ara wọn láti bá wa ṣe iṣẹ́ náà, irú bí, iṣẹ́ púlọ́ńbà, kíkun ọkọ̀ náà àti fífi igi ṣe ohun èlò sínú rẹ̀. Àwọn míì gbé oúnjẹ wá. Àwọn kan tún fún wa ní àwọn ohun tá a máa nílò láwọn ibi tí a tún máa lọ láti wàásù. Ìfẹ́ àlejò tí wọ́n fi hàn sí wa àti ìrànlọ́wọ́ wọn kọjá sísọ.

December 2008: A tún wéwèé láti lọ sí àwọn erékùṣù Dauan, Saibai àti Boigu. A fi ọgbọ́n yẹra fún ìjì ilẹ̀ olóoru nípa lílo ẹ̀rọ tó ń mọ ìró àti ìgbì, a sì darí ọkọ̀ wa gba àárín àwọn àpáta inú omi nípa lílo àwòrán ìrìn ojú omi. Ó gbà wá ní wákàtí méjìlá gbáko ká tó dé erékùṣù Dauan, àmọ́ erékùṣù yìí ló lẹ́wà jù lọ nínú àwọn èyí tá a tíì rí. Àwọn àpáta gàgàrà wà níbẹ̀ téèyàn á máa wò wọ́n lókèlókè. Àwọn èèyàn erékùṣù Dauan hára gàgà láti gbọ́ ohun tá a fẹ́ sọ, a sì ṣètò láti máa bá ìjíròrò Bíbélì náà nìṣó lórí tẹlifóònù lẹ́yìn tá a pa dà délé.

Obìnrin kan tó ń gbébẹ̀ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lettie ti rí àwọn ìwé ìròyìn wa gbà, ó sì ti fi ìwé pélébé kan ránṣẹ́ pé òun ń fẹ́ ìwé sí i. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Ọsirélíà fi àwọn ìwé ránṣẹ́ sí obìnrin náà, wọ́n sì fi lẹ́tà kan ránṣẹ́ sí ìjọ wa, tó sọ fún wa pé tó bá ṣeé ṣe ká wá a lọ. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, a wá Lettie kàn, a sì láyọ̀ pé a ràn án lọ́wọ́ dé ìwọ̀n àyè kan láti mọ̀ nípa Ọlọ́run.

Ní erékùṣù Saibai, aláṣẹ ibẹ̀ kò gbà wá láyè láti wàásù fún àwọn tó wà ní erékùṣù náà. Àmọ́, ó gba àwọn kan lára wa tí wọ́n ní àwọn ìbátan ní erékùṣù náà láyè láti lọ kí àwọn èèyàn wọn, kí wọ́n sì bá wọn sọ̀rọ̀. Ìjọba ibẹ̀ gbé iṣẹ́ kan fún mi, wọ́n ní kí n bá wọn kun àwọn ilé ní erékùṣù Saibai, èyí sì jẹ́ kí n rí owó ra díẹ̀ lára àwọn ohun tá a nílò.

Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin wa tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tassie jẹ́ ọmọ abúlé kan ní Papua New Guinea tó fi nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rin jìn sí erékùṣù Saibai. Nínú àdéhùn wọn pẹ̀lú ìjọba Ọsirélíà, àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Papua New Guinea lè wá sí erékùṣù Saibai láti ṣòwò. Èyí mú kí Tassie pàdé ọ̀pọ̀ èèyàn tó wá láti abúlé rẹ̀, kò sì ní ìwé tó pọ̀ tó láti fún gbogbo wọn. Látìgbà tí Tassie ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tó máa rí àwọn ará abúlé rẹ̀. Nítorí náà, a lọ gbé ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wá fún un láti ìdí ọkọ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé náà ló jẹ́ ní èdè Píjìn Papua New Guinea, ìyẹn èdè tí wọ́n mọ̀ sí Tok Pisin. Tassie ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì fún àwọn èèyàn tó ju ọgbọ̀n lọ, tí wọ́n jẹ́ ará Papua New Guinea, gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ náà sì gba gbogbo ìwé inú àpótí náà. Ọkọ̀ ojú omi nìkan ló lè dé abúlé tí wọ́n ń gbé, ó sì lè jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò tíì dé ọ̀dọ̀ wọn rí.

Ó nira gan-an láti dé erékùṣù tó kẹ́yìn, ìyẹn erékùṣù Boigu. Kìlómítà mẹ́rin la máa rìn láti etí omi lọ sí orí omi lọ́hùn-ún, mítà méjì ààbọ̀ ni omi náà sì fi jìn. Nǹkan bíi mítà méjì ni ìdí ọkọ̀ ńlá náà fi wọnú omi, nítorí náà omi kò pọ̀ láti jẹ́ kí ọkọ̀ náà lọ geere. Ni èmi àti ọ̀kan lára èrò ọkọ̀ bá lo ọkọ̀ kékeré wa láti wá ọ̀nà tó ṣeé gbà dé erékùṣù náà. Òjò ń ya mùúmùú, gbogbo ara wa rin gbingbin! Ó gbà wá ní wákàtí méjì ká tó lè rí ọ̀nà kan.

Nígbà tá a dé ibẹ̀, ẹnu ya àwọn ará erékùṣù náà gan-an, wọ́n sì sọ fún wa pé àwòrán tá a lò fún ìrìn ojú omi náà kò dára tó àti pé ẹ̀ṣọ́ orí omi tàbí ọmọ ogun ojú omi pàápàá kò jẹ́ gba ibẹ̀. Aláṣẹ erékùṣù náà kò gbà wá láyè láti wàásù, ṣùgbọ́n ó gba àwọn ará wa tí wọ́n ní ìbátan ní erékùṣù náà láyè láti kí wọn, kí wọ́n sì wàásù fún wọn. A bọ̀wọ̀ fún aláṣẹ náà àtohun tó sọ, kìkì àwọn ìbátan wọn nìkan ni wọ́n lọ bá. Ọkùnrin kan gba ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, a ó kà á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ àwọn ìbéèrè sí ẹ̀yìn Bíbélì rẹ̀. A tún kàn sí ọkùnrin yìí nígbà tó wá sí Erékùṣù Thursday.

January 2009: A pa dà lọ sí erékùṣù Moa àti Mabuiag láti bá àwọn tó fìfẹ́ hàn sí ìhìn rere inú Bíbélì sọ̀rọ̀. Ní erékùṣù méjèèjì yìí, wọ́n tẹ́wọ́ gbà wá tìdùnnú-tìdùnnú. Ọ̀pọ̀ èèyàn ní abúlé St. Paul tó wà ní Erékùṣù Moa sọ fún wa pé kí a má ṣe pẹ́ ká tó pa dà wá. Aláṣẹ ibẹ̀ sọ fún wa pé àwọn tẹ́wọ́ gbà wá láti wàásù ní abúlé náà nígbàkigbà tá a bá fẹ́.

Erékùṣù mẹ́tàdínlógún ló wà ní àgbègbè Torres Strait, ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. A kò mọ bó ṣe máa rọrùn fún wa tó láti bá gbogbo àwọn tó ń gbé ibẹ̀ sọ̀rọ̀. Àmọ́ gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ ní àwọn erékùṣù jíjìnnà réré ní àríwá Ọsirélíà láyọ̀ láti ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti mú ìyìn bá Jèhófà, Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ỌSIRÉLÍÀ

Weipa

Bamaga

ÀWỌN ERÉKÙṢÙ TORRES STRAIT

PAPUA NEW GUINEA

[Credit Line]

Látinú fọ́tò NASA/Visible Earth imagery

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Bamaga

Erékùṣù Thursday

Erékùṣù Moa

Erékùṣù Warraber

Erékùṣù Poruma

Erékùṣù Mabuiag

Erékùṣù Saibai

Erékùṣù Dauan

Erékùṣù Boigu

PAPUA NEW GUINEA

[Credit Line]

Látinú fọ́tò NASA/Visible Earth imagery

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Nígbà tá a dé Erékùṣù Thursday

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

À ń rìn lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó ń gbé Erékùṣù Saibai

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

A wàásù ní èdè Tok Pisin