Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Lo Ṣe Lè Borí Èrò Òdì?

Báwo Lo Ṣe Lè Borí Èrò Òdì?

Báwo Lo Ṣe Lè Borí Èrò Òdì?

ǸJẸ́ o ti ní èrò òdì rí. Lóòótọ́ kò sẹ́ni tí kì í ní èrò òdì. Ní àkókò tá a wà yìí, ọrọ̀ ajé ti dẹnu kọlẹ̀, ìwà ipá pọ̀ káàkiri, kò sì sí ìdájọ́ òdodo. Abájọ tí àìmọye èèyàn fi ní ìdààmú ọkàn àti ẹ̀bi tó pàpọ̀jù, tí wọ́n sì ń ronú pé àwọn kò já mọ́ nǹkan kan.

Irú èrò bẹ́ẹ̀ léwu. Wọ́n lè sọ wa dẹni tí kò lè ṣe nǹkan láṣeyanjú, tí kò lè ronú dáadáa, tí kò sì ní láyọ̀. Bíbélì sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” (Òwe 24:10) A nílò agbára àti okun inú ká lè máa gbé nínú ayé oníwàhálà yìí nìṣó. Nítorí náà, ó pọn dandan pé ká má ṣe jẹ́ kí èrò òdì borí wa. a

Bíbélì fún wa láwọn ohun kan tó gbéṣẹ́ tá a lè fi kojú èrò òdì. Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó dá ohun gbogbo tó sì ń gbé ìwàláàyè ró, kò fẹ́ ká bọ́hùn tàbí ká sọ̀rètí nù. (Sáàmù 36:9) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ọ̀nà mẹ́ta yẹ̀ wò tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè gbà ràn wá lọ́wọ́ láti borí èrò òdì.

Jẹ́ Kó Yé Ọ Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Rẹ

Àwọn kan rò pé ọwọ́ Ọlọ́run ti dí ju pé kó fiyè sí ẹ̀dùn ọkàn àwọn. Ṣé èrò tìẹ náà nìyẹn? Bíbélì mú un dá wa lójú pé ọ̀ràn wa jẹ Ẹlẹ́dàá lọ́kàn. Onísáàmù náà sọ pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” (Sáàmù 34:18) Ìtùnú ńlá gan-an ló jẹ́ pé Ọba Aláṣẹ tó jẹ́ alágbára gbogbo sún mọ́ wa nígbà tá a bá wà nínú ìdààmú!

Ọlọ́run kò jìnnà sí wa, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣàìgbọ́ igbe wa fún ìrànwọ́. Bíbélì sọ pé, “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó sì tètè máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń jìyà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú ìgbèkùn ní Íjíbítì ní nǹkan bí egbèjìdínlógún ó dín ọgọ́rùn-ún [3,500] ọdún sẹ́yìn, ó sọ pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, mo ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ní Íjíbítì níṣẹ̀ẹ́, mo sì ti gbọ́ igbe ẹkún wọn nítorí àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́; nítorí tí mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú. Èmi ń sọ̀ kalẹ̀ lọ láti dá wọn nídè.”—Ẹ́kísódù 3:7, 8

Ọlọ́run mọ gbogbo bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Ó ṣe tán, “Òun ni ó ṣẹ̀dá wa, kì í sì í ṣe àwa fúnra wa.” (Sáàmù 100:3) Nítorí náà, tá a bá rò pé èèyàn bíi tiwa kò lóye wa, ó dájú pé Ọlọ́run lóye wa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Nítorí kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan [ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan], nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:7) Kódà èrò inú wa lọ́hùn-ún pàápàá kò fara sin fún Ọlọ́run.

Òótọ́ ni pé Jèhófà tún mọ̀ pé a máa ń ṣàṣìṣe a sì ní àwọn kùdìẹ̀kudiẹ. Àmọ́, a dúpẹ́ pé Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ máa ń dárí jini. Dáfídì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí Ọlọ́run mí sí láti kọ Bíbélì sọ pé: “Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:13, 14) Ojú tá a fi ń wo ara wa kọ́ ni Ọlọ́run fi ń wò wá. Ó máa ń wo ohun rere tó wà nínú wa, ó sì máa ń gbójú fo ohun tí kò dára tó wà lára wa, ìyẹn tá a bá ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.—Sáàmù 139:1-3, 23, 24.

Nípa báyìí, tí èrò pé a kò já mọ́ nǹkan kan bá ń dà wá láàmú, a ní láti borí rẹ̀. A gbọ́dọ̀ rántí pé Ọlọ́run mọ̀ wá dáadáa!—1 Jòhánù 3:20.

Ní Àjọṣe Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Ọlọ́run

Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wò wá wo ara wa? Yóò jẹ́ kó rọrùn fún wa láti ṣe nǹkan kejì táá jẹ́ ká borí èrò òdì, ìyẹn ni níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ṣé ìyẹn ṣeé ṣe?

Gẹ́gẹ́ bíi Bàbá onífẹ̀ẹ́, Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní àjọṣe rere pẹ̀lú òun. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Òtítọ́ tó yani lẹ́nu kan ni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìlera, a lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run.

Ọlọ́run ti sọ ẹni tóun jẹ́ fún wa nínú Bíbélì ká bàa lè mọ̀ ọ́n dáadáa. Nípa kíka Bíbélì déédéé, a lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra tí Ọlọ́run ní. b Bá a ṣe ń ṣàṣàrò lórí irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀, a óò túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà gan-an. A óò túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an, pé ó jẹ́ Bàbá onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú.

Ríronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà nínú Bíbélì tún ń ṣe wá láǹfààní tó pọ̀. Tá a bá ń gba èrò Ọlọ́run sínú ọkàn wa, tá a sì ń jẹ́ kí wọ́n tọ́ wa sọ́nà, tí wọ́n ń tù wá nínú, tí wọ́n sì ń tọ́ ìṣísẹ̀ wa, ìyẹn á túbọ̀ jẹ́ ká sún mọ́ Bàbá wa ọ̀run dáadáa. A ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì nígbà tá a bá ń gbéjà ko àwọn èrò tó ń dà wá láàmú tàbí tó ń gbé wa lọ́kàn sókè. Onísáàmù náà sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.” (Sáàmù 94:19) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè tuni nínú lọ́nà tó jinlẹ̀. Tá a bá fìrẹ̀lẹ̀ gba ọ̀rọ̀ òtítọ́, à óò rí i pé ìtùnú àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run yóò rọ́pò èrò òdì tá a ní. Jèhófà a tipa bẹ́ẹ̀ tù wá lára bí òbí onífẹ̀ẹ́ ti ń tu ọmọ tó fara pa lára.

Ohun mìíràn tó ń mú kéèyàn di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ni bíbá a sọ̀rọ̀ déédéé. Bíbélì mú un dá wa lójú pé, “ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, [Ọlọ́run] ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòhánù 5:14) Ohun yòówù tí ì bá jẹ́ ìbẹ̀rù tàbí àníyàn wa, a lè gbàdúrà sí Ọlọ́run, kí a béèrè pé kó ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún Ọlọ́run, a óò ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóòmáa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 4:6, 7.

Tó o bá ń tẹ̀ lé ètò tó o ṣe láti máa ka Bíbélì, tó ò ń ṣàṣàrò lórí ohun tó o kà, tó o sì ń gbàdúrà, láìsí àní-àní wàá rí i pé àjọṣe rẹ pẹ̀lú Bàbá rẹ ọ̀run á máa lágbára sí i. Àjọṣe yẹn ni ohun ìjà tó lágbára láti fi gbógun ti èrò òdì. Kí ni ohun míì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

Fọkàn sí Ohun Tó Ò Ń Retí Lọ́jọ́ Ọ̀la

Kódà tá a bá dojú kọ ìṣòro tó le jù lọ pàápàá, a lè pa ọkàn wa pọ̀ sórí ohun rere. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ọlọ́run fún wa ní ohun tó dájú tá à ń retí lọ́jọ́ ọ̀la. Àpọ́sítélì Pétérù ṣàkópọ̀ àwọn ohun àgbàyanu tá à ń retí náà pé: “Ṣùgbọ́n ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn?

Gbólóhùn náà, “ọ̀run tuntun” ń tọ́ka sí ìjọba kan, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run lọ́run lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi. “Ilẹ̀ ayé tuntun” ń tọ́ka sí àwùjọ àwọn èèyàn tuntun lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run. Lábẹ́ ìṣàkóso “ọ̀run tuntun,” àwùjọ ilẹ̀ ayé tuntun yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo ohun tó ń fa èrò òdì. Bíbélì sọ nípa àwọn olóòótọ́ èèyàn tó máa gbé láyé nígbà yẹn, ó fi dá wa lójú pé Ọlọ́run “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.

Ó dájú pé, wàá gbà pé irú àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ń múnú ẹni dùn, wọ́n sì ń mórí ẹni yá. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé “ìrètí aláyọ̀” ni Bíbélì pe ohun tá à ń retí pé Ọlọ́run máa ṣe fún àwọn Kristẹni tòótọ́ lọ́jọ́ iwájú. (Títù 2:13) Tá a bá pa ọkàn wa pọ̀ sórí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la aráyé, ìyẹn sórí ìdí táwọn ìlérí wọ̀nyẹn fi dájú tó sì ṣeé gbọ́kàn lé, gbogbo èrò òdì á pòórá.—Fílípì 4:8.

Bíbélì fi ìrètí ìgbàlà wa wé àṣíborí. (1 Tẹsalóníkà 5:8) Láyé àtijọ́, ọmọ ogun kan kò ní lọ jagun láìdé àṣíborí. Ó mọ̀ pé àṣíborí ló máa gba gbogbo iná ọfà, tó sì máa ta wọ́n dà nù. Bí àṣíborí ṣe máa ń dáàbò bo orí, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí ṣe máa ń dáàbò bo èrò wa. Ríro àwọn èrò tó máa fi ìrètí kún ọkàn wa kò ní jẹ́ ká máa ro ìròkurò tó ń múni bẹ̀rù pé ọjọ́ ọ̀la kò ní dáa.

Nítorí náà, a lè borí èrò òdì. Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀! Ronú nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wò ẹ́, sún mọ́ ọn, kó o sì pa ọkàn pọ̀ sórí ìrètí tó wà fún ọjọ́ ọ̀la. Nígbà náà, wàá ní ìdánilójú pé wàá rí àkókò náà tí èrò òdì kò ní sí mọ́!—Sáàmù 37:29.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó lè pọn dandan pé kí àwọn tí ìsoríkọ́ tó lágbára ń dà láàmú fún àkókó tó gùn lọ rí dókítà tó mọṣẹ́ dunjú.—Mátíù 9:12.

b Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ August 1, 2009, ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó gbẹ́ṣẹ́ tó sì wúlò fún kíka Bíbélì.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]

“Nítorí tí mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú.”​—Ẹ́KÍSÓDÙ 3:7, 8

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]

“Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.”​—SÁÀMÙ 94:19

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

“Àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.”​—FÍLÍPÌ 4:7

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

Àwọn Ìwé Mímọ́ Tó Sọ Nípa Jèhófà Ọlọ́run Ń Tuni Nínú

“Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.”—Ẹ́KÍSÓDÙ 34:6.

“Ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” —2 KÍRÓNÍKÀ 16:9.

“Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—SÁÀMÙ 34:18.

“Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini.” —SÁÀMÙ 86:5.

“Jèhófà ń ṣe rere fún gbogbo gbòò, àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.”—SÁÀMÙ 145:9.

“Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’” —AÍSÁYÀ 41:13.

“Ìbùkún ni fún . . . Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 1:3.

“A óò sì fún ọkàn-àyà wa ní ìdánilójú níwájú rẹ̀ ní ti ohun yòówù nínú èyí tí ọkàn-àyà wa ti lè dá wa lẹ́bi, nítorí Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” —1 JÒHÁNÙ 3:19, 20.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Wọn Kò Jẹ́ Kí Èrò Òdì Borí Wọn

“Bàbá mi máa ń mutí lámujù, ó sì kó ìrora ọkàn tó pọ̀ bá mi. Ó ti pẹ́ gan-an tí mo ti ní èrò pé mi ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́ nígbà tí mo gbà kí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, mo kọ́ nípa ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Ìrètí yìí fi ayọ̀ kún ọkàn mi. Mo wá dẹni tó ń ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ìgbà gbogbo ni Bíbélì máa ń wà lọ́dọ̀ mi. Nígbà tí èrò òdì bá fẹ́ borí mi, màá nawọ́ mú un, màá sì ka àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tó ń tuni nínú. Kíkà nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tó fani mọ́ra máa ń mú un dá mi lójú pé mo ṣeyebíye lójú rẹ̀.”—Kátia, obìnrin ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n. c

“Mo ti sọ ọtí àmujù, igbó, oríṣiríṣi kokéènì di bárakú, mo sì máa ń fa èròjà kan tó ń jẹ́ glue, ságbárí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tí mo ní ni mo pàdánù, mo wá di alágbe. Àmọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo yí ìgbésí ayé mi pa dà pátápátá. Àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run ti wá dára gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì ní láti jìjàkadì pẹ̀lú èrò ẹ̀bi àti àìjámọ́ nǹkan kan tí mo ní, mo ti kọ́ bá a ṣe ń gbára lé àánú àti inú rere onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ó dá mi lójú pé Ọlọ́run yóò máa fún mi ní okun láti borí èrò òdì tí mo ní. Ohun tó dára jù lọ tí mo ní ni òtítọ́ Bíbélì tí mo mọ̀.”—Renato, ọkùnrin ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì.

“Látìgbà kékeré mi ni mo ti máa ń fara mi wé ẹ̀gbọ́n mi. Ìgbà gbogbo ni mo máa ń ronú pé mi ò lè ṣe tó bó ṣe máa ń ṣe. Mi ò dá ara mi lójú rárá nínú ohun tí mò ń ṣe. Àmọ́ mo pinnu pé kò ní sú mi, pé màá borí. Mo ti gbàdúrà láìsinmi sí Jèhófà, ó sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti borí èrò tí mo ní pé mi ò kúnjú ìwọ̀n. Inú mi dùn láti mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi gan-an, ó sì ń bójú tó mi!” —Roberta, obìnrin ẹni ọdún márùndínláàádọ́ta.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

c A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.