Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O mọ̀?

Ǹjẹ́ O mọ̀?

Ǹjẹ́ O mọ̀?

Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé òun ń gbé “àwọn àpá àmì ti ẹrú Jésù” kiri lára òun?—Gálátíà 6:17.

Oríṣiríṣi ìtumọ̀ lọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí lè gbé wá sọ́kàn àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Bí àpẹẹrẹ, ní ayé ìgbàanì, irin gbígbóná ni wọ́n máa fi ń sàmì sára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n kó bọ̀ lójú ogun, àwọn tó ń ja tẹ́ńpìlì lólè àtàwọn ẹrú tó sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá wọn kí wọ́n lè dá wọn mọ̀. Ohun àbùkù ló jẹ́ tí wọ́n bá fi irú àmì yìí sí èèyàn lára.

Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àmì máa ń jẹ́ ohun àbùkù. Láyé ìgbàanì, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lo àmì káwọn èèyàn lè mọ ẹ̀yà tí wọ́n ti wá tàbí ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ìwé tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Bíbélì, ìyẹn Theological Dictionary of the New Testament, sọ pé, “àwọn ará Síríà máa ń sàmì sí ọrùn ọwọ́ wọn tàbí ọrùn wọn láti fi hàn pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún ọlọ́run Hadad àti Atargatis . . . Àmì ewéko ivy ni wọ́n máa ń ṣe sára àwọn tó ń jọ́sìn ọlọ́run Dionysus.”

Ọ̀pọ̀ àwọn alálàyé lóde òní ló parí èrò sí pé àwọn àpá tí wọ́n dá sí Pọ́ọ̀lù lára láwọn ìgbà tí wọ́n lù ú lákòókò tó ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ló ní lọ́kàn. (2 Kọ́ríńtì 11:23-27) Àmọ́, ó lè jẹ́ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ni pé ọ̀nà tí òun gbà gbé ìgbésí ayé òun ló fi òun hàn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni,kì í ṣe àmì tó wà lára òun.

Ṣé àwọn ìlú ààbò lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ di ibi ààbò fún àwọn ọ̀daràn?

Ní orílẹ̀-èdè àwọn kèfèrí láyé àtijọ́, ọ̀pọ̀ tẹ́ńpìlì ló di ibi ààbò fún àwọn tó sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá wọn àti fún àwọn ọ̀daràn. Bákan náà, ní sànmánì ìgbà ọ̀làjú ti àwọn Kristẹni, àwọn ọ̀daràn máa ń lọ fara pa mọ́ sínú àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn ilé tí wọ́n kọ́ mọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì. Àmọ́, àwọn òfin tó wà fún ìlú ààbò ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kò fàyè gba kí àwọn ìlú yìí di ibi tí àwọn ọ̀daràn máa ń fara pa mọ́ sí.

Ẹni tó pa èèyàn láìmọ̀ nìkan ni Òfin Mósè sọ pé ó lè rí ààbò ní àwọn ìlú ààbò. (Diutarónómì 19:4, 5) Ẹni yìí lè sá lọ sí ìlú ààbò tó wà nítòsí rẹ̀, kí ọkùnrin kan tó jẹ́ èèyàn ẹni tó pa náà má bàa gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni náà lára rẹ̀. Lẹ́yìn tó bá ti sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe wáyé fún àwọn àgbààgbà ìlú náà, wọ́n á mú ẹni tó ń wá ààbò yìí lọ sí ìlú tó ń ṣàkóso ibi tó pa ẹni náà sí, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti máa ṣèdájọ́ rẹ̀. Ẹni tó ń wá ààbò yìí láǹfààní láti fi ẹ̀rí hàn níbẹ̀ pé òun kò jẹ̀bi. Àwọn àgbààgbà náà á wá ṣàyẹ̀wò bí àárín ẹni tó ń wá ààbò náà àti ẹni tó pa ṣe rí láti mọ̀ bóyá ó ti ní ẹni náà sínú tẹ́lẹ̀.—Númérì 35:20-24; Diutarónómì 19:6, 7; Jóṣúà 20:4, 5.

Tí ẹni tó ń wá ààbò yìí kò bá jẹ̀bi, wọ́n á dá a pa dà sí ìlú ààbò, inú ìlú náà lá sì máa gbé. Àwọn ìlú náà kì í ṣe ẹ̀wọ̀n. Ẹni náà á máa ṣiṣẹ́, á sì wúlò fún àwọn ará ìlú. Àmọ́ lẹ́yìn tí àlùfáà àgbà bá ti kú, àwọn tó ń wá ààbò lè kúrò ní ìlú ààbò láìsí ewu.—Númérì 35:6, 25-28.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÀWỌN ÌLÚ ÀÀBÒ

1 KÉDÉṢÌ

2 GÓLÁNÌ

3 RÁMÓTÌ-GÍLÍÁDÌ

4 ṢÉKÉMÙ

5 BÉSÉRÌ

6 HÉBÚRÓNÌ

Odò Jọ́dánì