Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣé òótọ́ ni pé àwọn èèrà máa ń pèsè oúnjẹ sílẹ̀ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn tí wọ́n sì máa ń kó àwọn oúnjẹ jọ nígbà ìkórè?

Òwe 6:6-8 sọ pé: “Tọ eèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ; wo àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí o sì di ọlọ́gbọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní olùdarí, tàbí onípò àṣẹ tàbí olùṣàkóso, ó ń pèsè oúnjẹ rẹ̀ sílẹ̀ àní ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn; ó ti kó àwọn ìpèsè oúnjẹ rẹ̀ jọ àní nígbà ìkórè.”

Onírúurú èèrà ló máa ń kó oúnjẹ jọ lóòótọ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èyí tí Sólómọ́nì sọ ló wọ́pọ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì lóde òní, ìyẹn àwọn èèrà tó máa ń kórè (Messor semirufus).

Ìwádìí kan sọ pé, “àwọn èèrà tó máa ń wá oúnjẹ máa ń kúrò nínú ilé wọn lákòókò tójú ọjọ́ dáa láti lọ wá oúnjẹ . . . [wọ́n á sì] kó èso jọ ní gbogbo oṣù tójú ọjọ́ móoru nínú ọdún.” Wọ́n lè kó èso jọ láti ara ohun ọ̀gbìn tàbí láti orí ilẹ̀. Wọ́n máa ń ṣe ilé sábẹ́ ilẹ̀ nítòsí oko, níbi ilé ìkó-oúnjẹ-pamọ́-sí, tí wọ́n á ti lè rí nǹkan oníhóró kó jọ.

Àwọn èèrà máa ń kó oúnjẹ pa mọ́ sínú ilé wọn nínú yàrá tó wà ní ìpele-ìpele, tí wọ́n á sì wá ṣe àwọn ọ̀nà tó máa dé ibẹ̀. Ibi tí wọ́n ń kó oúnjẹ sí yìí lè fẹ̀ tó sẹ̀ǹtímítà méjìlá ní gígùn, ó sì lè ga tó sẹ̀ǹtímítà kan. Torí náà, àwọn èèrà tó ń kórè tí wọ́n ní oúnjẹ tó pọ̀ tó lè wà láàyè “fún ohun tó lé ní oṣù mẹ́rin tí wọ́n á sì máa lo oúnjẹ àti omi tí wọ́n ti tọ́jú pa mọ́.”

Àwọn nǹkan wo ló jẹ́ ara iṣẹ́ agbọ́tí ọba?

Nehemáyà ni agbọ́tí Ọba Atasásítà tó ń ṣàkóso ìlú Páṣíà. (Nehemáyà 1:11) Ní ààfin ọba láyé àtijọ́ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé, kì í ṣe ìránṣẹ́ kan lásán ló ń ṣe agbọ́tí ọba. Kàkà bẹ́ẹ̀, òṣìṣẹ́ ọba onípò ńlá ni. Àwọn ìwé àtàwọn àwòrán àtijọ́ nípa àwọn agbọ́tí jẹ́ ká mọ àwọn ohun kan nípa ojúṣe Nehemáyà ní ààfin ọba ilẹ̀ Páṣíà.

Agbọ́tí máa ń tọ́ ọtí ọba wò, kí ọba má bàa jẹ májèlé. Torí náà, àwọn ọba máa ń fọkàn tán àwọn agbọ́tí wọn pátápátá. Ọ̀mọ̀wé Edwin M. Yamauchi sọ pé: “Ìdìtẹ̀ tó wọ́pọ̀ láàfin ọba Páṣíà nígbà yẹn jẹ́ ká rí ìdí tó fi jẹ́ pé wọ́n nílò òṣìṣẹ́ ààfin tó ṣeé fọkàn tán.” Ó ṣeé ṣe kí agbọ́tí tún jẹ́ òṣìṣẹ́ tí ọba yàn láàyò tí ọba lè fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan. Bó sì ṣe jẹ́ pé ojoojúmọ́ ló ń jíṣẹ́ fún ọba, èyí lè mú kó láǹfààní láti pinnu ẹni tó lè rí ọba.

Ipò tí Nehemáyà wà lè jẹ́ ara ohun tó mú kí ọba gbà pé kó pa dà lọ sí Jerúsálẹ́mù láti tún àwọn ògiri rẹ̀ kọ́. Kò sí àní-àní pé Ọba yìí mọyì Nehemáyà gan-an. Bíbélì The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Ohun tí ọba kàn fi dá a lóhùn ni pé ‘Ìgbà wo lo máa pa dà?’”—Nehemáyà 2:1-6.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ère àfin Páṣíà tó wà ní Persepolis

[Àwòrán]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Agbọ́tí

Ọba Sásítà

Dáríúsì ńlá

[Credit Line]

© The Bridgeman Art Library International