Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

KÍ LÓ mú kí ọmọ ogun alátakò kan tó tún jẹ́ olè yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà? Kí ló mú kí gbajúmọ̀ oníjà kọnfú kan yí ohun tó ń lépa nígbèésí ayé rẹ̀ pa dà? Báwo ni akitiyan tí bàbá kan ṣe lórí ọmọkùnrin rẹ̀ ṣe mú èrè wá? Ka àwọn ìtàn yìí láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yẹn.

“Láìka ìgbésí ayé tí kò dára tí mo ti gbé sẹ́yìn sí, mò ń láyọ̀ báyìí.”​—GARRY P. AMBROCIO

ỌJỌ́ ORÍ: 47

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: PHILIPPINES

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ỌMỌ OGUN ALÁTAKÒ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Vintar ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Inú àfonífojì tó fẹ̀ gan-an là ń gbé, àwọn òkè ńlá tí ewé bò, odò tó mọ́ àti atẹ́gùn atura sì wà láyìíká wa. Àmọ́, láìka bí àyíká yìí ṣe tura tó, ìgbésí ayé kò rọrùn rárá. Àwọn èèyàn máa ń jí ohun ọ̀sìn wa, wọ́n sì máa ń fọ́lé wa láti jà wá lólè.

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún, èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń mutí gan-an, mo máa ń mu sìgá, mo sì tún ń jalè kí n lè rówó ra àwọn nǹkan yẹn. Mo tiẹ̀ jí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ìyá mi àgbà pàápàá. Àwọn sójà fura sí mi pé mo wà lára àwọn ọmọ ogun alátakò tí wọ́n ń pè ní New People’s Army, wọ́n sì máa ń lù mí nílùkulù lọ́pọ̀ ìgbà. Nítorí èyí, mo pinnu láti di ara ọmọ ogun alátakò. Ọdún márùn-ún gbáko ni mo fi gbé lórí àwọn òkè ńlá pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun alátakò náà. Ìgbésí ayé le gan-an. Ojoojúmọ́ la máa ń wà lórí ìrìn, tí a ó máa sá fún àwọn sójà. Nígbà tó yá, ó sú mi láti máa fara pa mọ́ sáàárín àwọn òkè ńlá, nítorí náà, mo jọ̀wọ́ ara mi fún gómìnà tó ń ṣàkóso ẹkùn Ilocos Norte. Ọkùnrin yìí bójú tó mi dáadáa, ó tiẹ̀ ràn mí lọ́wọ́ láti wá iṣẹ́ tó dáa. Àmọ́, mi ò jáwọ́ nínú ìwàkiwà tí mò ń hù tẹ́lẹ̀, mò ń ja àwọn èèyàn lólè nínú ilé wọn, mo sì máa ń ṣẹ̀rù ba àwọn èèyàn.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Obìnrin kan wà ní ibi iṣẹ́ mi, Loida ni orúkọ rẹ̀, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Obìnrin yìí ló jẹ́ kí n mọ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jovencio, ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ kò rọrùn fún mi láti jáwọ́ nínú ìgbésí ayé tí mò ń gbé tẹ́lẹ̀. Mo máa ń mu sìgá kí Jovencio tó dé láti kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì tún ń lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan tí kò bófin mu. Nígbà tó yá, àwọn ọlọ́pàá mú mi níbi tí mo ti ń rú òfin, oṣù mọ́kànlá gbáko ni mo sì lò lẹ́wọ̀n. Láàárín àkókò yìí, mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo bẹ̀ ẹ́ gan-an pé kó ràn mí lọ́wọ́. Mo tọrọ ìdáríjì, mo sì bẹ̀bẹ̀ pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí mi, kó sì fi fún mi lókun.

Nígbà tó yá, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá wò mí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó mú Bíbélì wá fún mi. Mo kà á, mo sì rí i pé Jèhófà jẹ́ aláàánú àti onífẹ̀ẹ́, ó sì ṣe tán láti dárí ìṣìnà jini. Mo wá rí i pé Jèhófà ti fi àánú hàn sí mi àti pé ó ti fún mi láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀. Mo bẹ̀ ẹ́ pé kó fún mi lókun láti borí ìwàkiwà tó ti mọ́ mi lára. Ohun tí mo kà nínú Òwe 27:11 wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Lójú mi, ńṣe ló dà bíi pé èmi ni Jèhófà ń bá sọ̀rọ̀ ní tààràtà nínú ẹsẹ yìí. Ó ní: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.”

Nígbà tí mo jáde lẹ́wọ̀n, mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi pa dà lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé wọn, mo sì ń fi ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé mi. Nígbà tó yá pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún mi láti jáwọ́ nínú ìwàkiwà tó ti mọ́ mi lára. Lẹ́yìn náà, mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Láìka ìgbésí ayé tí kò dára tí mo ti gbé sẹ́yìn sí, mò ń láyọ̀ báyìí. Bo tilẹ̀ jẹ́ pé mo fi ara mi fún ìwàkiwà, àmọ́ ní báyìí, mo ti di ẹ̀dá tuntun. (Kólósè 3:9, 10) Lónìí, àǹfààní ló jẹ́ fún mi láti di ọ̀kan lára àwọn èèyàn Jèhófà tí wọ́n mọ́ tónítóní, mo tún láǹfààní láti máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè.

“Mo fẹ́ ṣojú fún orílẹ̀-èdè Brazil.”—JULIANA APARECIDA SANTANA ESCUDEIRO

ỌJỌ́ ORÍ: 31

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: BRAZIL

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ONÍJÀ KỌNFÚ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Londrina ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní ìlú yìí jẹ́ tálákà, síbẹ̀ àgbègbè yìí mọ́ tónítóní, kò sì sí wàhálà níbẹ̀. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin rọ̀ mí pé kí n dara pọ̀ mọ́ òun láti máa kọ́ ìjà kọnfú èyí tí wọ́n ń pè ní tae kwon do, èyí to túmọ̀ sí “àwọn tó máa ń fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ jà.” Dádì mi kò fara mọ́ eré ìdárayá yìí, àmọ́ nígbà tó yá, ó wá fara mọ́ ọn.

Mo gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ gan-an, mo sì borí nínú ìjà kọnfú tá a jà ní ìpínlẹ̀ Parana. Nígbà tó yá, mo borí nínú àwọn ìdíje yìí ní orílẹ̀-èdè wa, nígbà to sì di ọdún 1993, wọ́n kéde pé èmi ni ọ̀gá oníjà kọnfú ní orílẹ̀-èdè Brazil. Mo fẹ́ láti bá àwọn oníjà kọnfú láti orílẹ̀-èdè míì jà. Àmọ́, tálákà làwọn ará ilé mi, wọn ò sì lówó tí wọ́n lè san fún ìrìn àjò mi lọ sí orílẹ̀-èdè míì.

Mo ní ìrètí pé wọ́n máa fi ìjà kọnfú sára ìdíje Òlíńpíìkì, ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn. Mo fẹ́ ṣojú fún orílẹ̀-èdè Brazil nínú Ìdíje Òlíńpíìkì, nítorí náà, mo gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ gan-an, mo sì tún rí àwọn onígbọ̀wọ́ tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti lọ díje ní ilẹ̀ Faransé, Vietnam, South Korea àti Japan, mo tún lọ sí Ìdíje tó wáyé ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù. Ohun míì tí mo tún ń lépa ni láti kópa nínú Ìdíje Pan America, mo sì ṣe dáadáa débi tí wọ́n fi yàn mí láti wà lára àwọn mẹ́ta tó máa kópa nínú ìdíje yìí ní ìlú Santo Domingo, ní orílẹ̀-èdè Dominican Republic, lọ́dún 2003.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Lọ́dún 2001, èmi àti ọ̀rẹ́kùnrin mi pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mi ò kọ́kọ́ kọbi ara sí i. Gbogbo ìgbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ló máa ń rẹ̀ mí jù láti pọkàn pọ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo sì máa ń sùn lọ. Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, ohun tí mò ń kọ́ wọ̀ mí lọ́kàn, èyí sì fara hàn nínú ìdíje ńlá kan tí mo fẹ́ lọ.

Nítorí pé mo wà lára àwọn tó máa lọ sí Ìdíje Pan America, àwọn olùkọ́ni níjà kọnfú ṣètò pé kí n lọ́wọ́ nínú àwọn ìdíje onípele àkọ́kọ́. Nígbà tó kàn mí láti jà, ńṣe ni mo kàn dúró gbagidi síbi tá a ti máa ń jà, mi ò lè ṣe nǹkan kan. Ńṣe ló sọ sí mi lọ́kàn pé kò yẹ kí Kristẹni bá èèyàn jà, àní nínú eré ìdárayá pàápàá! Àṣẹ tí Bíbélì pa pé, “nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ” sọ sí mi lọ́kàn. (Mátíù 19:19) Lọ́gán, mo kúrò lágbo ìjà náà, mi ò sì kábàámọ̀ ohun tí mo ṣe. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe ń wò mí.

Nígbà tí mo délé, mo jókòó, mo sì ronú lórí ohun tí mo máa fi ìgbésí ayé mi ṣe. Mo mú ìwé pẹlẹbẹ kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, ìwé náà sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa. Nínú ìwé náà, mo rí i tí wọ́n tọ́ka sí Sáàmù 11:5, èyí tó sọ nípa Jèhófà pé: “Dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” Ọ̀rọ̀ onísáàmù yìí wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, mo sì pinnu pé màá jáwọ́ nínú ìjà kọnfú.

Inú àwọn olùkọ́ tó ń kọ́ mi ní ìjà kọnfú kò dùn. Wọ́n gbìyànjú láti yí èrò mi pa dà nípa sísọ fún mi pé èmi ni ọ̀gá nínú àwọn oníjà kọnfú ní orílẹ̀-èdè wa àti pé mo ti fẹ́ dẹni tó máa lọ kópa nínú Ìdíje Òlíńpíìkì. Àmọ́ mo ti pinnu ohun tí mo fẹ́ ṣe.

Ní àkókò yìí, èmi àti ọ̀rẹ́kùnrin mi ti ṣègbéyàwó. Òun ni tiẹ̀ ti ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí jáde lọ wàásù. Inú rẹ̀ máa ń dùn gan-an tó bá pa dà dé láti ibi ìwàásù, ó sì máa ń sọ fún mi bó ṣe bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Mo mọ̀ pé tí èmi náà bá fẹ́ nírú àǹfààní yìí, mo ní láti yí ìgbésí ayé mi pa dà. Mo kọ̀wé fi ẹ̀sìn tí mò ń ṣe tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, nígbà tó sì yá, mo kúnjú ìwọ̀n láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì ṣe ìrìbọmi.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Èmi àti ọkọ mi láyọ̀ gan-an, àárín wa sì gún nítorí pé à ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbéyàwó wa. Inú mi ń dùn láti máa ṣètìlẹ́yìn fún ọkọ mi bó ṣe ń ṣèrànwọ́ láti bójú tó ìjọ tí à ń dara pọ̀ mọ́. Mi ò bá ti sapá láti gba àmì ẹ̀yẹ góòlù ní ìdíje Òlíńpíìkì, tí màá sì wá di olókìkí. Àmọ́ mo mọ̀ pé kò sí nǹkan tí ayé aláìṣòótọ́ yìí lè fúnni tó lè dà bí àǹfààní sísin Jèhófà Ọlọ́run.

“Bàbá mi kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi sú òun.”—INGO ZIMMERMANN

ỌJỌ́ ORÍ: 44

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: JÁMÁNÌ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: Ẹ̀ṢỌ́ ILÉ IJÓ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Àwọn òbí tó ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló bí mi, ìlú Gelsenkirchen tí wọ́n ti máa ń wa kùsà ni wọ́n bí mi sí. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni bàbá mi. Àmọ́ màmá mi ta kò ó bó ṣe ń fi ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn rẹ̀ kọ́ èmi, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi méjì tó jẹ́ obìnrin. Wákàtí mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni bàbá mi fi máa ń fi ọkọ akẹ́rù ṣiṣẹ́ lójúmọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé láti aago méjì tàbí mẹ́ta òru ló ti máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Síbẹ̀, gbogbo ìgbà ló máa ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wa. Àmọ́, mi ò ka gbogbo ohun tó ń ṣe sí.

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, àwọn ìpàdé tó máa ń mú mi lọ sú mi, mo sì yarí mọ́ ọn lọ́wọ́. Ọdún kan lẹ́yìn náà, mo dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń kan ẹ̀ṣẹ́. Lọ́dún méjì tó tẹ̀ lé e, àwọn ìwà tí mò ń hù sọ bàbá mi di arúgbó ọ̀sán gangan. Nígbà tí mo sì di ọmọ ọdún méjìdínlógún, mo kúrò nílé.

Mo fẹ́ràn eré ìdárayá gan-an, nítorí náà, ìgbà mẹ́fà ni mo máa ń lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láàárín ọ̀sẹ̀, lákọ̀ọ́kọ́ lórí ẹ̀ṣẹ́ kíkàn àti lẹ́yìn náà, lórí gbígbé irin wíwúwo. Tó bá sì di òpin ọ̀sẹ̀, èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi sábà máa ń lọ sí ilé ijó. Lọ́jọ́ kan, èmi àti òǹwòran kan tó jẹ́ oníjàgídíjàgan jọ jà, àmọ́ ọwọ́ mi le ju tirẹ̀ lọ. Àṣé ẹni tó ni ilé ijó náà ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, kò sì pẹ́ tó fi ni kí n wá máa bá òun ṣọ́ ilé ijó náà. Owó tó lóun máa san tẹ́ mi lọ́rùn, nítorí náà mo gbà.

Ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, mo máa ń dúró sẹ́nu ọnà ilé ijó náà, tí màá sì máa pinnu ẹni tó yẹ kó wọlé àti ẹni tí kò yẹ kó wọlé. Àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ló máa ń wá sí ilé ijó yìí, nítorí náà ọwọ́ mi máa ń dí. Àwọn èèyàn sábà máa ń jà níbẹ̀. Àwọn èèyàn máa ń fi ìbọn àti àfọ́kù ìgò halẹ̀ mọ́ mi. Àwọn kan tí mi ò jẹ́ kí wọ́n wọlé tàbí tí mo lé síta máa ń dúró dè mí níta láti gbẹ̀san. Ọmọ ogún ọdún ni mí nígbà yẹn, èrò mi sì ni pé kò sọ́wọ́ ẹni tó lè ká mi. Òótọ́ ni pé apá kò ká mi, torí pé mo jẹ́ oníjàgídíjàgan, agbéraga, mò ń lé nǹkan ńlá, mo sì ya alágídí.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Bàbá mi kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi sú òun. Ó ṣètò láti máa fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! a ránṣẹ́ sí mi níbi tí mò ń gbé. Àwọn ìwé náà pọ̀ nínú yàrá mi, mi ò sì kà á. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, mo ka àwọn kan lára wọn. Mo ka àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa bí ètò ìṣèlú, ọrọ̀ ajé àti ẹ̀sìn tó wà báyìí ṣe máa dópin, èyí sì mú kí n pe ẹ̀gbọ́n mi obìnrin. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni òun àti ọkọ rẹ̀. Wọ́n béèrè bóyá màá fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Ìlànà tó wà nínú ìwé Gálátíà 6:7 mú kí n yí ìgbésí ayé mi pa dà. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ pé, ohunkóhun ti mo bá ṣe, tí mo bá sọ tàbí èyí tí mo pinnu lónìí máa nípa lórí ìgbésí ayé mi lọ́la. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 1:18 tún fún mi ní ìṣírí tó pọ̀, ó ní: “‘Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ sì jẹ́ kí a mú àwọn ọ̀ràn tọ́ láàárín wa,’ ni Jèhófà wí. ‘Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, a ó sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì.’” Ẹsẹ Bíbélì yìí ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti má ṣe rò pé mi ò wúlò tàbí pé Jèhófà kò ní tẹ́wọ́ gbà mí.

Láàárín oṣù mẹ́fà, mo ti ṣe àwọn ìyípadà tó kàmàmà nínú ìgbésí ayé mi, àmọ́ kì í ṣe pẹ̀lú ojú bọ̀rọ̀. Mo ní láti kúrò ní àgbègbè oníwà ìbàjẹ́, mo sì ní láti fi àwọn ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ tí mò ń kó sílẹ̀. Nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ mi pé mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì ń sọ ohun tí mo kọ́ fún wọn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fún mi, wọ́n sì ń pè mí ní àlùfáà. Ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ràn mí lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ míì tó dáa.

Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ẹ̀gbọ́n mi obìnrin àti ọkọ rẹ̀ ń lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgbọ̀n kìlómítà ni sí ilé mi. Gbọ̀ngàn Ìjọba kan wà nítòsí ilé mi tí mo lè lọ, àmọ́ ẹ̀rù ń bà mi nítorí mi ò fẹ́ pàdé àwọn tó ti mọ̀ mí láti kékeré. Àyà mi tún ń já láti máa wàásù láti ilé dé ilé ní àdúgbò tí mò ń gbé. Tí n bá lọ pàdé àwọn kan lára àwọn tí mo le jáde nínú ilé ijó lẹ́nu àìpẹ́ yìí ńkọ́ tàbí àwọn kan tí mo ti fún ní oògùn olóró? Àmọ́, mo lo ẹ̀kọ́ tí mo rí kọ́ nínú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo gbà nípa eré ìmárale, ẹ̀kọ́ náà ni pé, ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó bá le gan-an ló dára jù lọ. Nítorí náà, nígbà tí mo kúnjú ìwọ̀n láti wàásù, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi gbogbo okun àti agbára mi wàásù.

Ohun míì wà tí mo ní láti borí, ohun náà ni pé mi ò nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ mo mọ̀ pé tí mo bá fẹ́ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, mo ní láti sakun gan-an kí n lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ láti mọ òtítọ́. Mo wá rí i pé bí ẹni tó ń gbé irin wíwúwo lọ̀rọ̀ náà rí, èèyàn ní láti sapá kó bàa lè lókun.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Mo ṣì wà láàyè! Mo ṣì ní láti máa ṣàkóso ara mi kí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tí mo ní máa bàa borí mi. Àmọ́ nísinsìnyí, mò ń gbádùn ìdílé aláyọ̀ pẹ̀lú ìyàwó mi tó ní ìwà tó dáa èyí tó yẹ Kristẹni. Láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tí mo lè fọkàn tán. Ọdún márùn-ún sẹ́yìn ni bàbá mi kú, àmọ́ kó tó kú, ó láyọ̀ pé ọmọkùnrin òun ti pa dà wá.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.