Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn, Má Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Owó àti Ohun Ìní
Ọ̀nà Kìíní
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn, Má Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Owó àti Ohun Ìní
KÍ NI BÍBÉLÌ FI KỌ́NI? “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.”—1 Tímótì 6:10.
KÍ NI ÌṢÒRO NÁÀ? Àwọn tó ń polówó ọjà máa ń fúngun mọ́ wa kí ohun tá a ní má bàa tẹ́ wa lọ́rùn. Wọ́n ń fẹ́ ká ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó ká lè rí owó ná sórí àwọn nǹkan tuntun, àwọn nǹkan tó túbọ̀ dára, àtàwọn nǹkan ńláńlá. Ó rọrùn féèyàn láti nífẹ̀ẹ́ owó, téèyàn á sì máa wò ó pé owó ló ṣe pàtàkì jù. Àmọ́, Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.”—Oníwàásù 5:10.
KÍ LO LÈ ṢE? Fara wé Jésù, kó o sì kọ́ láti fẹ́ràn àwọn èèyàn ju ohun ìní lọ. Jésù múra tán láti yááfì gbogbo ohun tó ní, títí kan ìwàláàyè rẹ̀ pàápàá, nítorí ìfẹ́ tó ní fún àwọn èèyàn. (Jòhánù 15:13) Ó sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Tá a bá sọ ọ́ dàṣà láti máa lo àkókò àti okun wa fún àwọn ẹlòmíì, àwọn náà á ṣe bẹ́ẹ̀ fún wa. Jésù sọ pé: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín.” (Lúùkù 6:38) Àwọn tó ń lépa owó àti ohun ìní máa ń fa ọ̀pọ̀ ìrora àti ìpọ́njú fún ara wọn. (1 Tímótì 6:9, 10) Àmọ́, ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn máa ń wá látinú nínífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, kí àwọn náà sì nífẹ̀ẹ́ wa.
O ò ṣe ṣàgbéyẹ̀wò ìgbésí ayé rẹ bóyá o lè jẹ́ kí àwọn ohun ìní tara díẹ̀ tẹ́ ọ lọ́rùn. Ṣé o lè dín àwọn ohun ìní tó o ní kù tàbí kó o dín èyí tó o fẹ́ rà kù? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé wàá ní àkókò àti okun tó pọ̀ sí i láti ṣe àwọn ohun tó túbọ̀ ṣe pàtàkì nígbèésí ayé, ìyẹn ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ àti sísin Ọlọ́run, ẹni tó fún ọ ní ohun gbogbo tó o ní.—Mátíù 6:24; Ìṣe 17:28.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
“Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín”