Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Tó Kọ̀wé Nípa Jésù

Àwọn Tó Kọ̀wé Nípa Jésù

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Àwọn Tó Kọ̀wé Nípa Jésù

ǸJẸ́ o máa ń gbádùn ìtàn nípa Jésù nígbà tẹ́ ẹ bá jùmọ̀ ń kà á?— a Ó ya àwọn kan lẹ́nu pé Jésù kò kọ ibì kankan nínú Bíbélì. Síbẹ̀, àwọn mẹ́jọ kan lára àwọn tí wọ́n kọ Bíbélì sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa nípa Jésù. Ìgbà kan náà ni wọ́n gbé láyè pẹ̀lú Jésù, wọ́n sì sọ nípa ohun tó kọ́ni. Ṣé o lè dárúkọ àwọn mẹ́jọ náà?— Àwọn ni Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù. Àwọn mẹ́rin yòókù ni Pétérù, Jákọ́bù, Júdà àti Pọ́ọ̀lù. Kí lo mọ̀ nípa àwọn òǹkọ̀wé yìí?—

Jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn òǹkọ̀wé mẹ́ta tí wọ́n wà lára àwọn àpọ́sítélì Jésù méjìlá. Ṣé o mọ orúkọ wọn?— Àwọn ni Pétérù, Jòhánù àti Mátíù. Pétérù kọ lẹ́tà méjì sí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni. Ó sọ fún wọn nípa ohun tó mọ̀ pé Jésù ṣe àti ohun tó sọ. Ṣí Bíbélì rẹ sí 2 Pétérù 1:16-18, kó o kà nípa ohun tí Pétérù sọ nípa bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe bá Jésù sọ̀rọ̀ láti ọ̀run.—Mátíù 17:5.

Àpọ́sítélì Jòhánù kọ márùn-ún lára àwọn ìwé inú Bíbélì. Òun ló jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù lálẹ́ ọjọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn jẹun pẹ̀lú Jésù kó tó kú. Jòhánù tún wà lọ́dọ̀ Jésù lọ́jọ́ tó kú. (Jòhánù 13:23-26; 19:26) Jòhánù kọ ọ̀kan lára ìwé Bíbélì mẹ́rin tó sọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù, tá à ń pè ní ìwé Ìhìn Rere. Ó tún kọ àwọn ohun tí Jésù fi hàn án àti lẹ́tà mẹ́ta nínú Bíbélì tá à ń fi orúkọ rẹ̀ pè. (Ìṣípayá 1:1) Mátíù ni ẹnì kẹta tó jẹ́ àpọ́sítélì Jésù tó kọ lára Bíbélì. Agbowó orí ni tẹ́lẹ̀.

Àwọn méjì kan lára àwọn tó kọ Bíbélì mọ Jésù lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àbúrò rẹ̀ ni wọ́n, torí pé Màríà tó jẹ́ ìyá Jésù ló bí wọn fún Jósẹ́fù. (Mátíù 13:55) Wọn ò kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù nígbà tó ń wàásù. Wọ́n tiẹ̀ rò pé orí rẹ̀ ti yí ni nítorí bó ṣe ń fìtara wàásù. (Máàkù 3:21) Àwọn wo ni àbúrò rẹ̀ yìí?— Jákọ́bù jẹ́ ọ̀kan. Òun ló kọ ìwé Jákọ́bù inú Bíbélì. Júdásì ni ẹnì kejì, wọ́n tún ń pè é ní Júdà. Òun ló kọ ìwé Júdà inú Bíbélì.—Júdà 1.

Àwọn méjì míì tí wọ́n kọ nípa ìgbésí ayé Jésù ni Máàkù àti Lúùkù. Ìyá Máàkù ní ilé ńlá kan sí ìlú Jerúsálẹ́mù, àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ máa ń pàdé níbẹ̀, àpọ́sítélì Pétérù náà wà lára wọn. (Ìṣe 12:11, 12) Lọ́dún mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn, ìyẹn lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù ṣe Ìrékọjá tó kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Máàkù bá Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ sínú ọgbà Gẹtisémánì. Nígbà tí wọ́n mú Jésù, àwọn sójà gbá Máàkù mú, àmọ́ ó fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì sá lọ.—Máàkù 14:51, 52.

Dókítà tó kàwé dáadáa ni Lúùkù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí Jésù kú ló di ọmọ ẹ̀yìn. Ó fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù, ó sì kọ ìtàn tó yéni tó sì péye nípa rẹ̀. Nígbà tó yá, Lúùkù bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò láti lọ wàásù, òun ló sì tún kọ ìwé Ìṣe inú Bíbélì.—Lúùkù 1:1-3; Ìṣe 1:1.

Pọ́ọ̀lù ni ẹnì kẹjọ lára àwọn tó kọ nípa Jésù nínú Bíbélì. Ọ̀dọ̀ Gàmálíẹ́lì tó jẹ́ amòfin táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ló ti kẹ́kọ̀ọ́. Àwọn Farisí ló kọ́ Pọ́ọ̀lù lẹ́kọ̀ọ́, Sọ́ọ̀lù ni wọ́n ń pè é nígbà yẹn, ọ̀dọ̀ wọn ló sì dàgbà sí, ìyẹn ló mú kó kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ó sì lọ́wọ́ nínú ikú àwọn kan lára wọn. (Ìṣe 7:58–8:3; 22:1-5; 26:4, 5) Ǹjẹ́ o mọ bí Pọ́ọ̀lù ṣe mọ òtítọ́ nípa Jésù?—

Lójú ọ̀nà Damásíkù nígbà tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ lọ mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, lójijì ni ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò kan láti ọ̀run fọ́ ọ lójú. Ó gbọ́ ohùn kan tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” Jésù ló sọ̀rọ̀ yìí! Ó sọ fún Pọ́ọ̀lù pé kó lọ sí ìlú Damásíkù. Jésù wá darí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Ananíà pé kó lọ bá Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀, Pọ́ọ̀lù sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Ìṣe 9:1-18) Ìwé Bíbélì mẹ́rìnlá ni Pọ́ọ̀lù kọ, látorí ìwé Róòmù títí dé ìwé Hébérù.

Ṣé o ti ń ka àwọn ìwé Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa Jésù àbí ẹnì kan ti ń kà á fún ẹ?— Ọ̀kan lára ohun tó dáa jù lọ tó o lè ṣe nígbèésí ayé rẹ ni pé kó o bẹ̀rẹ̀ nísinsìnyí tó o ṣì kéré, kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa Jésù.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.

ÌBÉÈRÈ:

▪ Àwọn àpọ́sítélì Jésù wo ló wà lára àwọn tó kọ Bíbélì?

▪ Àwọn méjì wo lára àwọn tó kọ Bíbélì ni wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá Jésù?

▪ Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún Máàkù láti mọ Jésù, àmọ́ kí ló ṣeé ṣe tí Lúùkù kò fi mọ̀ ọ́n?

▪ Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe di ọmọ ẹ̀yìn Jésù?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Júdà

Máàkù

Pétérù

Mátíù

Pọ́ọ̀lù

Jákọ́bù

Lúùkù

Jòhánù