Fọwọ́ Pàtàkì Mú Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ọ̀nà Karùn-ún
Fọwọ́ Pàtàkì Mú Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run
KÍ NI BÍBÉLÌ FI KỌ́NI? “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—Mátíù 5:3.
KÍ NI ÌṢÒRO NÁÀ? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀sìn ló wà, ọ̀pọ̀ lára wọn sì ń kọ́ni ní ọ̀kan-kò-jọ̀kan ọ̀nà téèyàn lè gbà jọ́sìn Ọlọ́run. Báwo lo ṣe lè mọ ẹ̀sìn tó ń kọ́ni ní òtítọ́, tí Ọlọ́run sì tẹ́wọ́ gbà? Àwọn gbajúgbajà òǹkọ̀wé kan sọ pé kò bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run wà, kò sì bọ́gbọ́n mu láti máa jọ́sìn rẹ̀, kódà wọ́n ní ó ń pani lára. Ìwé ìròyìn Maclean ṣàkópọ̀ èrò gbajúmọ̀ kan tí kò gbà pé Ọlọ́run wà, ó ní: “Èrò àwọn Kristẹni pé, ohun kan wà tó kọjá òye èèyàn àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, . . . sọ ìgbésí ayé kan ṣoṣo wa yìí di aláìwúlò, èyí ló sì ń mú ká máa hùwà ipá.”
KÍ LO LÈ ṢE? Ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà. (Róòmù 1:20; Hébérù 3:4) Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni dí ẹ lọ́wọ́ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì, irú bíi: Kí nìdí tí a fi wà láàyè? Ṣé èèyàn máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú. Kí nìdí tí ìjìyà fi pọ̀ gan-an? Kí ni Ọlọ́run ń fẹ́ kí n ṣe? Rírí ìdáhùn tó yẹ sí àwọn ìbéèrè yẹn ṣe pàtàkì kéèyàn tó lè ní ìtẹ́lọ́rùn títí ayé.
Àmọ́, kò ní dáa kó o kàn gba gbogbo ohun táwọn èèyàn bá sọ. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún ẹ pé kó o lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ láti mọ ohun tó ṣètẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run. (Róòmù 12:1, 2) Wàá rí èrè gbà fún gbogbo ìsapá rẹ. Tó o bá lo àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́, tó o sì ń fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò, o ò ní kó sínú ìṣòro, àníyàn rẹ á dín kù, wàá sì túbọ̀ gbádùn ìgbésí ayé rẹ. Àwọn nǹkan yìí kì í ṣe ohun tí kò lè ṣeé ṣe. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. Bí àpẹẹrẹ, kà nípa ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn nínú ìwé ìròyìn yìí lójú ìwé 18 sí 21.
Bó o ti ń jàǹfààní látinú fífi ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì sílò, ìfọkànsìn rẹ sí Ọlọ́run á máa lágbára sí i. O ò ṣe jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, èrò rẹ á dà bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, àní fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi.”—1 Tímótì 6:6.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Wádìí ohun tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run