Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Òǹtẹ̀wé Ìjímìjí Kan Gbé Bíbélì Lárugẹ

Òǹtẹ̀wé Ìjímìjí Kan Gbé Bíbélì Lárugẹ

Òǹtẹ̀wé Ìjímìjí Kan Gbé Bíbélì Lárugẹ

Ó TI tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn táwọn èèyàn ti ń fọwọ́ kọ àwọn ìwé àtàwọn àkájọ ìwé. Àmọ́, àwọn ìwé tí wọ́n fi ohun ìtẹ̀wé tẹ̀ kò tíì pẹ́ tó ìyẹn. Orílẹ̀-èdè Ṣáínà ni wọ́n ti kọ́kọ́ tẹ àwọn ìwé jáde lọ́dún 868 Sànmánì Kristẹni, igi tí wọ́n gbẹ́ ni wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n fi tẹ̀ ẹ́. Lórílẹ̀-èdè Jámánì ní nǹkan bí ọdún 1455, ọ̀gbẹ́ni Johannes Gutenberg ṣe irin to ṣeé yí láti fi tẹ Bíbélì èdè Látìn àkọ́kọ́ jáde.

Àmọ́ lẹ́yìn àwọn ọdún mélòó kan tí iṣẹ́ ìwé títẹ̀ ti fìdí múlẹ̀, ni àwọn èèyàn wá bẹ̀rẹ̀ sí í pín Bíbélì àtàwọn ìwé míì káàkiri. Ìlú Nuremberg wá di ibi pàtàkì fún àwọn ilé iṣẹ́ tó ń tẹ̀wé jáde nílẹ̀ Jámánì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀gbẹ́ni Anton Koberger tó jẹ́ ọmọ ìlú yẹn ni òǹṣèwé, tó tún jẹ́ òǹtẹ̀wé àkọ́kọ́ tó tẹ Bíbélì lọ́pọ̀ yanturu fún ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.

Àwọn èèyàn tó wá láti onírúurú orílẹ̀-èdè mọyì iṣẹ́ àwọn tó kọ́kọ́ tẹ Bíbélì jáde, títí kan iṣẹ́ ọ̀gbẹ́ni Anton Koberger. Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn Koberger àti iṣẹ́ rẹ̀ yẹ̀ wò.

“Àbójútó Ìwé Kan Ṣoṣo, Ìyẹn Bíbélì”

Ọdún 1470 ni ọ̀gbẹ́ni Koberger ṣí ilé ìtẹ̀wé àkọ́kọ́ ti ìlú Nuremberg. Iye ẹ̀rọ tí ilé iṣẹ́ rẹ̀ fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan náà jẹ́ mẹ́rìnlélógún, ó sì gba àwọn atẹ̀wé, akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àtàwọn òṣìṣẹ́ míì tí iye wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún láti ìlú Basel, Strasbourg, Lyon àtàwọn ìlú Yúróòpù míì. Koberger tẹ àwọn ìwé lédè Látìn tí wọ́n ń sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ọ̀làjú àti ọ̀pọ̀ àwọn ìwé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ìgbà yẹn. Láàárín ìgbà tó fi ṣiṣẹ́ ìwé títẹ̀, ó tẹ igba ó lé mẹ́rìndínlógójì [236] oríṣiríṣi ìwé. Àwọn kan lára àwọn ìwé náà ní ojú ìwé tó tó ọgọ́rùn-ún mélòó kan, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé aláfọwọ́yí ló sì fi tẹ gbogbo wọn lọ́kọ̀ọ̀kan.

Nítorí pé ìrísí àwọn lẹ́tà ọ̀rọ̀ tí Koberger lò dára gan-an, èyí mú kí àwọn ìwé tó tẹ̀ gbajúmọ̀ nítorí wọ́n lẹ́wà wọ́n sì dùn-ún kà. Òpìtàn tó ń jẹ́ Alfred Börckel sọ pé, “Ìgbà gbogbo ni Koberger máa ń fẹ́ lo àwọn lẹ́tà ọ̀rọ̀ tó ṣe, tó sì gbẹ́ wọ́n ní ìrísí tó dára. Kì í lo àwọn lẹ́tà ọ̀rọ̀ tó ti bà jẹ́.” Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìwé àti Bíbélì tí Koberger tẹ̀ ló ní àwọn àwòrán tí wọ́n gbẹ́ sára igi, tí wọ́n wá tẹ̀ sórí ìwé.

Ọ̀gbẹ́ni Oscar Hase tó kọ ìtàn ìgbésí ayé Koberger sọ pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwé títẹ̀ rẹ̀ títí dé òpin “àbójútó ìwé kan ṣoṣo, ìyẹn Bíbélì, ló gbájú mọ́.” Koberger àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sapá gan-an láti rí i pé ọ̀rọ̀ tó péye ni wọ́n lò nígbà tí wọ́n ń tẹ Bíbélì. Iṣẹ́ yìí kò rọrùn rárá nítorí ọ̀pọ̀ ìwé awọ aláfọwọ́kọ jẹ́ ohun iyebíye tí wọ́n ń fi pa mọ́ sí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kan, wọn kì í fẹ́ kó pẹ́ lọ́wọ́ ẹni tí wọ́n bá yá pé kó ṣàdàkọ wọn, ìyẹn tí wọ́n bá tiẹ̀ fẹ́ yá ẹnì kan pàápàá.

Àwọn Bíbélì Èdè Látìn àti Ti Jámánì

Koberger tẹ oríṣi Biblia Latina (Bíbélì lédè Látìn) mẹ́ẹ̀ẹ́dógún jáde, ọdún 1475 ni ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ jáde. Àwọn ìtẹ̀jáde kan ní àwòrán ọkọ̀ Nóà, Òfin Mẹ́wàá àti tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì. Lọ́dún 1483, Koberger tẹ Biblia Germanica (Bíbélì lédè Jámánì), ó tẹ ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500], ìyẹn jẹ́ iye tó pọ̀ nígbà yẹn. Bíbélì náà ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún àwòrán tí wọ́n gbẹ́ sára igi, tí wọ́n wá tẹ̀ sórí ìwé nínú, èyí ń mú kí àwọn òǹkàwé fẹ́ láti kàwé, ó ń mú kí ọ̀rọ̀ ibẹ̀ túbọ̀ yéni, ó sì ń jẹ́ kí àwọn tí kò lè kàwé rántí àwọn ìtàn Bíbélì tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn àwòrán inú Bíbélì yìí ní ipa pàtàkì lórí àwọn tó ń yàwòrán sínú Bíbélì nígbà tó yá, pàápàá jù lọ àwọn tó yàwòrán sínú àwọn Bíbélì èdè Jámánì.

Bíbélì lédè Jámánì tí Koberger ṣe lọ́dún 1483 gbajúmọ̀ gan-an, àmọ́ nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀, èyí nìkan ni Koberger lè tẹ̀ jáde. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń bá a kàwé láti ṣàtúnṣe rẹ̀ fara balẹ̀ tún àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe kó lè bá Bíbélì Vulgate lédè Látìn tí ṣọ́ọ̀ṣì fọwọ́ sí mu, síbẹ̀, inú ìtumọ̀ Bíbélì táwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ṣe, èyí tí wọ́n fòfin dè ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìnlá ló ti kó àwọn ọ̀rọ̀ tó lò jọ. a Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, Póòpù Innocent Kẹjọ gbé ìgbésẹ̀ láti pa àwùjọ Ọmọlẹ́yìn Waldo run. Lẹ́yìn náà, àtakò ṣọ́ọ̀ṣì sí àwọn Bíbélì èdè ìbílẹ̀ wá ń pọ̀ sí i. Ní March 22, ọdún 1485, Bíṣọ́ọ̀bù àgbà Berthold ti Mainz, nílẹ̀ Jámánì gbé òfin kan jáde tó ka ṣíṣe ìtumọ̀ Bíbélì sí èdè Jámánì léèwọ̀. Ní January 4 ọdún tó tẹ̀ lé e, Berthold pààrọ̀ òfin náà. Nítorí àtakò tí wọ́n ń ṣe sí Bíbélì yìí, Koberger kò tún gbójúgbóyà mọ́ láti tẹ Bíbélì lédè Jámánì.

Bó ti wù kó rí, iṣẹ́ tí Anton Koberger ti ṣe kò já sásán. Ó mú ipò iwájú nínú lílo ọgbọ́n ìtẹ̀wé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí láti ṣe ọ̀pọ̀ ìwé lóríṣiríṣi tí kò wọ́nwó, tó sì wà káàkiri ilẹ̀ Yúróòpù. Iṣẹ́ ìwé títẹ̀ tí Koberger ṣe ti ṣèrànwọ́ láti mú kí Bíbélì dé ọwọ́ gbogbo èèyàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ka àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo—Látorí Jíjẹ́ Aládàámọ̀ Dórí Jíjẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì,” nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ March 15, 2002.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún: àwòrán Dáníẹ́lì nínú ihò kìnìún; Lẹ́tà ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ olómi wúrà; Àwọn lẹ́tà ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbẹ́ dáadáa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Koberger

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa Bíbélì tí Koberger tẹ̀ lédè Látìn àti Jámánì, ó ní ọ̀ṣọ́ lára àti àlàyé Jẹ́nẹ́sísì 1:1

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Gbogbo fọ́tò inú Bíbélì: Ìyọ̀ǹda látọ̀dọ̀ American Bible Society Library; Koberger: Mit freundlicher Genehmigung der Linotype GmbH