Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ó yẹ Kí N Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Kan?

Ṣé Ó yẹ Kí N Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Kan?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ṣé Ó yẹ Kí N Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Kan?

▪ Ṣé ẹ̀rù ń bà ẹ́ láti dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kan nítorí àgàbàgebè àti àìṣòótọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn aṣíwájú ẹ̀sìn? Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ rẹ ṣe rí rèé, òwe ilẹ̀ Faransé kan bá èrò rẹ mu, ó ní: “Àwọn tó sún mọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ló ń jìnnà sí Ọlọ́run.”

Ó ṣeé ṣe kó o bọ̀wọ̀ fún Bíbélì, kó o sì rò pé kò yẹ kí ìjọba àtàwọn èèyàn fi ẹ̀tọ́ láti dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kan du ẹnikẹ́ni. Àmọ́, o lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣé Ọlọ́run retí pé dandan ni kí èèyàn tó fẹ́ sin òun lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kan?’

Ìdáhùn tó ṣe ṣókí sí ìbéèrè náà ni pé, bẹ́ẹ̀ ni. Kí nìdí tó fi dá wa lójú bẹ́ẹ̀? Àti pé, ṣé ẹ̀sìn èyíkéyìí la lè dara pọ̀ mọ́?

Ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ Jésù. Ṣé Jésù dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kan? Nígbà tí Jésù wà ní kékeré, ó dara pọ̀ mọ́ àwọn ará ilé rẹ̀ àtàwọn míì tí wọ́n jẹ́ Júù tó jẹ́ àṣà wọn láti máa lọ ṣe ìjọsìn ní tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. (Lúùkù 2:41-43) Nígbà tí Jésù dàgbà, ó dara pọ̀ mọ́ àwọn Júù yòókù láti jọ́sìn Ọlọ́run nínú sínágọ́gù àdúgbò. (Lúùkù 4:14-16) Nígbà tí Jésù ń bá obìnrin kan tó ń ṣe ẹ̀sìn tó yàtọ̀ sí tirẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní: “Àwa ń jọ́sìn ohun tí àwa mọ̀.” (Jòhánù 4:22) Jésù fi hàn kedere níbí yìí pé, òun dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn àwọn Júù.

Nígbà tó yá, Jésù sọ pé, nítorí pé orílẹ̀-èdè àwọn Júù kọ òun sílẹ̀, Ọlọ́run máa kọ ìjọsìn wọn tó ti di ìdàkudà sílẹ̀. (Mátíù 23:33–24:2) Àmọ́, ó sọ pé ẹni tó fẹ́ sin Ọlọ́run lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà ní láti dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kan. Ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ọmọ ẹ̀yìn Kristi kan tí kò dara pọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ kò lè máa fi irú ìfẹ́ yìí hàn sí wọn. Kódà, kedere ni Jésù pàápàá ṣàlàyé pé, ọ̀nà ìsìn méjì péré ló wà. Ó ṣàlàyé pé ọ̀nà kan jẹ́ “fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò,” èyí “tí ó lọ sínú ìparun.” Àmọ́, ó sọ nípa ọ̀nà kejì, ó ní: “Tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.”—Mátíù 7:13, 14.

Nítorí náà, ó ṣe kedere pé, kì í ṣe ẹ̀sìn èyíkéyìí la lè ṣe. Bíbélì kìlọ̀ pé ká má ṣe dara pọ̀ mọ́ “àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún sọ pé, kí á “yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:5) Àmọ́ ṣá o, a ó jàǹfààní tó pọ̀ tá a bá mọ ọ̀nà tó lọ sí ìyè tá a sì dara pọ̀ mọ́ àwọn tó wà lójú ọ̀nà náà. A ó rí ìṣírí àti ìtìlẹ́yìn gbà nísinsìnyí, a ó sì ní ìrètí tó dájú pé ọjọ́ ọ̀la á dára.—Hébérù 10:24, 25.

Báwo lo ṣe lè mọ ẹ̀sìn tó ń tọ ọ̀nà tóóró náà? O ò ṣe ṣàgbéyẹ̀wò ìdáhùn Bíbélì gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní orí 15 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? a Ìwé yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́ nípa ẹ̀sìn tó yẹ kó o dara pọ̀ mọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.