Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Básámù Gílíádì Òróró Ìkunra Tó ń Woni Sàn

Básámù Gílíádì Òróró Ìkunra Tó ń Woni Sàn

Básámù Gílíádì Òróró Ìkunra Tó ń Woni Sàn

ÌTÀN inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì tó wà nínú Bíbélì sọ nípa bí àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ṣe tà á fún àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì tí wọ́n jẹ́ oníṣòwò tí wọ́n ń lọ sí Íjíbítì. Àwùjọ oníṣòwò náà wá láti Gílíádì àti pé àwọn ràkúnmí wọn ń gbé básámù àti àwọn ọjà míì lọ sí Íjíbítì. (Jẹ́nẹ́sísì 37:25) Ìtàn ráńpẹ́ yìí fi hàn pé básámù Gílíádì gbayì gan-an láyé àtijọ́ ní Àárín Ìlà Oòrùn ayé, ó sì ṣeyebíye nítorí èròjà àrà ọ̀tọ̀ tó ní láti woni sàn.

Àmọ́ ṣá o, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wòlíì Jeremáyà béèrè ìbéèrè kan nígbà tí inú rẹ̀ bà jẹ́, ó ní: “Ṣé básámù kò sí ní Gílíádì ni?” (Jeremáyà 8:22) Kí ló mú kí Jeremáyà béèrè ìbéèrè yìí? Kí ni básámù? Ṣé básámù tó ń woni sàn wà lónìí?

Básámù ní Àkókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì

Básámù jẹ́ orúkọ kan tí wọ́n ń lò láti fi ṣàpèjúwe oje tó ń wá látara onírúurú igi, ó rí bí òróró, ó sì ní òórùn dídùn. Òróró básámù tí wọ́n sábà máa ń fi ṣe tùràrí àti lọ́fíńdà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun afẹ́ olówó iyebíye táwọn èèyàn tó ń gbé Àárín Ìlà Oòrùn ayé máa ń lò láyé àtijọ́. Ó wà lára àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ṣe òróró àfiyanni mímọ́ àti tùràrí tí wọ́n ń lò ní àgọ́ ìjọsìn kété lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì. (Ẹ́kísódù 25:6; 35:8) Òróró básámù tún wà lára ẹ̀bùn olówó iyebíye tí ayaba Ṣébà mú wá fún Sólómọ́nì Ọba. (1 Àwọn Ọba 10:2, 10) Wọ́n ṣe Ẹ́sítérì lóge, wọ́n sì wọ́ ara fún un ní “oṣù mẹ́fà pẹ̀lú òróró básámù” kó tó wá síwájú Ahasuwérúsì Ọba.—Ẹ́sítérì 1:1; 2:12.

Òróró básámù wá láti onírúurú ilẹ̀ ní Àárín Ìlà Oòrùn ayé, àmọ́ básámù Gílíádì wá láti Ilẹ̀ Ìlérí, Gílíádì sì jẹ́ àgbègbè kan ní àríwá Odò Jọ́dánì. Jékọ́bù tó jẹ́ baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ka básámù sí ọ̀kan lára “àmújáde dídára jù lọ ilẹ̀” náà, ó sì wà lára ẹ̀bùn tó fi ránṣẹ́ sí Íjíbítì. (Jẹ́nẹ́sísì 43:11) Wòlíì Ìsíkíẹ́lì sọ pé básámù wà lára ọjà ti ilẹ̀ Júdà àti Ísírẹ́lì máa ń kó ránṣẹ́ sí ilẹ̀ Tírè. (Ìsíkíẹ́lì 27:17) Wọ́n mọ básámù káàkiri nítorí pé èròjà tó wà nínú rẹ̀ wúlò fún ìṣègùn. Àwọn ìwé àtijọ́ sábà máa ń mẹ́nu kan agbára tí básámù ní láti woni sàn, pàápàá tó bá di ọ̀ràn wíwo ọgbẹ́.

Básámù fún Orílẹ̀-Èdè Kan Tó Ń Ṣàìsàn

Kí wá nìdí tí Jeremáyà fi béèrè pé, “Ṣé básámù kò sí ní Gílíádì ni”? Ká bàa lè lóye ìdí náà, a ní láti ṣàgbéyẹ̀wò ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ṣáájú ìgbà tí Jeremáyà béèrè ìbéèrè yìí, wòlíì Aísáyà ṣàpèjúwe bí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run ti bà jẹ́ tó, ó ní: “Láti àtẹ́lẹsẹ̀ àní dé orí, kò sí ibì kankan nínú rẹ̀ tí ó dá ṣáṣá. Àwọn ọgbẹ́ àti ara bíbó àti ojú ibi tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ nà—a kò mọ́ wọn tàbí kí a dì wọ́n.” (Aísáyà 1:6) Kàkà kí orílẹ̀-èdè náà ronú lórí ipò ẹni téèyàn ń káàánú fún tí wọ́n wà, kí wọ́n sì wá ìwòsàn, ńṣe ni wọ́n ń bá ìwàkiwà nìṣó. Ní ìgbà Jeremáyà, ńṣe ló kédàárò pé: “Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ọgbọ́n wo sì ni wọ́n ní?” Ká ní wọ́n ti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà ni, ì bá ti wò wọ́n sàn. “Ṣé básámù kò sí ní Gílíádì ni?” Ìbéèrè yẹn mà ń múni ronú jinlẹ̀ gan-an o!—Jeremáyà 8:9.

Ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, aráyé lónìí ti ní “àwọn ọgbẹ́ àti ara bíbó àti ojú ibi tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ nà.” Ipò òṣì, àìsí ìdájọ́ òdodo, ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwà ìkà ń pọ́n aráyé lójú nítorí pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti ọmọnìkejì ẹni ti di tútù. (Mátíù 24:12; 2 Tímótì 3:1-5) Ọ̀pọ̀ èèyàn ti di ẹni àpatì nítorí ìran àti ibi tí wọ́n ti wá tàbí nítorí ọjọ́ orí wọn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìyàn, àìsàn, ogun àti ikú ti pa kún ìrora wọn. Bíi ti Jeremáyà, ọ̀pọ̀ olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ ń ṣe kàyéfì pé, “ṣé básámù kò sí ní Gílíádì ni,” èyí tí wọ́n lè fi wo ọgbẹ́ ọkàn àwọn tójú ń pọ́n, táá sì mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run dára sí i?

Ìhìn Rere Tó Ń Woni Sàn

Lákòókò Jésù, ìbéèrè kan náà ló wà lọ́kàn àwọn onírẹ̀lẹ̀ èèyàn. Ṣùgbọ́n wọ́n rí ìdáhùn gbà. Nínú sínágọ́gù ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 30 Sànmánì Kristẹni, Jésù ka àkájọ ìwé Aísáyà, ó ní: “Jèhófà ti fòróró yàn mí láti sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù. Ó ti rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn.” (Aísáyà 61:1) Lẹ́yìn náà, Jésù fi hàn pé òun gan-an lọ̀rọ̀ náà ń bá wí, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ni Mèsáyà tá a ti yàn láti sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn èèyàn.—Lúùkù 4:16-21.

Jálẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 4:17) Nínú Ìwàásù Lórí Òke, ó ṣèlérí fún àwọn tójú ń pọ́n pé, nǹkan máa yí pa dà fún wọn, ó ní: “Aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ń sunkún nísinsìnyí, nítorí pé ẹ óò rẹ́rìn-ín.” (Lúùkù 6:21) Jésù wo ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn sàn nípa kíkéde dídé Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ọ̀rọ̀ ìrètí tó sọ fún àwọn èèyàn.

Lọ́jọ́ tiwa yìí, “ìhìn rere ìjọba náà” ṣì ń tu àwọn èèyàn nínú bíi tìgbà yẹn. (Mátíù 6:10; 9:35) Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn Roger àti Liliane yẹ̀ wò. Ní January 1961 ni wọ́n kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ ìlérí Ọlọ́run nípa ìyè àìnípẹ̀kun, lára wọn, ó dà bíi básámù tí ń woni sàn. Liliane sọ pé, “Ńṣe ni mò ń jó nínú ilé ìdáná nígbà tí mò ń ronú nípa ohun tí mò ń kọ́. Inú mi dùn gan-an ni.” Roger, tí ẹ̀gbẹ́ kan ara rẹ̀ ti rọ fún ọdún mẹ́wàá, sọ pé, “Mo rí ayọ̀ ńlá, ayọ̀ pé mo wà láàyè, ọpẹ́lọpẹ́ ìrètí àgbàyanu náà, ìyẹn ìrètí àjíǹde àti pé gbogbo ìrora àti àìsàn máa dópin.”—Ìṣípayá 21:4.

Lọ́dún 1970 ọmọ wọn ọmọ ọdún mọ́kànlá kú, èyí bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ gan-an. Àmọ́, wọn kò jẹ́ kí ìbànújẹ́ dorí àwọn kodò. Àwọn fúnra wọn mọ̀ ọ́n lára pé Jèhófà “ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.” (Sáàmù 147:3) Ìrètí tí wọ́n ní tù wọ́n nínú. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọdún báyìí tí ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀ náà ti mú kí wọ́n ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn.

Ìwòsàn Kan Tó Ń Bọ̀ Lọ́nà

Ṣé “básámù kò sí ní Gílíádì” lónìí ni? Ó wà o, básámù tẹ̀mí ṣì wà. Ìtùnú àti ìrètí tí ìhìn rere ń mú wá ń wo ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn sàn? Ṣé wàá fẹ́ irú ìwòsàn bẹ́ẹ̀? Ohun tó o máa ṣe ni pé kó o ṣí ọkàn rẹ payá láti gba ìtùnú látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó o sì jẹ́ kó máa darí ìgbésí ayé rẹ. Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ti ṣe bẹ́ẹ̀.

Ìwòsàn tí básámù yìí ń fúnni jẹ́ àpẹẹrẹ ìtura ńlá tó ń bọ̀ lọ́nà. Àkókò náà ti sún mọ́lé gan-an tí Jèhófà Ọlọ́run máa mú kí “wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn” ṣẹlẹ̀ tí ìyè àìnípẹ̀kun á sì wà lọ́jọ́ iwájú. Ní àkókò yẹn, kò ní sí “olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” Ó dájú pé, ‘básámù ṣì wà ní Gílíádì’!—Ìṣípayá 22:2; Aísáyà 33:24.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Agbára tí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní láti woni sàn ń bá a nìṣó láti tu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn lára lónìí