Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Ẹ̀ṣẹ̀

Ohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Ẹ̀ṣẹ̀

Ohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Ẹ̀ṣẹ̀

ǸJẸ́ ẹni tí àìsàn ibà ń ṣe lè sọ pé ibà kò ṣe òun tó bá ṣáà ti lè ba ẹ̀rọ tí wọ́n fi ṣàyẹ̀wò àìsàn náà jẹ́? Rárá o! Bákan náà, pé ọ̀pọ̀ èèyàn kò fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀ṣẹ̀ wò ó kò túmọ̀ sí pé ẹ̀ṣẹ̀ kò sí. Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó pọ̀ fún wa nípa ẹ̀ṣẹ̀. Kí ló sọ?

Gbogbo Wa Kò Kúnjú Ìwọ̀n

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ bí inú òun ti bà jẹ́ tó nígbà tó sọ pé, ‘rere tí òun fẹ́ ni òun kò ṣe, ṣùgbọ́n búburú tí òun kò fẹ́ ni òun fi ń ṣe ìwà hù.’ (Róòmù 7:19) Ká sòótọ́, bí ọ̀ràn tiwa náà ṣe rí nìyẹn. Bóyá a fẹ́ láti máa tẹ̀ lé Òfin Mẹ́wàá tàbí àwọn ìlànà míì nínú ìgbésí ayé wa, bó ti wù ká sapá tó, a kò lè kúnjú ìwọ̀n. Kì í ṣe pé a kàn mọ̀ọ́mọ̀ tẹ ìlànà lójú, àmọ́ agbára wa kò gbé e ni. Kí ló fà á? Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ fún wa ní ìdáhùn, ó ní: “Bí ó bá jẹ́ pé ohun tí èmi kò fẹ́ ni èmi ń ṣe, ẹni tí ń ṣe é kì í ṣe èmi mọ́, bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi.”—Róòmù 7:20.

Bíi ti Pọ́ọ̀lù, gbogbo èèyàn ni àìpé tá a bí mọ́ wa ti ṣàkóbá fún, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé. Àpọ́sítélì náà sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” Kí ló fà á? Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 3:23; 5:12.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn kò gbà pé ẹ̀ṣẹ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ló sọ wá di àjèjì sí Ọlọ́run, tó sì mú ká pàdánù ìjẹ́pípé, àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ pé ó fà á gan-an nìyẹn. Jésù fi hàn pé òun gbà pé ìtàn Ádámù àti Éfà jóòótọ́ nítorí ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn orí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì láti fi ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27; 2:24; 5:2; Mátíù 19:1-5.

Ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Bíbélì kọ́ni ni pé, Jésù wá sáyé láti ra àwọn tó lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. (Jòhánù 3:16) Ohun tó máa pinnu ìwàláàyè wa lọ́jọ́ iwájú ni pé ká tẹ́wọ́ gba ọ̀nà tí Jèhófà lò láti fi gba aráyé tó mọrírì lọ́wọ́ ipò tí wọ́n bá ara wọn. Àmọ́ tí a kò bá mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀ṣẹ̀, a kò lè mọrírì ọ̀nà tí Ọlọ́run lò láti fi gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.

Ẹbọ Jésù àti Ìdí Tá A Fi Nílò Rẹ̀

Jèhófà fún Ádámù ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé. Kìkì tó bá ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ló máa pàdánù àǹfààní àgbàyanu yẹn. Ádámù ṣọ̀tẹ̀, nígbà tó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó di ẹlẹ́ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17; 3:6) Ádámù hùwà lọ́nà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, nítorí náà, kì í ṣe ẹni pípé mọ́, ó sì ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Nígbà tó rú òfin Ọlọ́run, ó dẹ́ṣẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kú. Ó bani nínú jẹ́ pé gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù títí kan àwa náà ni wọ́n bí sínú ẹ̀ṣẹ̀, tó sì jẹ́ pé ikú ló máa gbẹ̀yìn wa nítorí ẹ̀ṣẹ̀ náà. Kí nìdí?

Ohun tó fà á kò mù rárá. Àwọn òbí aláìpé kò lè bí ọmọ pípé. Ádámù bí gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ní aláìpé, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì sọ pé, “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Àmọ́ ṣá o, apá kejì ẹsẹ yẹn fún wa nírètí kan, ó ní: “Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” Ìyẹn ni pé nípasẹ̀ ikú ìrúbọ tí Jésù kú, á ṣeé ṣe láti wẹ aráyé tó jẹ́ onígbọràn mọ́ kúrò nínú àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù dá. a (Mátíù 20:28; 1 Pétérù 1:18, 19) Ipa wo nìyẹn lè ní lórí rẹ?

Ìfẹ́ Kristi “Sọ Ọ́ Di Ọ̀ranyàn fún Wa”

Nípasẹ̀ ìmísí Ọlọ́run, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ ìdáhùn tí Ọlọ́run fún wa. Ó sọ pé: “Nítorí ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa, nítorí èyí ni ohun tí àwa ti ṣèdájọ́, pé ọkùnrin kan kú fún gbogbo ènìyàn; . . . ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.” (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Bí ẹnì kan bá mọ̀ pé ẹbọ Jésù lè gbani lọ́wọ́ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ fà, tí onítọ̀hún sì fẹ́ fi ìmoore hàn fún ìpèsè yẹn, ó ní láti máa sapá láti máa gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Èyí kan pé kó máa kẹ́kọ̀ọ́ láti lóye ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó máa ṣe, kó máa fi ìlànà Bíbélì kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, kó sì máa gbé ìgbé ayé tó bá ìlànà Bíbélì mu.—Jòhánù 17:3, 17.

Ìwà àìtọ́ máa ń ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. Nígbà tí Ọba Dáfídì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tí òun àti Bátí-ṣébà dá àti bí ó ṣe pa ọkọ rẹ̀ ṣe wúwo tó, ó dájú pé ìtìjú ńlá bá a. Ṣùgbọ́n ohun tó jẹ ẹ́ lógún jù lọ, tó sì yẹ bẹ́ẹ̀ ni pé, ẹ̀ṣẹ̀ tó dá náà bí Ọlọ́run nínú. Ó fi ẹ̀mí ìrònúpìwàdà hàn sí Jèhófà, ó ní: “Ìwọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí, mo sì ti ṣe ohun tí ó burú ní ojú rẹ.” (Sáàmù 51:4) Bákan náà, nígbà tí ìdẹwò dojú kọ Jósẹ́fù láti ṣe panṣágà, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mú kó béèrè pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?”—Jẹ́nẹ́sísì 39:9.

Dájúdájú ẹ̀ṣẹ̀ lè mú ìbànújẹ́ báni, ó sì lè mú kéèyàn jẹ́jọ́ níwájú ará ìlú nítorí ohun tó kù díẹ̀ káàtó téèyàn lè ti ṣe. Àmọ́ ju gbogbo rẹ̀ lọ, rírú òfin Ọlọ́run lórí ìbálòpọ̀, ìṣòtítọ́, ọ̀wọ̀, ìjọsìn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ máa ń ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Tá a bá mọ̀ọ́mọ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀, ńṣe là ń sọ ara wa di ọ̀tá Ọlọ́run. Òtítọ́ tó yẹ kéèyàn ronú jinlẹ̀ lé lórí lèyí jẹ́.—1 Jòhánù 3:4, 8.

Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ti yí pa dà ni? Rárá o. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ ń jẹ́. Àwọn èèyàn kàn ń pè é ní orúkọ míì kó bàa dà bíi pé kò fi bẹ́ẹ̀ burú. Ńṣe lọ̀pọ̀ èèyàn pa ẹ̀rí ọkàn wọn kú tàbí kí wọ́n má fiyè sí i mọ́. Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run gbọ́dọ̀ yàgò fún irú ìwà bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀, kì í wulẹ̀ ṣe pé ẹ̀ṣẹ̀ máa ń ba ògo téèyàn ní jẹ́ tàbí kí ó kó ìtìjú báni, àmọ́ ó máa ń ṣekú pani. Ọ̀ràn ìyè àti ikú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́.

Ó dùn mọ́ wa nínú pé ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ṣeé ṣe nípasẹ̀ ìtóye ẹbọ Jésù tó ń rani pa dà, ìyẹn tá a bá ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a sì jáwọ́ nínú wọn. Pọ́ọ̀lù sọ pé, “Aláyọ̀ ni àwọn tí a ti dárí àwọn ìṣe àìlófin wọn jì, tí a sì ti bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀; aláyọ̀ ni ènìyàn tí Jèhófà kì yóò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí lọ́rùn lọ́nàkọnà.”—Róòmù 4:7, 8.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí bí ikú ìrúbọ tí Jésù kú ṣe ní agbára láti gba aráyé onígbọràn là, ka ojú ìwé 47 sí 54 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àyípadà Bá Ẹ̀kọ́ Ìsìn Kan

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ni ẹ̀kọ́ Limbo kò yé. Ní ohun tó lé ní ogún ọdún sẹ́yìn, ẹ̀kọ́ yìí ti ń pa rẹ́ lọ́ débi pé kò fara hàn nínú ìwé katikísìmù mọ́. Lọ́dún 2007, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fòpin sí ẹ̀kọ́ Limbo nínú ìwé kan tó ṣàlàyé “àwọn ìdí tí ẹ̀kọ́ ìsìn àti ti ìgbàgbọ́ fi mú ká nírètí pé àwọn ọmọ jòjòló tí wọ́n kò sàmì fún kí wọ́n tó kú lè rí ìgbàlà kí wọ́n sì wọnú ayọ̀ ayérayé.”—International Theological Commission.

Kí nìdí tí àyípadà fi dé bá ẹ̀kọ́ ìsìn yìí? Ó jẹ́ nítorí kí ṣọ́ọ̀ṣì bàa lè bọ́ lọ́wọ́ ohun tí Henri Tincq òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Faransé pè ní “ẹ̀kọ́ tó ti wà tipẹ́ tó ń nini lára, tí wọ́n ti ń dáàbò bo láti Àárín Ìgbà Ọ̀làjú títí di ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún, tí Ṣọ́ọ̀ṣì ń lò láti fi dẹ́rù ba àwọn òbí kí wọ́n lè sàmì fún àwọn ọmọ wọn ní kíákíá.” Àmọ́, òpin tó dé bá ẹ̀kọ́ Limbo tún gbé àwọn àríyànjiyàn kan dìde.

Ṣé Ẹ̀kọ́ Àtọwọ́dọ́wọ́ Ni àbí Ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́? Ìtàn sọ pé ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ Limbo wá látinú ìjiyàn kan tó jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ pọ́gátórì tó wáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejìlá. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kọ́ni pé ọkàn máa ń kúrò nínú ara lẹ́yìn téèyàn bá kú, nítorí náà, ó ṣòro fún wọn láti ṣàlàyé ibi tí ọkàn àwọn ọmọ jòjòló máa lọ torí wọ́n kò lọ sí ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò yẹ fún ọ̀run àpáàdì nítorí pé wọn kò sàmì fún wọn. Èyí ló mú kí ẹ̀kọ́ Limbo wáyé.

Àmọ́ ṣá o, Bíbélì kò kọ́ni pé ọkàn èèyàn máa ń wàláàyè lẹ́yìn tí ara bá ti kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ kedere pé ọkàn tó bá ṣẹ̀ yóò “pa run” tàbí “yóò kú.” (Ìṣe 3:23; Ìsíkíẹ́lì 18:4) Nígbà tó jẹ́ pé ọkàn lè kú, kò sí ibì kan tó ń jẹ́ Limbo nìyẹn. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì sọ nípa ikú pé ó jẹ́ ipò téèyàn kò ti mọ nǹkan kan, tó dà bí oorun.—Oníwàásù 9:5, 10; Jòhánù 11:11-14.

Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run ka àwọn ọmọ tí òbí kan tó jẹ́ Kristẹni bí sí mímọ́. (1 Kọ́ríńtì 7:14) Irú gbólóhùn yẹn kò wúlò tó bá jẹ́ pé ìsàmì ọmọ jòjòló pọn dandan kí wọ́n tó lè rí ìgbàlà.

Ẹ̀kọ́ Limbo ń tàbùkù sí Ọlọ́run gan-an, ó ń fi í hàn pé òǹrorò tó ń fìyà jẹ àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ni, dípò Bàbá onífẹ̀ẹ́ tó jẹ́, tó ń ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu. (Diutarónómì 32:4; Mátíù 5:45; 1 Jòhánù 4:8) Abájọ tí ẹ̀kọ́ ti kò bá Ìwé Mímọ́ mu yìí kò fi bọ́gbọ́n mu lójú àwọn Kristẹni tòótọ́.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Gbígbé ìgbé ayé tó bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu ń jẹ́ kéèyàn ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run àti èèyàn