Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí ni ẹnubodè ìlú tí wọ́n sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì?

Ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀pọ̀ jù lọ ìlú ńlá ni wọ́n máa ń fi odi yí ká. Àyè gbalasa máa ń wà nínú ọ̀pọ̀ ẹnubodè, ibẹ̀ làwọn èèyàn ti máa ń pàdé ara wọn, wọ́n máa ń ṣòwò níbẹ̀, wọ́n sì máa ń sọ nǹkan tuntun fún àwọn èèyàn. Ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń ṣe ìkéde fáwọn èèyàn, ibẹ̀ sì làwọn wòlíì ti máa ń kéde iṣẹ́ tí wọ́n ń jẹ́. (Jeremáyà 17:19, 20) Ìwé náà The Land and the Book sọ pé “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo káràkátà ló máa ń wáyé ní ẹnubodè tàbí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè ìlú.” Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn ẹnubodè ìlú dà bí gbọ̀ngàn ìlú láyé òde òní.

Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù ra ilẹ̀ ìsìnkú fún ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ Éfúrónì “lójú àwọn ọmọ Hétì láàárín gbogbo àwọn tí ń wọ ẹnubodè ìlú ńlá rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 23:7-18) Bóásì sọ fún àgbààgbà mẹ́wàá Bẹ́tílẹ́hẹ́mù kí wọ́n jókòó ní ẹnubodè ìlú, kó lè ṣe ètò níṣojú wọ́n bí ẹnì kan a ṣe ṣú Rúùtù lópó, táwọn ogún ọkọ rẹ̀ olóògbé á sì bọ́ sọ́wọ́ ẹni náà. (Rúùtù 4:1, 2) Nígbà táwọn àgbààgbà ìlú kan bá fẹ́ ṣe onídàájọ́, wọ́n máa ń jókòó ní ẹnubodè láti gbọ́ àwọn ẹjọ́, ṣe àwọn ìpinnu, àti láti ṣe ìdájọ́.—Diutarónómì 21:19.

Ibo ni Ófírì tí Bíbélì sọ pé wọ́n ti ń rí ojúlówó wúrà wà?

Ìwé Jóòbù ló kọ́kọ́ mẹ́nu kan “wúrà Ófírì,” ó sì fi wé “ògidì wúrà.” (Jóòbù 28:15, 16) Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé Jóòbù, Dáfídì Ọba kó “wúrà Ófírì” jọ láti fi kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù. Bákan náà, ọmọ rẹ̀, Sólómọ́nì kó wúrà wọ̀lú láti Ófírì.—1 Kíróníkà 29:3, 4; 1 Àwọn Ọba 9:28.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé Mímọ́ ti wí, Sólómọ́nì ní ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun tó ṣe ní Esioni-gébérì, tí wọ́n ń rìn lórí Òkun Pupa, tí wọ́n sì ń kó wúrà wá láti Ófírì. (1 Àwọn Ọba 9:26) Àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé Esioni-gébérì wà ní ibi tí omi ti ya wọ ilẹ̀ ní Aqaba, èyí tó wà ní àgbègbè Élátì àti Aqaba òde òní. Láti ibẹ̀, àwọn ọkọ̀ òkun lè dé apá èyíkéyìí lára Òkun Pupa, tàbí àwọn ibi ìṣòwò tó jìnnà réré ní etíkun ilẹ̀ Áfíríkà tàbí ilẹ̀ Íńdíà, ìyẹn àwọn ibi tó ṣeé ṣe kí Ófírì wà. Àwọn míì gbà pé Ófírì wà ní Arébíà, níbi tí wọ́n ti rí àwọn ibi tí wọ́n ti ń wa wúrà nígbà àtijọ́, wọ́n sì ti rí wúrà kó níbẹ̀ ní àkókò tiwa yìí.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti sọ, ǹjẹ́ àròsọ ni ibi tí Sólómọ́nì ti wa wúrà? Kenneth A. Kitchen tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun ìṣẹ̀ǹbáyé Íjíbítì sọ nípa èyí pé: “Orúkọ náà Ófírì kì í ṣe àròsọ. Àfọ́kù ìkòkò àwọn Hébérù tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ àkọlé kékeré kan sí lára pé: ‘Wúrà Ófírì fún Beti-Hórónì—ọgbọ̀n [30] ṣékélì.’ Ófírì gan-gan ni wọ́n sọ pé wúrà náà ti wá, gẹ́gẹ́ bíi ti ‘Wúrà ‛Amau,’ tàbí ‘Wúrà Punt’ tàbí ‘Wúrà Kush’ tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ èdè Íjíbítì kọ. Orúkọ wúrà kọ̀ọ̀kàn wá láti ilẹ̀ ibi tí wọ́n ti rí i tàbí kó jẹ́ látinú bí wúrà ilẹ̀ náà ti jẹ́ ojúlówó tó.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ábúráhamù rèé ní ẹnubodè ìlú, ó fẹ́ ra ilẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àfọ́kù ìkòkò àwọn Hébérù tí wọ́n kọ Ofírì sí lára

[Credit Line]

Fọ́tò yìí wá látọwọ́ Israel Antiquities Authority © Ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ti Ísírẹ́lì nílùú Jerúsálẹ́mù