5 Ibo La Ti Máa Gbàdúrà, Ìgbà Wo La sì Máa Gbà Á?
5 Ibo La Ti Máa Gbàdúrà, Ìgbà Wo La sì Máa Gbà Á?
KÒ SÍ iyèméjì pé wàá ti rí i tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ń tẹnu mọ́ ọn pé àwọn ilé ràgàjì kan jẹ́ ilé àdúrà, tí wọ́n sì máa ń sọ pé àkókò kan wà tó yẹ kéèyàn máa gbàdúrà lójúmọ́. Ǹjẹ́ Bíbélì sọ ibi pàtó kan tá a ti máa gbàdúrà àti ìgbà tá a máa gbàdúrà?
Òótọ́ ni pé Bíbélì sọ pé àwọn àkókò kan wà tó yẹ kéèyàn gbàdúrà. Bí àpẹẹrẹ, kí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹun, Jésù gbàdúrà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. (Lúùkù 22:17) Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì péjọ fún ìjọsìn, wọ́n gbàdúrà. Ohun tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń ṣe yìí kì í ṣe tuntun, torí pé ó ti pẹ́ tí àwọn Júù ti máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nínú sínágọ́gù àti nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí tẹ́ńpìlì jẹ́ “Ilé àdúrà fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”—Máàkù 11:17.
Nígbà táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá kóra jọ tí wọ́n sì gbàdúrà sí i, àdúrà wọn máa ń gbà. Bí èrò àwùjọ náà bá ṣọ̀kan, tí àdúrà tí wọ́n gbà bá sì bá àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ mu, inú Ọlọ́run máa dùn sí i. Àdúrà bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè mú kí Ọlọ́run ṣe ohun tí kò fẹ́ ṣe tẹ́lẹ̀. (Hébérù 13:18, 19) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbàdúrà déédéé ní àwọn ìpàdé wọn. A rọ̀ ẹ́ pé kí ìwọ náà wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò rẹ, kó o sì wá gbọ́ àwọn àdúrà náà.
Àmọ́ Bíbélì kò sọ pé àkókò kan pàtó tàbí ibì kan pàtó lèèyàn ti lè gbàdúrà. Nínú Bíbélì, a rí ìtàn nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n gbàdúrà ní oríṣiríṣi àkókò àti ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Jésù sọ pé: “Nígbà tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ àti, lẹ́yìn títi ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tí ń bẹ ní ìkọ̀kọ̀; nígbà náà Baba rẹ tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀ yóò san án padà fún ọ.”—Mátíù 6:6.
Ǹjẹ́ inú rẹ kò dùn láti gbọ́ èyí? O lè bá Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run sọ̀rọ̀ nígbàkigbà, ní ìwọ nìkan, tó sì dájú pé á gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Abájọ tí Jésù fi sábà máa ń fẹ́ dá wà kó bàa lè gbàdúrà! Lákòókò kan, ó lo gbogbo òru nígbà tó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, tó ń béèrè ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run lórí ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fẹ́ ṣe.—Lúùkù 6:12, 13.
Àwọn ọkùnrin àti obìnrin míì nínú Bíbélì gbàdúrà nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe ìpinnu tó lágbára tàbí iṣẹ́ kan tó kà wọ́n láyà. Láwọn ìgbà míì, wọ́n gbàdúrà sókè, ìgbà míì sì rèé, ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa ń dá gbàdúrà, wọ́n sì tún máa ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí àwùjọ. Kókó ibẹ̀ ni pé wọ́n máa ń gbàdúrà. Ọlọ́run tiẹ̀ ké sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ máa gbàdúrà láìdabọ̀.” (1 Tẹsalóníkà 5:17) Ọlọ́run ṣe tán láti máa gbọ́ àdúrà àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Èyí fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa.
Òótọ́ ni pé, nínú ayé onímọtara-ẹni-nìkan tá à ń gbé yìí, ọ̀pọ̀ ń ṣe kàyéfì pé àdúrà kò wúlò. Ìwọ náà lè béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ àdúrà lè ràn mí lọ́wọ́?’
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
A lè gbàdúrà nígbàkigbà àti níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀