Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Mú Kí Èrò Àwọn Èèyàn Nípa Ẹ̀ṣẹ̀ Yí Pa Dà?

Kí Ló Mú Kí Èrò Àwọn Èèyàn Nípa Ẹ̀ṣẹ̀ Yí Pa Dà?

Kí Ló Mú Kí Èrò Àwọn Èèyàn Nípa Ẹ̀ṣẹ̀ Yí Pa Dà?

“ÀWỌN èèyàn òde òní kì í fẹ́ gbọ́ pé àwọn ti jẹ̀bi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Wọn ò tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wà pàápàá. . . . Àwọn èèyàn bí Adolf Hitler àti ọ̀gbẹ́ni Josef Stalin lè ti dẹ́ṣẹ̀ ní tiwọn, àmọ́ àwa yòókù kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀.”—The Wall Street Journal.

Ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí jẹ́ ká rí i pé àríyànjiyàn ńlá ló wà lónìí nípa ọ̀ràn ẹ̀ṣẹ̀. Kí nìdí? Kí ló mú kí èrò àwọn èèyàn nípa ẹ̀ṣẹ̀ yí pa dà? Àti pé, kí ló dé táwọn èèyàn òde òní ò gbà pé ẹ̀ṣẹ̀ wà?

Apá méjì ni ọ̀ràn náà pín sí, apá àkọ́kọ́ ni ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá, apá kejì ni ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn fúnra rẹ̀ ń dá. Ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yẹ̀ wò.

Ṣé A Jogún Ẹ̀ṣẹ̀ Lóòótọ́?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo aráyé ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Nítorí náà, gbogbo wa ni a jẹ́ aláìpé látìgbà tí wọ́n ti bí wa. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo àìṣòdodo jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.”—1 Jòhánù 5:17.

Ó rú ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lójú, wọn kò sì gbà pé ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn kan ti dá láti ọjọ́ pípẹ́, táwọn kò sì lọ́wọ́ nínú rẹ̀ lè sọ gbogbo èèyàn di aláìpé. Ọ̀gbẹ́ni Edward Oakes, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìsìn sọ nípa ẹ̀kọ́ yìí pé, “ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ṣọ́ọ̀ṣì ń sọ pé káwọn èèyàn gbà pé ẹlẹ́ṣẹ̀ làwọn tàbí pé àwọn á gbìyànjú láti má ṣe dẹ́ṣẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lè fi ohun tí wọ́n sọ yẹn ṣèwà hù.”

Ẹ̀kọ́ tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń kọ́ni nípa ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó mú kó ṣòro fún àwọn èèyàn láti gbà pé àwọn ti jogún ẹ̀ṣẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní ibi àpérò tí àwọn olórí ìjọ Kátólíìkì ṣe (ọdún 1545 sí 1563), ṣọ́ọ̀ṣì sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé sísàmì fún àwọn ọmọ jòjòló láti mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò kò dára ti jẹ̀bi. Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn sọ pé, ọmọ jòjòló kan tí wọn kò sàmì fún láti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò kó tó kú kò ní lè dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní ọ̀run. Ọ̀gbẹ́ni Calvin ní tiẹ̀ kọ́ni pé àwọn ọmọ jòjòló ‘máa ń gbé ẹ̀ṣẹ̀ wá látinú ìyá wọn.’ Ẹ̀ṣẹ̀ wọn yìí burú débi pé ‘Ọlọ́run kà wọ́n sí ẹni ìkórìíra àti ẹlẹ́gbin.’

Èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé, àwọn ọmọ jòjòló kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan, torí náà kò ní bọ́gbọ́n mu pé irú àwọn ọmọ yìí á jìyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá. A lè wá rí i bí àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ṣe mú káwọn èèyàn má ṣe gbà pé ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá wà. Kódà, àwọn aṣáájú inú ṣọ́ọ̀ṣì kan kò lè fọwọ́ sọ̀yà pé inú iná ọ̀run àpáàdì làwọn ọmọ jòjòló tí wọn kò sàmì fún ń lọ. Nítorí náà, wọn ò mọ ohun tí wọ́n máa fi kọ́ni pé ó máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò di ara ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì, ó ti pẹ́ tí àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ti ń kọ́ni pé Limbo, ìyẹn ibi tí èèyàn kì í gbé ni àwọn ọmọ jòjòló tí wọn kò sàmì fún kí wọ́n tó kú ń lọ. a

Nǹkan míì tó mú káwọn èèyàn má gbà pé ẹ̀dá èèyàn ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ ni pé, àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún ń sọ pé kò sí ìdí láti gba àwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì gbọ́. Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, àròsọ ọ̀gbẹ́ni Darwin nípa ẹfolúṣọ̀n ti sọ ìtàn Ádámù àti Éfà di ìtàn àròsọ lásán. Àbájáde gbogbo èyí sì ni pé, ọ̀pọ̀ èèyàn ń ka Bíbélì sí èrò àti àṣà àwọn tó kọ ọ́, wọ́n ní kò wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Èrò wo wá ni ẹ̀kọ́ yìí ń gbé yọ nípa ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá? Kókó ibẹ̀ ni pé, tí wọ́n bá ń kọ́ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì pé Ádámù àti Éfà kò gbé ayé rí, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé kò sí ẹ̀ṣẹ̀ kankan tí èèyàn jogún láti ọ̀dọ̀ wọn. Lójú àwọn tó fẹ́ láti gbà pé òótọ́ ni ẹ̀dá èèyàn jẹ́ aláìpé, ńṣe ni ọ̀rọ̀ pé ẹ̀dá èèyàn jogún ẹ̀ṣẹ̀ dà bí ọ̀nà míì láti ṣàlàyé pé ẹ̀dá èèyàn jẹ́ aláìpé.

Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni èèyàn kò jogún ẹ̀ṣẹ̀, kí wá ni ti ẹ̀ṣẹ̀ tí èèyàn fúnra rẹ̀ ń dá tí wọ́n sọ pé ó máa ń bí Ọlọ́run nínú?

Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Lóòótọ́?

Tí wọ́n bá béèrè èrò àwọn èèyàn nípa ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn máa ń dá fúnra rẹ̀, ọ̀pọ̀ ló gbà pé rírú Òfin Mẹ́wàá ni, irú bí ìṣìkàpànìyàn, àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, olè jíjà àtàwọn nǹkan míì. Ohun tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni tipẹ́ ni pé, inú iná ọ̀run àpáàdì ni ẹnikẹ́ni tó bá kú láìronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí ń lọ, tá á sì máa jìyà títí láéláé. b

Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sọ pé tí ẹnì kan bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ irú ìjìyà yìí, ó gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún àlùfáà kan tí wọ́n sọ pé ó lágbára láti mú ẹ̀ṣẹ̀ náà kúrò. Àmọ́, lójú ọ̀pọ̀ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, ààtò ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ìdáríjini àti ìkẹ́dùn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti di ohun àtijọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí nípa àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tó wà ní Ítálì fi hàn pé, èèyàn mẹ́fà nínú mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni kì í lọ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

Kò sí àní-àní pé àlàyé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì nípa ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn ń dá fúnra rẹ̀ àti àbájáde rẹ̀ kò mú káwọn èèyàn jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ni kò ka ẹ̀ṣẹ̀ dídá sí nǹkan tó burú mọ́. Bí àpẹẹrẹ, èrò àwọn kan ni pé, tí àwọn méjì tó ti dàgbà bá gbà láti ní ìbálòpọ̀ tí ìyẹn ò sì ṣèpalára fún ẹlòmíì, kò sóhun tó burú níbẹ̀.

Àlàyé kan tá a lè ṣe nípa irú ìrònú yìí ni pé, ohun tí wọ́n fi kọ́ àwọn èèyàn tó ń lọ́wọ́ nínú nǹkan yìí kò yí èrò wọn pa dà pé ẹ̀ṣẹ̀ kò dáa. Ọ̀pọ̀ ni kò gbà gbọ́ pé Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ kan lè máa fìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀ títí láé nínú iná ọ̀run àpáàdì. Nítorí náà, iyè méjì táwọn èèyàn ní nípa ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ló jẹ́ ká mọ ara ìdí táwọn èèyàn ò fi ka ẹ̀ṣẹ̀ sí bàbàrà mọ́. Àmọ́ àwọn nǹkan míì tún wà tó mú káwọn èèyàn má ka ẹ̀ṣẹ̀ sí nǹkan kan mọ́.

Àwọn Èèyàn Ti Pa Ìwà Ọmọlúwàbí Tì

Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ láwọn ọgọ́rùn-ún ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ti mú àyípadà tó pọ̀ bá àwùjọ ẹ̀dá èèyàn àti ìrònú wọn. Ogun àgbáyé méjèèjì, àìlóǹkà ogun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ àti onírúurú ìpẹ̀yàrun tó ti wáyé ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ronú pé kò sídìí láti máa hùwà rere. Wọ́n máa ń béèrè pé: ‘Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu lákòókò ọ̀làjú yìí pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí wọ́n ti ṣe láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn tí kò bá ìgbésí ayé òde òní mu?’ Ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n orí àtàwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìlànà ìwà sọ pé kò bọ́gbọ́n mu. Èrò wọn ni pé, kéèyàn pa ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti ìgbésí ayé ojú dúdú tì, kí wọ́n sì gbájú mọ́ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó máa mú kéèyàn lè gbé àwọn nǹkan ńlá ṣe.

Ìrònú yìí ti jẹ́ káwọn èèyàn pa Ọlọ́run tì. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní ilẹ̀ Yúróòpù, àwọn èèyàn díẹ̀ ló ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Ńṣe ni iye àwọn èèyàn tí kò gba nǹkan kan gbọ́ ń pọ̀ sí i, inú sì ń bí ọ̀pọ̀ èèyàn sí ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n kà wọ́n sí ohun tí kò bọ́gbọ́n mu. Wọ́n máa ń sọ pé, tó bá jẹ́ pé, ńṣe lèèyàn ṣèèṣì wà, tí kò sì sí Ọlọ́run, kí la wá ń da ara wa láàmú sí pé a ti dẹ́ṣẹ̀?

Báwọn èèyàn ò ṣe ka ìwà ọmọlúwàbí sí nǹkan kan ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún ti yí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ takọtabo pa dà pátápátá. Ìwọ́de àwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbígbéjà ko àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti oògùn tí kì í jẹ́ kéèyàn lóyún ti kó ipa tó pọ̀ láti mú káwọn èèyàn jáwọ́ nínú ìwà ọmọlúwàbí. Kò sì pẹ́ táwọn èèyàn fi pa ìlànà Bíbélì tì. Ìran tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé wá gbé ìlànà ìwà tí wọ́n á máa tẹ̀ lé kalẹ̀ àti èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀. Òǹkọ̀wé kan sọ pé, látìgbà yẹn, “ìfẹ́ ìbálòpọ̀ làwọn èèyàn mọ̀,” ìyẹn sì mú kí ìbálòpọ̀ tí kò bójú mu gbalẹ̀ kan.

Ohun Táwọn Èèyàn Fẹ́ Ni Ìsìn Ń Kọ́ Wọn

Nígbà tí ìwé ìròyìn Newsweek ń sọ̀rọ̀ nípa ipò tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wà, ó sọ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n pé: “Ọ̀pọ̀ àlùfáà ló gbọ́dọ̀ máa sọ ohun táwọn èèyàn fẹ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn náà á gba ibòmíì lọ.” Ẹ̀rù ń ba àwọn àlùfáà pé tí àwọn bá lọ ń fòté lé e pé ìwà ọmọlúwàbí ló yẹ káwọn èèyàn máa hù, wọn ò ní wá sí ilé ìsìn àwọn mọ́. Àwọn èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ pé ó yẹ káwọn ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, káwọn fi ìwà tó dára àti ìwà funfun kọ́ra tàbí pé kí wọ́n fetí sí ẹ̀rí ọkàn wọn tó ń bá wọn wí àti pé kí wọ́n ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí ìdí èyí, ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ló ń wàásù ohun tí ìwé ìròyìn Chicago Sun-Times pè ní “ìwàásù tí wọ́n rò pé ó yẹ fáwọn Kristẹni bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ ìmọtara-ẹni ló ń kọ́ni, tí wọ́n sì pa ìhìn rere tì.”

Ohun tó jẹ́ àbájáde irú ìrònú yìí ni ìjọsìn tó ń sọ ohun tí Ọlọ́run ò jẹ́, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ti pa Ọlọ́run tì, tí kò sì ka àwọn ìlànà rẹ̀ sí, àmọ́ tó gbájú mọ́ bí iyì táwọn èèyàn ní a ṣe máa pọ̀ sí i. Ìfẹ́ ọkàn wọn ni pé káwọn ṣe ohun táwọn ọmọ ìjọ wọn fẹ́. Àbájáde rẹ̀ sì ni pé wọ́n ń jọ́sìn láìsí ìlànà ìsìn. Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal sọ pé: “Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sí ìwà rere tá a mọ̀ mọ àwọn Kristẹni? Ohun kan ṣoṣo tí híhùwà ọmọlúwàbí túmọ̀ sí ni pé kéèyàn ṣáà ti máa ṣe rere fún àwọn èèyàn.”

Ohun tí wọ́n sọ ni pé, ẹ̀sìn èyíkéyìí tó bá ti lè mára tuni ló dáa jù. Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal, sọ pé, “ẹnikẹ́ni tó bá nírú èrò yìí lè ṣe ẹ̀sìn èyíkéyìí tó bá wù ú, níwọ̀n ìgbà tí irú ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ kò bá ti fi dandan mú ẹnikẹ́ni láti ṣe ohun kan pàtó, àmọ́ tó jẹ́ pé ńṣe ló ń tuni lára tí kì í sì í dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́.” Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì sì ti múra tán láti gba àwọn èèyàn “bí wọ́n ṣe rí,” láì máa sọ pé kí wọ́n hùwà rere.

Àwọn ohun tá a ti ń sọ bọ̀ yìí máa rán ẹni tó ń ka Bíbélì létí àsọtẹ́lẹ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, pé: “Nítorí sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí; wọn yóò sì yí etí wọn kúrò nínú òtítọ́.”—2 Tímótì 4:3, 4.

Bí àwọn olórí ẹ̀sìn bá gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ dá, tí wọ́n sọ pé kò sí ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá, tí wọ́n sì ń ‘rin’ àwọn ọmọ ìjọ wọn létí nípa sísọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́ fún wọn dípò ohun tí Bíbélì sọ, wọn ò ṣe wọ́n lóore kankan. Irọ́ ni irú àwọn ìwàásù bẹ́ẹ̀, wọ́n sì léwu. Èyí ń fi ọ̀kan lára ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni hàn lọ́nà tí kò tọ́. Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ àti ìdáríjì gan-an nígbà tí wọ́n ń wàásù ìhìn rere. Láti mọ̀ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí, a rọ̀ ẹ́ pé kó o ka àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ẹ̀kọ́ Limbo tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu yìí ti kó ìdààmú ọkàn bá àwọn èèyàn, ó sì ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ ara ìdí tí wọ́n fi mú un kúrò nínú ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì ti ẹnu àìpẹ́ yìí. Wo àpótí náà “Àyípadà Bá Ẹ̀kọ́ Ìsìn Kan,” lójú ìwé 10.

b Kò sí ibì kankan nínú Bíbélì tó tì í lẹ́yìn pé àwọn èèyàn á máa jóná títí láé nínú iná. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, ka orí 6, tó sọ pé, “Ibo Làwọn Òkú Wà?,” nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

Èso búburú ni ìsìn kan ń so, tó bá jẹ́ pé nǹkan táwọn èèyàn ń fẹ́ ló ń kọ́ wọn kí ara lè tù wọ́n

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Èèyàn Kò Banú Jẹ́ Nítorí Ẹ̀ṣẹ̀ Mọ́

▪ “Nǹkan yìí gan-an ló jẹ́ ìṣòro tó le jù lọ tí ṣọ́ọ̀ṣì ní lónìí. A ò rí ara wa bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tó nílò ìdáríjì mọ́. Nígbà kan rí, inú wa máa ń bàjẹ́ tá a bá dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ ní báyìí kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́. Bí ṣọ́ọ̀ṣì tiẹ̀ ní ojútùú sí ìbànújẹ́ tóń báni téèyàn bá dẹ́ṣẹ̀, ọ̀ràn ẹ̀ṣẹ̀ dídá kì í ṣe ìṣòro lójú ọ̀pọ̀ ará Amẹ́ríkà mọ́, ó kéré tán, kì í ṣe ìṣòro tó le lójú ọ̀pọ̀ wọn.”—John A. Studebaker, Jr., òǹkọ̀wé nípa ẹ̀sìn.

▪ “Àwọn èèyàn máa ń sọ pé: ‘Mó fẹ́ máa hùwà rere, mó sì retí pé káwọn èèyàn máa ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, àmọ́ mo mọ̀ pé èèyàn ni gbogbo wa, torí náà, gbogbo ohun tí mo lè ṣe ni mò ń ṣe.’ Nǹkan tá a lè ṣe tá a máa fi tu ara wa nínú nìyẹn, bá a tiẹ̀ ń dẹ́sẹ̀. À ń tún àyíká ṣe. A kì í gbé mọ́tò wá sójú ọ̀nà. Àmọ́ a ti pa ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì tì, ìyẹn ẹ̀ṣẹ̀.”—Albert Mohler, ààrẹ Southern Baptist Theological Seminary.

▪ “Àwọn èèyàn ti wá ń fi ohun tí wọ́n kà sí ohun ìtìjú [ìyẹn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ló ń yọrí sí ikú] yangàn, àwọn òbí ń fún àwọn ọmọ wọn níṣìírí láti máa gbéra ga, wọ́n ní ó ṣe pàtàkì fún iyì ara ẹni. Àwùjọ alásè nílẹ̀ Faransé tí wọ́n ń wá iyì ara wọn ta ko ìgbìmọ̀ aláṣẹ Kátólíìkì pé àjẹkì kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀. Ìlara ló máa jẹ́ kéèyàn lókìkí. Àwọn tó ń polówó ọjà sọ pé táwọn bá jẹ́ káwọn èèyàn lójú kòkòrò làwọn fi máa ń rí ọjà àwọn tà. Àwọn èèyàn sì sọ pé ìbínú kò burú tí wọ́n bá múnú bíni. Ìgbà míì wà tó kàn máa ń wù mí láti ṣe ọ̀lẹ.”—Ọ̀gbẹ́ni Nancy Gibbs, nínú ìwé ìròyìn Time.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ń wo ìtàn Ádámù àti Éfà bí ìtàn àròsọ lásán