Aráyé Kò Ka Ẹ̀ṣẹ̀ Sí Nǹkan Kan Mọ́
Aráyé Kò Ka Ẹ̀ṣẹ̀ Sí Nǹkan Kan Mọ́
NÍGBÀ kan rí, àwọn èèyàn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì máa ń gbọ́ táwọn oníwàásù máa ń sọ̀rọ̀ fatafata látorí àga ìwàásù pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tí wọn kò gbọ́dọ̀ dá, torí ó lè yọrí sí ikú. Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà ni, “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, bíbá ẹ̀mí èṣù sọ̀rọ̀, ìlépa ọrọ̀, ìṣẹ́yún, ìbọ̀rìṣà, owú àti ìbúra èké.” Ọ̀pọ̀ ìgbà ni oníwàásù náà máa ń ṣàlàyé àgbákò tí ẹ̀ṣẹ̀ ń fà, ó sì máa ń rọ àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n ronú pìwà dà. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Nísinsìnyí, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn oníwàásù kì í sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ torí pé kì í jẹ́ kí ara tu àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó máa mára tu àwọn èèyàn ni wọ́n ń sọ.”
Àwọn akọ̀ròyìn náà ti ṣàkíyèsí pé bọ́ràn ṣe rí níbi gbogbo nìyẹn. Ohun táwọn ìwé ìròyìn kan sọ rèé:
▪ “Àwọn èèyàn kò ka ẹ̀ṣẹ̀, ìrònúpìwàdà àti ìtúnràpadà sí pàtàkì mọ́, ohun táwọn èèyàn kà sí ní báyìí ni àwọn ọ̀rọ̀ tó máa tù wọ́n lára bí ìgbéra-ẹni-lárugẹ àti ìfẹ́ ara ẹni.”—Star Beacon, Ashtabula, Ohio.
▪ “Àwọn èèyàn kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí nǹkan kan mọ́.”—Newsweek.
▪ “A kò tún béèrè mọ́ pé, ‘Kí ni Ọlọ́run fẹ́ kí n ṣe?’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ‘Nǹkan tá a máa rí gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run’ là ń béèrè.”—Chicago Sun-Times.
Lóde òní, à ń gbé nínú àwùjọ tó ní onírúurú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, èyí sì mú káwọn èèyàn fàyè gba oríṣiríṣi èrò, wọn kì í sì í fẹ́ sọ pé ohun kan dáa tàbí kò dáa. Wọ́n ní téèyàn bá sọ pé ohun kan dáa tàbí kò dáa kò ní jẹ́ káwọn èèyàn máa gbé níṣọ̀kan. Ó jọ pé ẹ̀ṣẹ̀ tó tóbi jù lọ ni kéèyàn máa sọ pé ìwà tẹ́nì kan hù kò dára. Nítorí náà, ohun táwọn èèyàn ń sọ nísinsìnyí ni pé: ‘O lè gbà pé ohun kan lè ṣe ẹ́ láǹfààní, àmọ́ má ṣe fipá mú ẹlòmíì láti gba ohun náà. Ní ìgbà tiwa yìí, èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ táwọn èèyàn ní ló mú kí wọ́n máa gbé irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé. Kò sẹ́ni tó lè sọ pé èrò tòun nìkan ló tọ̀nà. Èrò àwọn yòókù náà tọ̀nà gẹ́gẹ́ bí èrò tìrẹ náà ṣe tọ̀nà.’
Èrò tí àwọn èèyàn ní yìí ti mú kí ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ń lò nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ yí pa dà. Àwọn èèyàn kì í sábà lo ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀ṣẹ̀” mọ́ nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì. Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, ẹ̀ṣẹ̀ ti di ọ̀rọ̀ àwàdà. Nígbà kan rí “ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n kà á sí” bí ọkùnrin àti obìnrin bá ń gbé pọ̀ láì fẹ́ ara wọn níṣulọ́kà, àmọ́ ní báyìí wọn ò kà á sí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Lójú wọn, yíyan àlè kì í ṣe “panṣágà,” wọ́n á ní “ó ń jayé orí ẹ̀ ni.” Wọ́n kì í pe àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin sùn ní “abẹ́yà kan náà lòpọ̀” mọ́, wọ́n ní wọ́n kàn yan “ìgbésí ayé kan tó yàtọ̀” ni.
Kò sí àní-àní pé ohun táwọn èèyàn gbà pé ó “dára” tàbí ohun tí wọ́n pè ní “ẹ̀ṣẹ̀” ti yí pa dà. Àmọ́ kí nìdí tí èrò àwọn èèyàn fi yí pa dà? Ṣé àwọn èèyàn kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí mọ́ ni? Ǹjẹ́ èrò tó o ní nípa ọ̀ràn náà tiẹ̀ ṣe pàtàkì?