Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Kí Nìdí Téèyàn Fi Lè Dúró Sírú Ibí Yìí?”

“Kí Nìdí Téèyàn Fi Lè Dúró Sírú Ibí Yìí?”

Lẹ́tà Láti Orílẹ̀-èdè South Africa

“Kí Nìdí Téèyàn Fi Lè Dúró Sírú Ibí Yìí?”

“ÀGBÈGBÈ YÌÍ LÉWU GAN-AN NÍTORÍ ÀWỌN ADIGUNJALÈ ÀTÀWỌN AṢẸ́WÓ.” Èyí ni ìkìlọ̀ tó wà lára àkọlé kan lójú ọ̀nà ìgbèríko kan. A gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa yà sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà níbi eruku tí àwọn kan gbé ọkọ̀ wọn sí lábẹ́ àkọlé gàdàgbà tó ń tọ́ka sí ilé ìgbádùn àti ilé tẹ́tẹ́ tó wà nísàlẹ̀ ọ̀nà náà. Àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ olówó ńlá ń sáré kọjá, àwọn èèyàn tó wà nínú wọn sì ń yọjú wò wá, ìrísí ojú wọn ń fi hàn pé wọ́n ń ṣe kàyéfì pé: ‘Kí nìdí téèyàn fi lè dúró sírú ibí yìí?’

A paná ọkọ̀ wa, a jáde, á sì dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn tó múra dáadáa tí wọ́n dúró sábẹ́ òjìji àkọlé náà. Àwọn tó wá láti onírúurú ìran àti ẹ̀yà ló wà nínú àwùjọ yìí, èyí sì jẹ́ ohun tí kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè South Africa. A ti rìnrìn àjò nǹkan bí ọgọ́rùn-ún [100] kìlómítà láti àríwá ìlú Johannesburg wá sí ibí yìí láti wá sọ òtítọ́ Bíbélì fún àwọn tí ń gbé láwọn abúlé tó wà níbẹ̀.

A ṣe ìpàdé ráńpẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà láti jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́, a sì ṣètò bá a ṣe máa wàásù láti ilé dé ilé. A gbàdúrà, a sì pa dà sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa. Lódì kejì lọ́ọ̀ọ́kán, a rí àwọn ilé àti ahéré tí wọ́n kọ́ gátagàta. Àwọn ilé náà rí kóókòòkó lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn òkìtì gàgàrà tó wà ní ibi ìwakùsà àlùmọ́ọ́nì tó fàwọ̀ jọ fàdákà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀ pọ̀ lọ jàra níbí yìí, ó yani lẹ́nu pé àwọn èèyàn tòṣì gan-an.

Èmi, ìyàwó mi àtàwọn àlejò méjì láti orílẹ̀-èdè Jámánì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé láàárọ̀ ọjọ́ yẹn. Nǹkan bí ìdá mẹ́ta lára àwọn tó ń gbé ibẹ̀ ni kò níṣẹ́, torí náà ilé wọn kì í ṣe ti olówó gọbọi. Àwọn igi tí kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára ni wọ́n fi kọ́ àwọn ahéré náà, tí wọ́n sì fi páànù bò wọ́n lórí. Ìṣó ńlá tí wọ́n kì sínú ìdérí ọtí bíà tí wọ́n lù pẹlẹbẹ ni wọ́n fi kan páànù náà, kí omi má bàa gba ìdí ìṣó wọlé.

Bí a ṣe ń dé ilé kọ̀ọ̀kan, à ń kí wọn láti ẹnu géètì, obìnrin ló sábà máa ń jáde wá bá wa. Àwọn tá a bá sọ̀rọ̀ fẹ́ láti gbọ́ ohun tá a mú wá, wọ́n sì gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Oòrùn tó ń ràn sí páànù òrùlé ilé náà máa ń mú ki ilé gbóná gan-an lọ́sàn-án. Nítorí náà, wọ́n á ní káwọn ọmọ lọ gbé àga wá fún wa sábẹ́ igi. Wọ́n á sì ní ká jókòó sábẹ́ ibòji.

Àwọn ìdílé máa ń jókòó sórí ìjókòó tí orí rẹ̀ kò dán tàbí sórí ike tí wọ́n máa ń kó ọtí sí. Kódà, wọ́n máa ń pe àwọn ọmọ níbi tí wọ́n ti ń fi àwọn ohun ìṣeré wọn ṣeré pé kí wọ́n wá gbọ́ ìwàásù. A ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún wọn, a sì ní kí àwọn ọmọ tó ti ń lọ sílé ìwé bá wa ka àwọn ìwé wa tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tá a bá pàdé ló láyọ̀ láti gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, ọ̀pọ̀ sì sọ pé ká pa dà wá.

Lọ́sàn-án, a sinmi díẹ̀ láti fi nǹkan panu àti láti fi nǹkan tútù pòùngbẹ ká tó pa dà lọ bá àwọn tá a ti rí tẹ́lẹ̀. Ibi àkọ́kọ́ tá a dé ni ọ̀dọ̀ Jimmy, orílẹ̀-èdè Màláwì ló ti wá, ó sì ń ṣiṣẹ́ ní ọ̀kan lára àwọn ibi ìwakùsà tó wà ládùúgbò náà. A ti máa ń lọ sọ́dọ̀ Jimmy fún nǹkan bí oṣù mélòó kan. Inú rẹ̀ máa ń dùn láti rí wa, a sì ti lo àkókò díẹ̀ láti jíròrò Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀. Jimmy fẹ́ obìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Setswana, ó sì ti bí ọmọ méjì tó jẹ́ àrídunnú fún un. A kò rí i nílé nígbà tá a wá kẹ́yìn, nítorí náà, a fẹ́ mọ bó ṣe ń ṣe sí nísinsìnyí.

Bá a ṣe wakọ̀ dé ilé Jimmy, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la mọ̀ pé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀. Ọgbà rẹ̀ tó máa ń rí tónítóní ti wá rí jákujàku, àwọn àgbàdo rẹ̀ ti gbẹ, kò sì sí àwọn adìyẹ tó máa ń fẹsẹ̀ tan ilẹ̀ níbẹ̀ mọ́. Wọ́n fi ẹ̀wọ̀n gbàǹgbà ti ilẹ̀kùn ní ìta. Ni obìnrin kan tí wọ́n jọ wà ládùúgbò bá wá sọ́dọ̀ wa. A béèrè ibi tí Jimmy wà. Obìnrin náà sọ fún wa pé Jimmy ti kú àti pé ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ ti kó lọ bá ìdílé ìyàwó rẹ̀, ìyẹn sì dùn wá gan-an ni.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìlú yìí kò bójú mu láti máa béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀, àmọ́, a ní kó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà fún wa. Ó sọ fún wa pé, “Ó ṣàìsàn, ó sì kú. Ọ̀pọ̀ àìsàn ló wà lóde báyìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ń kú.” Kò sọ orúkọ àìsàn náà ní pàtó, nítorí pé wọ́n kì í sábà sọ̀rọ̀ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀, àmọ́ sàréè tó ń pọ̀ sí i ní itẹ́ òkú tó wà ládùúgbò yẹn jẹ́ ẹ̀rí tó ń bani nínú jẹ́ pé òótọ́ ni obìnrin yẹn sọ. A jíròrò ìrètí àjíǹde pẹ̀lú obìnrin náà fún àkókò díẹ̀, lẹ́yìn náà, a fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ibi tó kàn, àmọ́ inú wa bà jẹ́.

A wọ inú abúlé tó kàn, a sì wakọ̀ lọ sí ibi tí ọ̀wọ́ àwọn ilé tó kángun sí òkìtì ìwakùsà tó ga gègèrè wà. A sì wọnú ọ̀nà kékeré kan tó wà ní òpin òpópónà náà. Wọ́n fi ọ̀dà tó ń tàn yanran kọ àwọn ọ̀rọ̀ sára òkúta inú ọgbà tó wà níbẹ̀, gbólóhùn náà kà pé: “Ẹni tí kò bá lè ṣèpinnu lásìkò, nǹkan rẹ̀ á bà jẹ́.” David, a tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà rọra gbé orí rẹ̀ sókè lẹ́yìn ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ ìjàpá rẹ̀ tó jẹ́ ọkọ̀ àtijọ́. Ọkùnrin náà wo oòrùn tó ń wọ̀, ó sì rẹ́rìn-ín bó ṣe rí i pé àwa ni, oòrùn sì tàn sí góòlù tó fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí eyín rẹ̀ iwájú. Ó nu ọwọ́ rẹ̀, ó sì wá kí wa.

Ó kí wa pé, “Ẹ ǹlẹ́ o, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi! Ibo lẹ ti wà látọjọ́ yìí?” Inú wa dùn láti rí David lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó bẹ̀ wá pé òun kò ní lè lo àkókò púpọ̀ pẹ̀lú wa lọ́jọ́ náà nítorí òun ti rí iṣẹ́ nígbà tá a wá kẹ́yìn, òun kò sì ní pẹ́ lọ sí ibi ìwakùsà. Ní gbogbo ìgbà tá à ń sọ̀rọ̀ yẹn, David kò yé rẹ́rìn-ín. Ó fi ìdùnnú sọ pé: “Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tá a ti pàdé ni ìgbésí ayé mi ti yí pa dà! Kí n sòótọ́, mi ò mọ ibi tí mi ò bá wà lónìí ká ní o kò wá bá mi.”

Inú wa dùn, a sì fi David sílẹ̀. Bí oòrùn ṣe ń wọ̀ lọ, a gbé ọkọ wa, a dorí kọ ọ̀nà ilé. A wo pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà lẹ́ẹ̀kan sí i, a kò rí ọ̀ọ́kán dáadáa nítorí oòrùn tó ń ràn tí kùrukùru sì wà káàkiri, à ń ṣe kàyéfì bí ìhìn rere ṣe máa dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn èèyàn yìí. Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Jésù wá yé wa gan-an pé: “Ìkórè pọ̀, ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ kéré níye.”—Lúùkù 10:2.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ náà pa dà.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 17]

Ìyọ̀ǹda látọ̀dọ̀ Ilé Iṣẹ́ Ìfìwéránṣẹ́ orílẹ̀-èdè South Africa