Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Ṣe Máa Fi Ara Rẹ Wé Àwọn Ẹlòmíì

Má Ṣe Máa Fi Ara Rẹ Wé Àwọn Ẹlòmíì

Ọ̀nà Kejì

Má Ṣe Máa Fi Ara Rẹ Wé Àwọn Ẹlòmíì

KÍ NI BÍBÉLÌ FI KỌ́NI? “Ṣe iṣẹ́ rẹ dáadáa, nígbà náà ìwọ yóò ní ohun kan tí wàá máa fi yangàn. Àmọ́ má ṣe fi ara rẹ wé àwọn ẹlòmíì.”—Gálátíà 6:4, Bíbélì Contemporary English Version.

KÍ NI ÌṢÒRO NÁÀ? A máa ń fẹ́ fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì, nígbà míì, a máa ń wo ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwa àtàwọn tí kò ní ohun ìní tó wa, lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń fara wa wé àwọn tó lágbára jù wá lọ, àwọn tó lọ́rọ̀ jù wá lọ, tàbí àwọn tó ní ẹ̀bùn jù wá lọ. Ohun yòówù kó fà á, ìyọrísí rẹ̀ kì í dáa. Èrò tí kò tọ̀nà tá a máa ń ní ni pé ohun tí ẹnì kan ní tàbí ohun tó lè ṣe ló máa ń fi hàn bí ẹni náà ti ṣe pàtàkì tó. A tún lè dá ẹ̀mí owú àti ẹ̀mí ìdíje sílẹ̀.—Oníwàásù 4:4.

KÍ LO LÈ ṢE? Sapá láti máa fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wò ẹ́ wo ara rẹ. Jẹ́ kí èrò Ọlọ́run máa darí ojú tó o fi ń wo bó o ti ṣe pàtàkì tó. Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:7) Jèhófà a kì í fi ẹ́ wé àwọn ẹlòmíì kó lè mọ bó o ti ṣe pàtàkì tó, àmọ́, ṣíṣàyẹ̀wò ohun tó wà ní ọkàn rẹ, èrò rẹ àti bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára rẹ ló máa fi ń mọ bó o ti ṣe pàtàkì tó. (Hébérù 4:12, 13) Jèhófà lóye ibi tí agbára rẹ mọ, ó sì ń fẹ́ kí ìwọ náà mọ ìwọ̀n ara rẹ. Tó o bá ń fi ara rẹ wé àwọn ẹlòmíì láti mọ bó o ti ṣe pàtàkì tó, wàá di agbéraga tàbí ẹni tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn. Nítorí náà, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ á jẹ́ kó o gbà pé kì í ṣe gbogbo nǹkan lo lè tayọ nínú rẹ̀.—Òwe 11:2.

Kí ni nǹkan tó o gbọ́dọ̀ ṣe kó o bàa lè níye lórí lójú Ọlọ́run? Ọlọ́run mí sí wòlíì Míkà láti sọ pé: “Ó ti sọ fún ọ, ìwọ ará ayé, ohun tí ó dára. Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?” (Míkà 6:8) Tó o bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn, Ọlọ́run yóò bójú tó ẹ. (1 Pétérù 5:6, 7) Kò sí ọ̀nà míì téèyàn lè gbà rí ìtẹ́lọ́rùn tó ju èyí lọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ohun tó wà lọ́kàn wa ni Jèhófà fi ń díwọ̀n bá a ti ṣe pàtàkì tó