Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Yóò Jẹ́ Kí O Rí Òun”

“Yóò Jẹ́ Kí O Rí Òun”

Sún Mọ́ Ọlọ́run

“Yóò Jẹ́ Kí O Rí Òun”

1 KÍRÓNÍKÀ 28:9

ǸJẸ́ o mọ Ọlọ́run? Ìdáhùn ìbéèrè yìí kò rọrùn tó bó o ṣe rò. Mímọ Ọlọ́run dunjú gba pé kéèyàn mọ ohun tó fẹ́ àtàwọn ọ̀nà rẹ̀ dáadáa. A ó tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ ṣe tímọ́tímọ́, ìyẹn á sì ní ipa rere lórí ìgbésí ayé wa. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti ní irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run? Tó bá ṣeé ṣe, báwo lá ṣe lè ní in? A lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí nínú ìmọ̀ràn tí Dáfídì Ọba fún Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú 1 Kíróníkà 28:9.

Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Dáfídì ti ṣàkóso Ísírẹ́lì fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì ọdún, nǹkan sì lọ dáadáa fún orílẹ̀-èdè náà lákòókò ìṣàkóso rẹ̀. Ọ̀dọ́ ni Sólómọ́nì tó máa tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso nípò rẹ̀. (1 Kíróníkà 29:1) Ọ̀rọ̀ ìdágbére wo ni Dáfídì sọ fún ọmọkùnrin rẹ̀?

Dáfídì bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ látinú ọ̀pọ̀ ìrírí tó ní nínú sísin Ọlọ́run, ó ní: “Sólómọ́nì ọmọkùnrin mi, mọ Ọlọ́run baba rẹ.” Ohun tí Dáfídì ní lọ́kàn ju pé kéèyàn ṣáà kàn mọ Ọlọ́run. Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì ti ń jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì. Wọ́n ti parí ìdá mẹ́ta lára Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù lákòókò yẹn, kò sì sí iyè méjì pé Sólómọ́nì mọ̀ nípa ohun táwọn ìwé yìí sọ nípa Ọlọ́run. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé, ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí “mọ” lè tọ́ka sí “ẹni tá a mọ̀ dáadáa.” Bẹ́ẹ̀ ni, Dáfídì fẹ́ kí ọmọ rẹ̀ náà ní irú àjọṣe tímọ́tímọ́ tí òun pẹ̀lú Ọlọ́run ní.

Ó yẹ kí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ ní ipa tó jinlẹ̀ lórí ìgbésí ayé Sólómọ́nì. Dáfídì gba ọmọ rẹ̀ níyànjú pé: “Fi ọkàn-àyà pípé pérépéré àti ọkàn tí ó kún fún inú dídùn sin [Ọlọ́run].” a Kíyè sí i pé ohun tó kọ́kọ́ sọ ni pé, kó mọ Ọlọ́run, lẹ́yìn ìyẹn ló wá fún un ní ìmọ̀ràn pé kó sìn ín. Bẹ́ẹ̀ ni, èèyàn ní láti mọ Ọlọ́run ná kó tó lè sìn ín. Àmọ́ kò yẹ kí ó máa fi ààbọ̀ ọkàn sin Ọlọ́run tàbí kí ó máa sin Ọlọ́run pẹ̀lú ọkàn méjì. (Sáàmù 12:2; 119:113) Dáfídì gba ọmọkùnrin rẹ̀ níyànjú pé kó sin Ọlọ́run tọkàntọkàn àti tinútinú.

Kí nìdí tí Dáfídì fi rọ ọmọkùnrin rẹ̀ pé kó sin Ọlọ́run pẹ̀lú èrò tí ó tọ́? Dáfídì ṣàlàyé pé: “Nítorí gbogbo ọkàn-àyà ni Jèhófà ń wá, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú sì ni ó ń fi òye mọ̀.” Sólómọ́nì kò ní láti sin Ọlọ́run torí kó lè mú inú Dáfídì bàbá rẹ̀ dùn. Àwọn tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ni Ọlọ́run fẹ́.

Ṣé Sólómọ́nì á tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bàbá rẹ̀ tí á sì sún mọ́ Jèhófà? Ọwọ́ Sólómọ́nì nìyẹn kù sí. Dáfídì sọ fún ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “ Bí ìwọ bá wá a, yóò jẹ́ kí o rí òun; ṣùgbọ́n bí o bá fi í sílẹ̀, òun yóò ta ọ́ nù títí láé.” Kí Sólómọ́nì tó lè di olùjọsìn tó sún mọ́ Ọlọ́run, ó ní láti sapá gan-an kó bàa lè mọ Jèhófà. b

Ìmọ̀ràn bàbá sọ́mọ tí Dáfídì fún ọmọ rẹ̀ fi hàn pé Jèhófà fẹ́ ká sún mọ́ òun. Àmọ́ ká tó lè ní irú àjọṣe yìí, a ní láti “wá a,” ká kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ká bàa lè mọ̀ ọ́n dáadáa. Ìmọ̀ tá a ní nípa rẹ̀ yẹ kó mú wa sìn ín tọkàntọkàn àti tinútinú. Ohun tí Jèhófà retí láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ń sìn ín nìyẹn, òun sì ni ẹni to yẹ ká máa jọ́sìn.—Mátíù 22:37.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Báwọn Bíbélì kan ṣe túmọ̀ ẹsẹ yìí rèé: “Sìn ín tọkàntọkàn àti tinútinú.”

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tọkàntọkàn ni Sólómọ́nì fi bẹ̀rẹ̀ sí í sin Ọlọ́run, àmọ́, ó ṣeni láàánú pé kò jẹ́ olóòótọ́ títí dópin.—1 Àwọn Ọba 11:4.