Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nígbà Tí ‘Ọkàn Tí Ó Ní Ìròbìnújẹ́ Tí Ó sì Wó Palẹ̀’ Bá Tọrọ Ìdáríjì

Nígbà Tí ‘Ọkàn Tí Ó Ní Ìròbìnújẹ́ Tí Ó sì Wó Palẹ̀’ Bá Tọrọ Ìdáríjì

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Nígbà Tí ‘Ọkàn Tí Ó Ní Ìròbìnújẹ́ Tí Ó sì Wó Palẹ̀’ Bá Tọrọ Ìdáríjì

2 SÁMÚẸ́LÌ 12:1-14

GBOGBO wa la máa ń dẹ́ṣẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Bó ti wù kí ohun tá a ṣe dùn wá tó, a lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘ǹjẹ́ Ọlọ́run gbọ́ àdúrà àtọkànwá tí mo gbà pé kó dárí jì mí? Ṣé á dárí jì mí?’ Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó fini lọ́kàn balẹ̀ yìí pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kò fara mọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ó múra tán láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. Òtítọ́ yìí hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì àtijọ́, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé 2 Sámúẹ́lì orí 12.

Fojú inú wo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀. Dáfídì jẹ̀bi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan. Ó ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà, nígbà tí gbogbo akitiyan rẹ̀ láti bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀ sì já sásán, ó ṣètò pé kí wọ́n pa ọkọ obìnrin náà. Fún ọ̀pọ̀ oṣù, Dáfídì ṣẹnu mẹ́rẹ́n bíi pé kò ṣe nǹkan kan. Àmọ́, Jèhófà rí ohun tó ṣẹlẹ̀. Ó rí ẹ̀ṣẹ̀ tí Dáfídì dá. Àmọ́, ó tún mọ̀ pé ọkàn Dáfídì kò burú débi tí kò fi ní ronú pìwà dà. (Òwe 17:3) Kí ni Jèhófà wá ṣe?

Jèhófà rán wòlíì Nátánì sí Dáfídì. (Ẹsẹ 1) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, Nátánì wá ọgbọ́n tó máa fi bá ọba sọ̀rọ̀, ó sì mọ̀ pé ó yẹ kí òun ronú lórí ọ̀rọ̀ tóun máa lò. Báwo ló ṣe máa jẹ́ kí Dáfídì mọ̀ pé ńṣe ló ń tan ara rẹ̀ jẹ, tó sì máa jẹ́ kó rí bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣe lágbára tó?

Kí Dáfídì má bàa wá àwáwí, Nátánì sọ ìtàn kan tó dájú pé ó máa wọ ọba tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn yìí lọ́kàn. Ìtàn náà dá lórí ọkùnrin méjì, ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ tálákà. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà ní “àgùntàn àti màlúù púpọ̀ gan-an,” àmọ́ “abo ọ̀dọ́ àgùntàn kan” ni ọkùnrin tálákà náà ní. Àlejò wá kí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà, ó sì fẹ́ se oúnjẹ fún un. Àmọ́ dípò kó mú ọ̀kan lára àwọn àgùntàn rẹ̀, àgùntàn kan ṣoṣo tó jẹ́ ti ọkùnrin tálákà yẹn ló mú. Dáfídì rò pé ìtàn yẹn ṣẹlẹ̀ lóòótọ́, ló bá fi ìbínú sọ pé: “Ikú tọ́ sí ọkùnrin tí ó ṣe èyí!” Kí nìdí? Dáfídì ṣàlàyé, ó ní: “Nítorí pé kò ní ìyọ́nú.” aẸsẹ 2 sí 6.

Ìtàn náà ṣe ohun tí Nátánì fẹ́ kó ṣe. Dáfídì ti ṣèdájọ́ ara rẹ̀. Nátánì wá jẹ́ kó yé e pé: “Ìwọ fúnra rẹ ni ọkùnrin náà!” (Ẹsẹ 7) Bí Nátánì ṣe gbẹnu sọ fún Ọlọ́run yìí fi hàn pé inú Jèhófà kò dùn sí ohun tí Dáfídì ṣe. Bí Dáfídì ṣe rú òfin Ọlọ́run yẹn fi hàn pé kò bọ̀wọ̀ fún Ẹni tó ṣòfin náà. Ọlọ́run sọ pé: “O tẹ́ńbẹ́lú mi.” (Ẹsẹ 10) Ìbáwí yìí wọ ọkàn Dáfídì gan-an, torí náà ó jẹ́wọ́, ó ní: “Èmi ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.” Nátánì fi Dáfídì lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa dárí jì í, àmọ́ ó máa jìyà ohun tó ṣe yẹn.—Ẹsẹ 13 àti 14.

Lẹ́yìn tí àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì tú, ó ṣàkọsílẹ̀ ohun tó wá di Sáàmù 51. Nínú àkọsílẹ̀ náà, Dáfídì sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, èyí tó fi bí ìrònúpìwàdà rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó hàn. Ńṣe ni Dáfídì fi ẹ̀ṣẹ̀ tó dá yìí tẹ́ńbẹ́lú Jèhófà. Àmọ́ nígbà tí ọba tó ti ronú pìwà dà yìí rí ìdáríjì Ọlọ́run gbà, ó wá sọ fún Jèhófà pé: “Ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀ ni ìwọ, Ọlọ́run, kì yóò tẹ́ńbẹ́lú.” (Sáàmù 51:17) Ṣàṣà lọ̀rọ̀ tó máa tu ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ń wá àánú Jèhófà nínú tó bí èyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Pípa àgùntàn fún àlejò jẹ́ ọ̀nà kan láti gbà ṣeni lálejò. Àmọ́ ìwà ọ̀daràn ni téèyàn bá jí àgùntàn, ìjìyà tó wà fún ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, á san mẹ́rin dípò ẹyọ kan tí ó jí. (Ẹ́kísódù 22:1) Lójú Dáfídì, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn kò láàánú rárá bó ṣe mú àgùntàn yẹn. Ńṣe ló tipasẹ̀ ohun tó ṣe yìí gba ẹran tó lè máa pèsè wàrà àti irun àgùntàn tí ìdílé ọkùnrin tálákà náà nílò, tó sì máa bí àwọn ọmọ tó máa di agbo àgùntàn ọkùnrin yìí.