Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ Jésù tiẹ̀ bá èyíkéyìí lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá tan?

Ìwé Mímọ́ kò fún wa ní ìdáhùn pàtó sí ìbéèrè yìí. Àmọ́, ó jọ pé àwọn ìsọfúnni míì àti ìtàn sọ pé àwọn kan lára àwọn méjìlá náà bá Jésù tan.

Àwọn tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere dárúkọ àwọn obìnrin kan tó ń wo Jésù nígbà tó ń kú lọ lórí òpó igi oró. Ìwé Jòhánù 19:25 dárúkọ àwọn mẹ́rin: “Ìyá rẹ̀ [Màríà] àti arábìnrin ìyá rẹ̀ . . . ; Màríà aya Kílópà àti Màríà Magidalénì.” Tá a bá fi ẹsẹ yìí wé àlàyé tí Mátíù àti Máàkù ṣe lórí ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà yìí, ó lè jẹ́ ká gbà pé àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n ìyá Jésù ni Sàlómẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Sàlómẹ̀ yìí ló bí àwọn ọmọkùnrin Sébédè. (Mátíù 27:55, 56; Máàkù 15:40) Ní ibòmíì nínú Bíbélì, wọ́n pe àwọn ọmọkùnrin tí obìnrin yìí bí ní Jákọ́bù àti Jòhánù, nítorí náà, àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n ìyá Jésù ló bí àwọn ọmọ yìí. Jésù pe tẹ̀gbọ́n-tàbúrò tí wọ́n jẹ́ apẹja yìí pé kí wọ́n wá di ọmọ ẹ̀yìn òun.—Mátíù 4:21, 22.

Àwọn ìwé ìtàn kan sọ pé àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù tó jẹ́ alágbàtọ́ Jésù ni Kílópà tàbí Álífíọ́sì, tó jẹ́ ọkọ ọ̀kan lára àwọn obìnrin tá a mẹ́nu kàn ní Jòhánù 19:25. Tí ìtàn yìí bá jóòótọ́, á jẹ́ pé ọmọ àbúrò tàbí ọmọ ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù tó jẹ́ alágbàtọ́ Jésù ni Jákọ́bù ọmọkùnrin Álífíọ́sì tó jẹ́ ọ̀kan lára àpọ́sítélì méjìlá.—Mátíù 10:3.

Báwo ni Jésù àti Jòhánù Oníbatisí ṣe bára wọn tan?

Àwọn kan gbà pé ọmọ ẹ̀gbọ́n ọmọ àbúrò ni àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí. Báwọn èèyàn ṣe túmọ̀ Lúùkù 1:36 ló mú kí wọ́n gbà bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Bibeli Mimọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé, ọmọ ẹ̀gbọ́n ọmọ àbúrò ni Èlísábẹ́tì ìyá Jòhánù àti Màríà ìyá Jésù.

Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n lò nínú ẹsẹ yìí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtó. Ohun tó ń sọ ni pé, àwọn obìnrin méjèèjì kàn bára wọn tan ni, kò túmọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n ọmọ àbúrò. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì ìyẹn The Interpreter’s Dictionary of the Bible sọ pé, “ọ̀rọ̀ náà fẹjú gan-an débi pé a kò lè sọ pàtó bí wọ́n ṣe bára wọn tan.” Ibo wá ni èrò náà pé Jésù àti Jòhánù jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n ọmọ àbúrò ti wá? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Catholic Encyclopedia, dáhùn pé: “Gbogbo nǹkan tá a mọ̀ nípa . . . òbí Màríà . . . wá látinú ìwé Àpókírífà.”

Nítorí náà, Jésù àti Jòhánù bára wọn tan bákan ṣá, àmọ́ kò túmọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n ọmọ àbúrò.