Adẹ́tẹ̀ Kan Rí Ìwòsàn Gbà!
Abala Àwọn Ọ̀dọ́
Adẹ́tẹ̀ Kan Rí Ìwòsàn Gbà!
Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Náámánì, Èlíṣà àti ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan tí a kò dárúkọ rẹ̀
Àkópọ̀: Náámánì tó jẹ́ olórí ọmọ ogun Síríà tí àìsàn burúkú kan ń ṣe rí ìwòsàn gbà lẹ́yìn tí ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan sọ pé kó lọ rí Èlíṣà.
1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA 2 ÀWỌN ỌBA 5:1-19.
Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára ọmọdébìnrin tí wọ́n mú kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run?
․․․․․
Ìjákulẹ̀ wo lo kíyè sí pé Náámánì ní, ìyẹn ọkùnrin alágbára tó ní àìsàn burúkú lára?
․․․․․
Ìṣarasíhùwà wo lo kíyè sí nínú ìjíròrò tó wáyé láàárín Náámánì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 11 sí 13 ṣe sọ?
․․․․․
Ìyípadà wo lo kíyè sí pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í wáyé nínú ìwà Náámánì gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 15 ṣe sọ?
․․․․․
2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.
Àwọn nǹkan wo ló ṣeé ṣe kó mú kí Náámánì máa gbéra ga? (Ka ẹsẹ 1.)
․․․․․
Lo àwọn ìwé ìwádìí tó o mọ̀, ṣèwádìí nípa àrùn ẹ̀tẹ̀ lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. a (Bí àpẹẹrẹ, báwo ni àrùn náà ṣe burú tó? Ṣé ó lè ran èèyàn? Báwo ni wọ́n ṣe ń tọ́jú rẹ̀?)
․․․․․
Ipa wo lo rò pé ó ṣeé ṣe kí ìwòsàn tí Náámánì rí gbà ní lórí ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì náà?
․․․․․
Ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe kí èsì Èlíṣà gbà jẹ́ ìdánwò fún Náámánì? (Ka ẹsẹ 10.)
․․․․․
3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .
Ewu tó wà nínú kéèyàn máa gbéra ga.
․․․․․
Fífi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́.
․․․․․
Agbára Jèhófà láti woni sàn.
․․․․․
4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?
․․․․․
KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I NÍPA BÍBÉLÌ, LÓRÍ ÌKÀNNÌ WA www.watchtower.org ÀTI www.pr418.com
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àrùn tá à ń pè ní àrùn Hansen lónìí wà lára àrùn ẹ̀tẹ̀ ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì.