Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Agbèjà Ìgbàgbọ́—Ṣé Ajàfẹ́sìn Kristẹni Ni Wọ́n Ni àbí Onímọ̀ Ọgbọ́n Orí?

Àwọn Agbèjà Ìgbàgbọ́—Ṣé Ajàfẹ́sìn Kristẹni Ni Wọ́n Ni àbí Onímọ̀ Ọgbọ́n Orí?

Àwọn Agbèjà Ìgbàgbọ́—Ṣé Ajàfẹ́sìn Kristẹni Ni Wọ́n Ni àbí Onímọ̀ Ọgbọ́n Orí?

DÍẸ̀ lára àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni ni ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan, ṣíṣekúpa ọmọdé, pípa èèyàn jẹ. Èyí yọrí sí ọ̀pọ̀ àtakò tó mú kí àwọn Kristẹni tó jẹ́ òǹkọ̀wé fẹ́ láti gbèjà ìgbàgbọ́ wọn. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn mọ̀ wọ́n sí agbèjà ìgbàgbọ́, ìfẹ́ ọkàn àwọn òǹkọ̀wé yìí ni láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ìsìn àwọn kì í ṣe eléwu kí àwọn aláṣẹ Róòmù àtàwọn ará ìlú bàa lè máa fojú ire wò wọ́n. Ewu ńlá ni ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yìí, torí pé ohun kan ṣoṣo téèyàn lè ṣe láti tẹ́ àwọn aláṣẹ Róòmù àtàwọn èèyàn náà lọ́rùn ni pé kéèyàn fara mọ́ ohun tí wọ́n fẹ́. Ewu míì ni pé, ìyẹn lè mú káwọn aláṣẹ gbé àtakò gbígbóná dìde tàbí kí àwọn Kristẹni pa ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tì nítorí kí wọ́n lè tẹ́ àwọn èèyàn lọ́rùn. Báwo làwọn agbèjà ìgbàgbọ́ náà ṣe gbèjà ìgbàgbọ́ wọn? Àlàyé wo ni wọ́n ṣe? Kí ló sì jẹ́ àbájáde ìsapá wọn?

Àwọn Agbèjà Ìgbàgbọ́ Bá Àwọn Aláṣẹ Róòmù Sọ̀rọ̀

Ọ̀mọ̀wé làwọn agbèjà ìgbàgbọ́ yìí, ọgọ́rùn-ún ọdún kejì àti apá ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta ni wọ́n gbé láyé. Àwọn tó lókìkí jù lọ nínú wọn ni Justin Martyr, Clement ti ìlú Alẹkisáńdíríà àti Tertullian. a Àwọn kèfèrí àtàwọn aláṣẹ Róòmù ni wọ́n darí ìwé wọn sí láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni, lemọ́lemọ́ ni wọ́n sì ń fi àwọn ẹsẹ Bíbélì sínú ìwé wọn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ kojú àwọn alátakò, wọ́n ní irọ́ ni gbogbo ẹ̀sùn wọn, wọ́n sì sọ pé àwọn Kristẹni kì í ṣe eléwu ẹ̀dá.

Olórí ohun tó wà lọ́kàn àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ ni láti mú un dá àwọn aláṣẹ òṣèlú lójú pé àwọn Kristẹni kì í ṣe ọ̀tá olú ọba tàbí ti ilẹ̀ ọba Róòmù. Tertullian sọ nípa olú ọba pé “Ọlọ́run wa ti yàn án,” Athenagoras sì sọ pé, ó yẹ kí àǹfààní ipò olú ọba máa wà títí lọ nínú ìdílé kan náà, lòun náà bá lọ́wọ́ nínú òṣèlú àkókò yẹn. Wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pa ọ̀rọ̀ Jésù Kristi tì, èyí tó sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.”—Jòhánù 18:36.

Àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ tún sọ pé ó yẹ kí àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín Róòmù àti ẹ̀sìn Kristẹni. Ọ̀gbẹ́ni Melito sọ pé, ńṣe ni ètò méjèèjì yìí jọ ń ṣiṣẹ́, wọ́n sì ń jẹ́ kí nǹkan máa lọ déédéé ní ilẹ̀ ọba náà. Òǹkọ̀wé kan tá ò mọ orúkọ rẹ̀ tó kọ ìwé The Epistle to Diognetus sọ pé àwọn Kristẹni jẹ́ èèyàn pàtàkì tó jẹ́ kí ‘ayé wà níṣọ̀kan.’ Tertullian sì tún kọ̀wé pé, àwọn Kristẹni ń gbàdúrà fún aásìkí ilẹ̀ ọba Róòmù àti pé kí òpin ètò àwọn nǹkan yìí má tètè dé. Àbájáde èyí ni pé, dídé Ìjọba Ọlọ́run kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì sí wọn mọ́.—Mátíù 6:9, 10.

Wọ́n Mú Ìmọ̀ Ọgbọ́n Orí Wọnú Ẹ̀sìn Kristẹni

Onímọ̀ ọgbọ́n orí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Celsus fi àwọn Kristẹni ṣe yẹ̀yẹ́, ó pè wọ́n ní “aláàárù, àwọn tó ń ṣe bàtà, àgbẹ̀, òpè àti ọ̀dẹ̀.” Ọ̀rọ̀ yìí dun àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ gan-an. Torí náà, wọ́n pinnu pé àwọn á dọ́gbọ́n míì kí àwọn èèyàn lè máa fojú ire wò wọ́n. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fara mọ́ ọgbọ́n ayé tẹ́lẹ̀, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó láti fi ṣàlàyé ohun tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, Clement ti Alẹkisáńdíríà ka ìmọ̀ ọgbọ́n orí sí “ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀gbẹ́ni Justin sọ pé òun kò fara mọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn kèfèrí, òun ló kọ́kọ́ fi èrò àti ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Kristẹni, ó ka irú ìmọ̀ ọgbọ́n orí yìí sí “ohun tí kò léwu, tó sì ń ṣeni láǹfààní.”

Látìgbà yẹn lọ, ohun tí wọ́n ṣe ni pé wọn ò ta ko ìmọ̀ ọgbọ́n orí mọ́, àmọ́ wọ́n fẹ́ sọ èrò àwọn Kristẹni di ìmọ̀ ọgbọ́n orí tó ga ju ti àwọn kèfèrí lọ. Ọ̀gbẹ́ni Justin sọ pé, “Lórí àwọn kókó kan, a máa ń kọ́ni nírú àwọn nǹkan tí àwọn akéwì àti onímọ̀ ọgbọ́n orí tẹ́ ẹ bọ̀wọ̀ fún ń kọ́ni, lórí àwọn kókó míì sì rèé, àlàyé wa kún rẹ́rẹ́ ju tiwọn lọ, a sì ń kọ́ni nípa Ọlọ́run.” Ọ̀nà tuntun tó ń gbà ṣàlàyé ara rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí yìí mú káwọn èèyàn wá ka ẹ̀kọ́ táwọn agbèjà ìgbàgbọ́ pè lẹ́kọ̀ọ́ Kristẹni yìí sí òtítọ́ tó gbayì tó yẹ kéèyàn máa tẹ̀ lé. Àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ sọ pé àwọn ìwé ẹ̀sìn Kristẹni ti wà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìwé àwọn Gíríìkì àti pé àwọn wòlíì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn ti gbé láyé ṣáájú àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ará ilẹ̀ Gíríìkì. Àwọn kan lára àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ tiẹ̀ sọ pé ńṣe làwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí kàn ń ṣàfarawé àwọn wòlíì. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé ọmọ ẹ̀yìn Mósè ni Plato!

Wọ́n Sọ Ẹ̀kọ́ Kristẹni Dìdàkudà

Ọ̀nà tuntun yìí mú kí wọ́n pa ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni pọ̀ mọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn kèfèrí. Wọ́n wá ń fi àwọn ọlọ́run Gíríìkì wé àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn. Wọ́n fi Jésù wé Perseus, wọ́n sì fi Màríà tó lóyún Jésù wé Danaë, ìyá Perseus tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ wúńdíá.

Ìyípadà tó bá àwọn ẹ̀kọ́ kan kì í ṣe kékeré. Bí àpẹẹrẹ, nínú Bíbélì, wọ́n pe Jésù ní “Logos,” èyí tó túmọ̀ sí “Ọ̀rọ̀” Ọlọ́run tàbí Agbẹnusọ. (Jòhánù 1:1-3, 14-18; Ìṣípayá 19:11-13) Ó ti pẹ́ gan-an tí Justin ti sọ ẹ̀kọ́ yìí dìdàkudà, bíi ti àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí, ó lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì méjì kan tí logos lè túmọ̀ sí, ìyẹn “ọ̀rọ̀” àti “orí pípé.” Ó ní, àwọn Kristẹni rí ọ̀rọ̀ náà gbà, ìyẹn Kristi fúnra rẹ̀. Àmọ́, nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí logos ṣe túmọ̀ sí orí pípé, ó sọ pé gbogbo èèyàn ló ní orí pípé títí kan àwọn kèfèrí. Nítorí náà, ó sọ pé, Kristẹni ni gbogbo èèyàn tó bá ń gbé ayé pẹ̀lú orí pípé, títí kan àwọn aláìgbà-pọ́lọ́run-wà tàbí àwọn táwọn èèyàn rò pé wọn kò gbà pé Ọlọ́run wà, àwọn bíi Socrates àtàwọn míì.

Àmọ́ bí àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ yìí, títí kan Tertullian ṣe ń fi tipátipá ṣàlàyé pé Jésù àti logos ti àwọn Gíríìkì onímọ̀ ọgbọ́n orí jọra, ìyẹn nǹkan tó jẹ mọ́ Ọlọ́run, wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ dáwọ́ lé ohun kan tó wá yọrí sí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. b

Ó lé ní ìgbà ẹgbẹ̀rin ó lé àádọ́ta [850] tí ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” fara hàn nínú Bíbélì, yàtọ̀ síyẹn, ó tún lé ní ìgbà ọgọ́rùn-ún [100] tó fara hàn lédè Gíríìkì. Ohun tó túmọ̀ sí ni ẹni kíkú, ohun alààyè, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹranko. (1 Kọ́ríńtì 15:45; Jákọ́bù 5:20; Ìṣípayá 16:3) Àmọ́ àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ lọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí po bí wọ́n ṣe fi wé ìmọ̀ ọgbọ́n orí Plato pé ọkàn máa ń fi ara sílẹ̀, pé kò ṣeé fojú rí àti pé kò lè kú. Ọ̀gbẹ́ni Minucius Felix tiẹ̀ sọ pé látinú ẹ̀kọ́ Pythagoras pé ọkàn máa ń ṣípò pa dà ni ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde ti wá. Ẹ ò rí i pé àkóbá táwọn Gíríìkì ṣe fún àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ ti mú kí wọ́n yapa kúrò nínú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì!

Àṣìṣe Wọn

Àwọn kan lára àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ rí àkóbá tí ìmọ̀ ọgbọ́n orí lè ṣe fún ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ta ko àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí, síbẹ̀ wọ́n ṣì fẹ́ràn ìmọ̀ ọgbọ́n orí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gbẹ́ni Tatian, bẹnu àtẹ́ lu àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí pé wọn kò ṣàṣeyọrí kankan, àmọ́ lẹ́sẹ̀ kan náà, ó pe ẹ̀sìn Kristẹni ní “ìmọ̀ ọgbọ́n orí tiwa,” ó sì lọ́wọ́ sí ìméfò tí wọ́n fi ìmọ̀ ọgbọ́n orí gbé kalẹ̀. Ní ti ọ̀gbẹ́ni Tertullian, ó ta ko ipa tí ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn kèfèrí ní lórí èrò àwọn Kristẹni. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó sọ pé òun fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ “ọ̀gbẹ́ni Justin, tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí àti ajẹ́rìíkú àti ọ̀gbẹ́ni Miltiades, tó jẹ́ olùkọ́ ẹ̀kọ́ ọgbọ́n orí láwọn ṣọ́ọ̀ṣì” àtàwọn èèyàn míì. Ọ̀gbẹ́ni Athenagoras pe ara rẹ̀ ní “Kristẹni onímọ̀ ọgbọ́n orí ilẹ̀ Áténì.” Ní ti ọ̀gbẹ́ni Clement, wọ́n ní ó sọ pé èrò òun ni pé “àwọn Kristẹni lè lo ìmọ̀ ọgbọ́n orí lọ́nà tó dáa, tó sì mọ́gbọ́n dání, wọ́n sì lè fi gbèjà ìgbàgbọ́.”

Àṣeyọrí yòówù táwọn agbèjà ìgbàgbọ́ ì báà ti ṣe nínú bí wọ́n ṣe gbèjà ìgbàgbọ́ wọn, kò sí iyè méjì pé wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá látàrí ìgbèjà yìí. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni létí pé láàárín àwọn ohun tá a fi ń ja ìjà tẹ̀mí tá a ní, kò sí èyí tó lágbára ju “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” èyí tó ‘yè, tó sì ń sa agbára.’ Pọ́ọ̀lù sọ pé, “àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga fíofío tí a gbé dìde lòdì sí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run ni àwa ń [fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run] dojú wọn dé.”—Hébérù 4:12; 2 Kọ́ríńtì 10:4, 5; Éfésù 6:17.

Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòhánù 16:33) Gbogbo àdánwò àti inúnibíni tó dé bá a nígbà tó wà láyé kò borí ìgbàgbọ́ àti ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí Baba rẹ̀. Bákan náà, Jòhánù tó kú gbẹ̀yìn lára àwọn àpọ́sítélì kọ̀wé pé: “Èyí . .  ni ìṣẹ́gun tí ó ti ṣẹ́gun ayé, ìgbàgbọ́ wa.” (1 Jòhánù 5:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ fẹ́ gbèjà ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni, àṣìṣe wọn ni pé wọ́n fàyè gba èrò àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí ayé. Àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ jẹ́ kí irú àwọn ìmọ̀ ọgbọ́n orí bẹ́ẹ̀ tan àwọn jẹ, wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ayé ṣẹ́gun wọn àti ọ̀nà ìjọsìn wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Torí náà, dípò kí wọ́n borí, kí wọ́n sì jà fún ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni, ńṣe làwọn agbèjà ìgbàgbọ́ nínú ṣọ́ọ̀ṣì àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣubú sínú páńpẹ́ tí Sátánì dẹ láìmọ̀, ìyẹn ẹni tó ń “pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.”—2 Kọ́ríńtì 11:14.

Lóde òní, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn agbèjà ìgbàgbọ́ gan-an. Dípò kí wọ́n fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbèjà ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́, ńṣe ni wọ́n máa ń fojú kéré Bíbélì tí wọ́n sì ń lo ìmọ̀ ọgbọ́n orí ayé nínú ẹ̀kọ́ wọn kí aráyé àtàwọn ọmọ ìjọ wọn lè gba tiwọn. Dípò kí wọ́n kìlọ̀ fún àwọn èèyàn nípa ewu tó wà lẹ́yìn títẹ̀lé àwọn nǹkan tí ayé ń ṣe tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, ńṣe ni wọ́n di olùkọ́ tó ń ‘rin etí’ àwọn olùgbọ́ wọn kí wọ́n má bàa kúrò lọ́dọ̀ wọn. (2 Tímótì 4:3) Ó bani nínú jẹ́ pé, bíi tàwọn agbèjà ìgbàgbọ́ ayé àtijọ́, àwọn olùkọ́ yìí ti pa ìkìlọ̀ àwọn àpọ́sítélì tì, èyí tó sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.” Wọ́n rán wa létí pé “òpin wọn dájúdájú yóò rí bí iṣẹ́ wọn.”—Kólósè 2:8; 2 Kọ́ríńtì 11:15.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn òǹkọ̀wé míì ni Quadratus, Aristides, Tatian, Apollinaris, Athenagoras, Theophilus, Melito, Minucius Felix àtàwọn míì táwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀. Wo Ilé Ìṣọ́ May 15, 2003, ojú ìwé 27 sí 29 àti March 15, 1996, ojú ìwé 28 sí 30.

b Fún àlàyé síwájú sí i lórí ìgbàgbọ́ Tertullian, ka Ilé Ìṣọ́ May 15, 2002, ojú ìwé 29 sí 31.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 31]

“Àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga fíofío tí a gbé dìde lòdì sí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run ni àwa ń dojú wọn dé.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 10:5

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Lójú ọ̀gbẹ́ni Justin, títẹ̀lé ìmọ̀ ọgbọ́n orí jẹ́ “ohun tí kò léwu, tó sì ń ṣeni láǹfààní”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ọ̀gbẹ́ni Clement ka ìmọ̀ ọgbọ́n orí sí “ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ìmọ̀ ọgbọ́n orí tí ọ̀gbẹ́ni Tertullian gbé kalẹ̀ lànà sílẹ̀ fún ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ọ̀gbẹ́ni Tatian pe ẹ̀sìn Kristẹni ní “ìmọ̀ ọgbọ́n orí tiwa”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn lóde òní ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn agbèjà ìgbàgbọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé ká ṣọ́ra fún ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn èèyàn

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]

Clement: Historical Pictures Service; Tertullian: © Bibliothèque nationale de France