Bí O Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Nínú Ọdún Àkọ́kọ́ Ìgbéyàwó
Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Bí O Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Nínú Ọdún Àkọ́kọ́ Ìgbéyàwó
Ọkọ sọ pé: “Ó yà mí lẹ́nu pé èmi àti ìyàwó mi yàtọ̀ síra wa gan-an! Bí àpẹẹrẹ, mo máa ń tètè jí, àmọ́ òun máa ń pẹ́ jí. Mi ò lóye bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára rẹ̀! Ohun mìíràn ni pé tí mo bá se oúnjẹ, ó máa ń rí nǹkan wí sí mi gan-an, àgàgà bí mo ṣe máa ń fi aṣọ tá a fi ń nu àwo nu ọwọ́ mi.”
Ìyàwó sọ pé: “Ọkọ mi kì í sọ̀rọ̀ púpọ̀. Àmọ́ bá a ṣe ń ṣe ní ilé tí mo ti wá ti mọ́ mi lára. A máa ń sọ̀rọ̀ gan-an, pàápàá nígbà oúnjẹ. Nígbà tí ọkọ mi bá se oúnjẹ, aṣọ tó wà fún nínu àwo ló máa ń fi nu ọwọ́! Ìyẹn máa ń múnú bí mi! Kí ló dé táwọn ọkùnrin fi ṣòroó lóye tó bẹ́ẹ̀? Báwo ni tọkọtaya ṣe lè mú kí àjọgbé wọn yọrí sí rere?”
TÓ BÁ jẹ́ pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ni, ṣé o ní irú ìṣòro yẹn? Ṣé ó jọ pé ẹnì kejì rẹ̀ ṣàdédé ní àbùkù àti kùdìẹ̀kudiẹ tí kò ní nígbà tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra yín sọ́nà ni? Báwo lo ṣe lè dín “wahalà” tí àwọn tọkọtaya máa ń ní kù?—1 Kọ́ríńtì 7:28, Bibeli Mimọ.
Ohun àkọ́kọ́ ni pé, má ṣe retí pé ẹ̀jẹ́ tẹ́ ẹ jẹ́ lọ́jọ́ ìgbéyàwó yín ti sọ ẹ̀yin méjèèjì dẹni tó mọ̀ nípa ọ̀ràn lọ́kọláya dáadáa. O lè ti mọ bá a ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn nígbà tí o kò tíì ṣègbéyàwó, ìmọ̀ yẹn sì ti lè pọ̀ sí i nígbà tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra yín sọ́nà. Àmọ́, ìgbéyàwó yóò dán ìmọ̀ tó o ní yẹn wò lóríṣiríṣi ọ̀nà, ó sì lè mú kó o ní ìmọ̀ tuntun sí i. Ṣé o máa ṣàṣìṣe? Ó dájú pé wàá ṣàṣìṣe. Ǹjẹ́ o lè ní ìmọ̀ tó o nílò? Bẹ́ẹ̀ ni!
Ọ̀nà tó dára jù lọ téèyàn lè gbà mú kí ìmọ̀ èyíkéyìí téèyàn ní pọ̀ sí i ni pé, kéèyàn lọ bá ẹni tó mọ̀ dáadáa nípa ọ̀ràn náà, kéèyàn sì lo ìmọ̀ràn tó bá fúnni. Jèhófà Ọlọ́run ni ẹni tó mọ̀ jù lọ nípa ọ̀ràn lọ́kọláya. Ó ṣe tán, òun ni Ẹni tó dá wa pẹ̀lú ìfẹ́ láti ṣègbéyàwó. (Jẹ́nẹ́sísì 2:22-24) Kíyè sí bí Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro, ká sì ní ìmọ̀ tá a nílò láti mú ìgbéyàwó wa ṣàṣeyọrí lọ́dún àkọ́kọ́, kó sì máa bá a lọ́ bẹ́ẹ̀.
ÌMỌ̀ 1. KỌ́ BÓ O ṢE LÈ BÁNI SỌ̀RỌ̀
Kí ni àwọn ìṣòro náà? Ọkọ kan tó ń jẹ́ Keiji, a tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Japan, máa ń gbàgbé nígbà míì pé ìpinnu tóun bá ṣe máa kan ìyàwó òun. Ó sọ pé: “Mo máa ń gba ìwé ìkésíni láìfọ̀rọ̀ náà tó ìyàwó mi létí. Nígbà tó bá yá, màá wá rí i pé kò ní ṣeé ṣe fún un láti lọ síbi tí wọ́n pè wá sí náà.” Ọkọ kan tó ń jẹ́ Allen, ń gbé lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, ó sọ pé: “Mo rò pé kò bójú mu pé kí ọkùnrin máa fọ̀rọ̀ lọ ìyàwó rẹ̀ kó tó ṣe ìpinnu.” Ó ní ìṣòro nítorí ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ ọ dàgbà. Ohun kan náà ló ṣe Dianne, obìnrin kan tó ń gbé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ó sọ pé: “Ohun tó ti mọ́ mi lára ni pé kí n máa béèrè àmọ̀ràn lọ́dọ̀ ìdílé mi. Nítorí náà, nígbà tí mo kọ́kọ́ ṣègbéyàwó, àwọn ará ilé mi ni mo máa ń fọ̀rọ̀ lọ̀ tí mo bá fẹ́ ṣe ìpinnu, dípò kí n fọ̀rọ̀ lọ ọkọ mi.”
Kí ni ojútùú rẹ̀? Má gbàgbé pé Jèhófà Ọlọ́run ń wo tọkọtaya pé wọ́n jẹ́ “ara kan.” (Mátíù 19:3-6) Lójú Ọlọ́run, kò sí àjọṣe àárín àwọn èèyàn tó ṣe pàtàkì ju àjọṣe tó wà láàárín ọkọ àti aya lọ! Láti lè mú ki àjọṣe yẹn máa lágbára sí i, wọ́n ní láti máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ déédéé.
Tọkọtaya kan lè kọ́ ohun tó pọ̀ látinú ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run gbà bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, jọ̀wọ́ ka ìjíròrò tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 18:17-33. Kíyè sí i pé Ọlọ́run pọ́n Ábúráhámù lé lọ́nà mẹ́ta. (1) Jèhófà ṣàlàyé ohun tóun fẹ́ ṣe. (2) Ó fetí sílẹ̀ nígbà tí Ábúráhámù ń ṣàlàyé èrò rẹ̀. (3) Dé ìwọ̀n àyè kan, Jèhófà gbà láti ṣe ohun tí Ábúráhámù fẹ́. Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yẹn tó o bá ń bá ọkọ tàbí aya rẹ sọ̀rọ̀?
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ọ̀rọ̀ kan tó kan ẹnì kejì yín, (1) ṣàlàyé bó o ṣe máa bójú tó ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ má ṣe gbé ìpinnu kalẹ̀, àbá ni kó o mú wá, (2) ní kí ẹnì kejì rẹ sọ èrò rẹ̀, kó o sì gbà pé ó ní ẹ̀tọ́ láti ní èrò tó yàtọ̀ àti pé (3) ‘jẹ́ kí ìfòyebánilò rẹ di mímọ̀’ nípa gbígba èrò ẹnì kejì rẹ tó bá yẹ bẹ́ẹ̀.—Fílípì 4:5.
ÌMỌ̀ 2. KỌ́ BÉÈYÀN ṢE Ń LO ÌFÒYEBÁNILÒ
Kí ni ìṣòro náà? Ó wà lọ́wọ́ ìdílé tó o ti wá àti ibi tí wọ́n ti tọ́ ẹ dàgbà, ó lè jẹ́ pé ńṣe lo máa ń sọ èrò rẹ lọ́nà tó le, tàbí kó o máa sọ̀rọ̀ láìro bó ṣe máa rí lára ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, Liam, tó ń gbé ní Yúróòpù, sọ pé: “Níbi tí mo ti wá, ńṣe làwọn èèyàn kàn máa ń sọ̀rọ̀ gbàùgbàù. Bí mo ṣe máa ń sọ̀rọ̀ gbàùgbàù máa ń múnú bí ìyàwó mi. Mo ní láti kọ́ béèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́tù.”
Fílípì 2:3, 4) Ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba míṣọ́nnárì kan lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó pẹ̀lú. Ó ní: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́.” Nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, a tún lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí “ẹni pẹ̀lẹ́” sí “ẹni tó ń fòye báni lò.” (2 Tímótì 2:24) Ẹni tó ń fòye bani lò máa ń mọ bí ọ̀ràn kan ti gbẹgẹ́ tó, ó sì máa ń fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú nǹkan, kì í múnú bí àwọn èèyàn.
Kí ni ojútùú rẹ̀? Má ṣe rò pé ẹnì kejì rẹ á fẹ́ kó o máa bá òun sọ̀rọ̀ lọ́nà tó o máa ń gbà sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀. (GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Nígbà tínú bá ń bí ẹ sí ọkọ tàbí aya rẹ, fojú wò ó pé ọ̀rẹ́ rẹ àtàtà kan tàbí ẹni tó gbà ẹ́ síṣẹ́ lò ń bá sọ̀rọ̀ dípò ẹnì kejì rẹ. Ṣé ohùn tó le yẹn tàbí àwọn ọ̀rọ̀ kan náà tó le lo máa fi bá a sọ̀rọ̀? Lẹ́yìn náà, ronú ìdí tí ọkọ tàbí aya rẹ fi yẹ lẹ́ni tó o gbọ́dọ̀ fi ọ̀wọ̀ àti òye tó pọ̀ hàn fún ju èyí tó o máa fi bá ọ̀rẹ́ rẹ tàbí ẹni tó gbà ẹ́ síṣẹ́ sọ̀rọ̀.—Kólósè 4:6.
ÌMỌ̀ 3. KỌ́ BÓ O ṢE MÁA MÚ ARA RẸ BÁ IPÒ TUNTUN MU
Kí ni ìṣòro náà? Níbẹ̀rẹ̀, ọkọ lè máa lo ipò orí rẹ̀ lọ́nà tó ni aya rẹ̀ lára, tàbí kí aya má mọ bó ṣe yẹ kóun fọgbọ́n dábàá àwọn nǹkan fún ọkọ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ kan tó ń jẹ́ Antonio lórílẹ̀-èdè Ítálì sọ pé: “Ekukáká ni bàbá mi fi máa ń fi ọ̀ràn lọ màmá mi nígbà tó bá fẹ́ ṣe ìpinnu tó kan ìdílé wa. Nítorí náà, ní ìbẹ̀rẹ̀, ńṣe ni mò ń ṣàkóso ìdílé mi bí ọba.” Aya kan tó ń jẹ́ Debbie lórílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé: “Mo ṣe é lọ́ranyàn fún ọkọ mi pé kó túbọ̀ máa wà ní mímọ́, kó sì máa to àwọn nǹkan nigínnigín. Àmọ́, bí mo ṣe máa ń pàṣẹ fún un mú kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ burú sí i.”
Ojútùú wo ló wà fún ọkọ? Àwọn ọkọ kan kò mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tí Bíbélì sọ pé kí aya jẹ́ onítẹríba àti kí ọmọ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí wọn. (Kólósè 3:20; 1 Pétérù 3:1) Bíbélì sọ pé kí ọkọ “fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan,” àmọ́ kò sọ pé òbí àti ọmọ yóò di ara kan. (Mátíù 19:5) Jèhófà sọ pé aya jẹ́ àṣekún tàbí ẹnì kejì fún ọkọ. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Kò sọ pé ọmọ jẹ́ àṣekún tàbí ẹnì kejì fún òbí. Bí ọkọ kan bá ń fojú ọmọ wo ìyàwó rẹ̀, tó sì ń hùwà sí i bẹ́ẹ̀, ṣé ó ń bọlá fún ètò ìgbéyàwó?
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ ẹ́ pé kó o máa hùwà sí aya rẹ gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣe sí ìjọ Kristẹni. O lè mú kó rọrùn fún aya rẹ láti wò ẹ́ gẹ́gẹ́ bí orí rẹ̀ (1) tí o kì í bá mú un lọ́ranyàn pé kó tẹrí ba fún ẹ láìsí pé ó ń ṣe àṣìṣe kankan àti (2) tí o bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ, àní tí ìṣòro bá tiẹ̀ dé.—Éfésù 5:25-29.
Ojútùú wo ló wà fún aya? O ní láti gbà pé ọkọ rẹ ni Ọlọ́run yàn nísinsìnyí láti jẹ́ orí rẹ. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Bó o bá bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ, Ọlọ́run lo bọ̀wọ̀ fún yẹn. Tó o bá ta ko ipò orí ọkọ rẹ, kì í ṣe èrò rẹ nípa ọkọ rẹ nìkan lò ń fi hàn, o tún ń fi èrò rẹ nípa Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ká ṣe hàn.—Kólósè 3:18.
Nígbà tó o bá ń bójú tó ìṣòro tó le, ìṣòro yẹn ni kó o máa bá jà, má ṣe bá ọkọ rẹ jà. Bí àpẹẹrẹ, Ayaba Ẹ́sítérì fẹ́ kí ọkọ rẹ̀ Ahasuwérúsì Ọba bójú tó ìwà àìṣẹ̀tọ́ kan. Kàkà kí obìnrin náà gbéjà ko ọkọ rẹ̀, ó fòye ṣàlàyé ìṣòro náà fún un. Ọkọ rẹ̀ gba àbá tó mú wá, ó sì mú àìṣẹ̀tọ́ náà kúrò níkẹyìn. (Ẹ́sítérì 7:1-4; 8:3-8) Ó ṣeé ṣe kí ọkọ rẹ wá nífẹ̀ẹ́ rẹ jinlẹ̀ tó o bá (1) jẹ́ kó rí àyè kọ́ nípa iṣẹ́ tuntun tó gbà gẹ́gẹ́ bí orí ìdílé, (2) tí o sì ń bọ̀wọ̀ fún un, àní bó bá tiẹ̀ ṣe àṣìṣe.—Éfésù 5:33.
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Kàkà kó o máa sọ àwọn àtúnṣe tó yẹ kí ọkọ rẹ ṣe, ńṣe ló yẹ kó o máa ronú nípa àwọn àtúnṣe tó yẹ kí ìwọ fúnra rẹ ṣe. Ìwọ ọkọ, nígbà tó o bá múnú bí aya rẹ nípa ọ̀nà tó ò ń gbà lo ipò orí rẹ, béèrè lọ́wọ́ aya rẹ pé, kí ló yẹ kí n ṣe kí nǹkan lè dára sí i? Lẹ́yìn náà, kọ àwọn àbá náà sílẹ̀. Ìwọ aya, nígbà tí ọkọ rẹ bá sọ pé o kò bọ̀wọ̀ fún òun, béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, kí ló yẹ kó o ṣe kí nǹkan lè dára sí i? Lẹ́yìn náà, kó o kọ àwọn àbá náà sílẹ̀.
Má Retí Ohun Tó Pọ̀ Jù
A lè fi àjọgbé ọkọ àti aya lọ́nà tó lárinrin wé kíkọ́ béèyàn ṣe ń gun kẹ̀kẹ́. Wàá retí pé èèyàn á máa ṣubú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bó ṣe ń mọ kẹ̀kẹ́ náà gùn. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ tọkọtaya ṣe rí, ó yẹ kó o máa retí àṣìṣe tó ń tini lójú bó o ṣe ń ní ìrírí sí i.
Máa túra ká, kó o sì máa ṣàwàdà. Jẹ́ kí ọ̀ràn ọkọ tàbí aya rẹ jẹ ọ́ lógún, àmọ́ fi ara rẹ rẹ́rìn-ín nígbà tó o bá ṣàṣìṣe. Máa wá ohun tó máa mú inú ẹnì kejì rẹ dùn ní ọdún àkọ́kọ́ ìgbéyàwó yín. (Diutarónómì 24:5) Lékè gbogbo rẹ̀, jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa tọ́ ẹ sọ́nà nínú àjọṣe yín. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbéyàwó rẹ yóò máa lágbára sí i bọ́dún ṣe ń gorí ọdún.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
BÍ ARA RẸ PÉ . . .
▪ Ṣé ọkọ tàbí aya mi ni mo máa ń finú hàn, àbí àwọn ẹlòmíì ni mo máa ń fọ̀rọ̀ lọ̀?
▪ Ní wákàtí mẹ́rìnlélógún tó kọjá, kí ni mo ṣe ní pàtàkì tó fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya mi, tí mo sì ń bọ̀wọ̀ fún un?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11, 12]
Bíbélì Gba Ìgbéyàwó Wa Là
Toru àti Akiko fẹ́ràn ara wọn gan-an nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ ṣègbéyàwó. Àmọ́ oṣù mẹ́jọ lẹ́yìn náà, tọkọtaya tó jẹ́ ará Japan yìí pinnu láti kọ ara wọn sílẹ̀. Wọ́n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀.
Toru: “Mo wá rí i pé èmi àti ìyàwó mi kò bá ara wa mu tó bí mo ṣe rò. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a bá ń wo tẹlifíṣọ̀n, èmi fẹ́ran eré ìdárayá, àmọ́ òun fẹ́ran eré orí ìtàgé. Èmi fẹ́ràn láti máa jáde, àmọ́ òun fẹ́ràn láti máa jókòó sílé.”
Akiko: “Ọkọ mi máa ń ṣe gbogbo nǹkan tí àwọn ará ilé rẹ̀ bá ní kó ṣe, àmọ́ kò ní fọ̀rọ̀ lọ̀ mí. Mo bí i pé, ‘Ta ló ṣe pàtàkì sí ẹ, ìyá rẹ ni àbí èmi?’ Bákan náà, ẹnu yà mí gan-an sí bí ọkọ mi kì í ṣeé sọ òótọ́. Mo sọ fún un pé irọ́ kan ló ń múni pa igba irọ́, tí o kò bá jáwọ́ nínú ìwà yìí, màá kọ̀ ẹ́ sílẹ̀.”
Toru: “Gbogbo nǹkan tojú sú mi, ni mo bá ní kí ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tó dàgbà jù mí lọ gbà mí lámọ̀ràn nípa ọ̀nà tí màá gbà máa hùwà sí ìyàwó mi. Ó sọ fún mi pé: ‘Sáà sọ fún un pé kó pa ẹnu rẹ̀ mọ́. Tó bá ń ṣàròyé, lù ú bolẹ̀.’ Nígbà kan, mo gbá Akiko lójú, mo sì ti tábìlì ṣubú. Ìjà náà lágbára, ló bá fi ilé sílẹ̀. Mo ní láti lọ mú un wálé láti òtẹ́ẹ̀lì kan nílùú Tokyo. Níkẹyìn, a pinnu pé ká kọ ara wa sílẹ̀. Ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí í kó ẹrù rẹ̀ ní àárọ̀ ọjọ́ yẹn, nígbà tí mò ń lọ sí ọ́fíìsì.”
Akiko: “Aago ẹnu ọ̀nà ń dún bí mo ṣe ń gbé àwọn àpò mi lọ sí ẹnu ọ̀nà iwájú ilé. Obìnrin kan ló dúró síbẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Mo ní kó wọlé.”
Toru: “Nígbà tí mo dé ọ́fíìsì, mo tún èrò pa lórí ọ̀ràn ìkọ̀sílẹ̀ náà, ni mo bá tètè pa dà sílé. Nígbà tí mo délé, mo bá ìyàwó mi tó ń bá obìnrin náà sọ̀rọ̀. Obìnrin náà sọ fún mi pé: ‘Ohun kan wà tí ẹ̀yin méjèèjì lè ṣe pa pọ̀. Ṣé wàá fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?’ Mo sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tó lè gba ìgbéyàwó wa là!’”
Akiko: “Obìnrin náà ṣètò bá a ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀rọ̀ wa bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà nígbà tá a ka Bíbélì tó sọ nípa ètò ìgbéyàwó. Ó sọ pé: ‘Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin yóò ṣe fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.’”—Jẹ́nésísì 2:24.
Toru: “Mo lóye ọ̀rọ̀ náà lójú ẹsẹ̀. Mo sọ fún àwọn òbí mi pé, ‘Láti ìsinsìnyí lọ, màá máa fọ̀rọ̀ lọ ìyàwó mi kí n tó ṣèpinnu èyíkéyìí.’ Mo tún jáwọ́ nínú mímu ọtí àmujù. Nígbà tí mo sì kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kórìíra irọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ kìkì òótọ́.”
Akiko: “Èmi náà yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, mo máa ń gbó ọkọ mi lẹ́nu. Àmọ́ nígbà tí mo rí i pé ó ti ń fi ìlànà Bíbélì sílò, mo túbọ̀ ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. (Éfésù 5:22-24) Nísinsìnyí, ó ti lé ní ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n tá a ti ń gbádùn ìgbéyàwó alárinrin. Ó ṣeé ṣe fun wa láti borí àwọn ìṣòro wa bá a ti ń mọ ara wa dáadáa tá a sì ń lo àwọn ìlànà tó bọ́gbọ́n mu tó wà nínú Bíbélì.”