Ìran Nípa Ọ̀run
Ìran Nípa Ọ̀run
BÓ O tẹjú mọ́ ojú ọ̀run jù bẹ́ẹ̀ lọ, o ò lè rí ẹni ẹ̀mí kankan. Bó o tẹ́tí sílẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, o kò lè gbọ́ ohùn kankan. Síbẹ̀, ó yẹ kó o gbà pé àwọn ẹni ẹ̀mí wà. Àwọn áńgẹ́lì lóye gan-an, wọ́n sì lágbára gan-an, wọ́n ní orúkọ àtàwọn ànímọ́ tó yàtọ̀ síra. Àwọn kan ń wá ire wa, àwọn míì sì fẹ́ láti ṣe wá ní jàǹbá. Gbogbo wọn ló ní ohun kan lọ́kàn nípa wa.
Ọlọ́run tòótọ́ pàápàá jẹ́ ẹ̀mí. (Jòhánù 4:24) Ó ní orúkọ àrà ọ̀tọ̀ èyí tó mú kó yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ ọlọ́run èké. Orúkọ rẹ̀ ni Jèhófà. (Sáàmù 83:18) Onísáàmù kan kọ̀wé pé: “Nítorí pé Jèhófà tóbi lọ́lá, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi. Ó jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ. Nítorí gbogbo ọlọ́run àwọn ènìyàn jẹ́ àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, òun ni ó ṣe ọ̀run pàápàá. Iyì àti ọlá ńlá ń bẹ níwájú rẹ̀; okun àti ẹwà ń bẹ nínú ibùjọsìn rẹ̀.”—Sáàmù 96:4-6.
Ìran Nípa Ọlọ́run Tòótọ́
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí.” (Jòhánù 1:18) Ìrísí àti ọlá ńlá rẹ̀ kọjá òye ẹ̀dá èèyàn, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń ṣàlàyé àwọ̀ fún ẹni tí wọ́n bí ní afọ́jú. Bí olùkọ́ kan tó dáńgájíá ṣe máa ń fi àwọn ohun tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ ṣàlàyé ẹ̀kọ́ tó díjú fún wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ń fi àwọn nǹkan téèyàn lè rí ṣàlàyé àwọn nǹkan téèyàn kò lè rí. Jèhófà jẹ́ ká rí bí àgbàlá ọ̀run ṣe rí nípasẹ̀ àwọn ìran tó fi han àwọn olóòótọ́ ayé ìgbàanì, ó sì jẹ́ ká mọ bá a ṣe jẹ́ sí àwọn tó ń gbé níbẹ̀.
Bí àpẹẹrẹ, nínú ìran tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí, ó sọ pé ògo Jèhófà dà bí iná, ìmọ́lẹ̀, òkúta sàfáyà àti òṣùmàrè. Nínú ìran míì, àpọ́sítélì Jòhánù rí Jèhófà lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sọ pé “ìrísí [Ọlọ́run], sì dà bí òkúta jásípérì àti òkúta aláwọ̀ pupa tí ó ṣeyebíye,” ó tún sọ pé, “yí ká ìtẹ́ náà òṣùmàrè kan wà tí ó dà bí òkúta émírádì ní ìrísí.” Àwọn àlàyé yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ibi tí Jèhófà wà kò lẹ́gbẹ́ ó sì lẹ́wà, ó ń dán gbinrin, ó jojú ní gbèsè, ó sì jẹ́ ibi tí ó pa rọ́rọ́.—Ìṣípayá 4:2, 3; Ìsíkíẹ́lì 1:26-28.
Wòlíì Dáníẹ́lì náà rí Jèhófà nínú ìran kan, níbi tó ti rí “ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n] . . . ń dúró níwájú [Jèhófà].” (Dáníẹ́lì 7:10) Ẹ ò rí i pé àgbàyanu ni ìran yìí jẹ́! Nǹkan àgbàyanu ló jẹ́ téèyàn bá rí áńgẹ́lì kan ṣoṣo nínú ìran, àmọ́ fojú inú wo bó ṣe máa rí téèyàn bá rí ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ẹni pípé!
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ìgbà tí wọ́n mẹ́nu kan áńgẹ́lì nínú Bíbélì, àwọn kan lára wọ́n jẹ́ séráfù, àwọn kan sì jẹ́ kérúbù. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì àti Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí “áńgẹ́lì” nínú Bíbélì ní ìtumọ̀ kan ṣoṣo, ìyẹn “ìránṣẹ́.” Nítorí náà, àwọn áńgẹ́lì lè bá ara wọn sọ̀rọ̀, wọ́n sì ti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láwọn ìgbà kan sẹ́yìn. Àwọn áńgẹ́lì kì í ṣe àwọn èèyàn tó ti fi ìgbà kan rí gbé orí ilẹ̀ ayé. Jèhófà ti dá àwọn áńgẹ́lì tipẹ́tipẹ́ kó tó dá àwọn èèyàn.—Nínú ìran tí Dáníẹ́lì rí, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn áńgẹ́lì pé jọ láti ṣẹlẹ́rìí ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu kan. Dáníẹ́lì wá rí “ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn” tó ń lọ síbi ìtẹ́ Jèhófà láti gba “agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun.” (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Jésù Kristi tó ti jíǹde ni “ọmọ ènìyàn” tó wà ní ipò pàtàkì ní ọ̀run, òun ni Ọlọ́run fún ní agbára láti ṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ayé. Láìpẹ́, ìṣàkóso rẹ̀ máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn, ó sì máa fòpin sí àìsàn, ìbànújẹ́, ìnilára, ipò òṣì àti ikú pàápàá.—Dáníẹ́lì 2:44.
Kò sí àní-àní pé, gbígbé tí a gbé Jésù gorí ìtẹ́ yìí mú ayọ̀ ńlá wá fún ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tí wọ́n ń fẹ́ ire àwa èèyàn. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn áńgẹ́lì ni inú wọn dùn sí èyí.
Ọ̀tá Ọlọ́run àti Èèyàn
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn, áńgẹ́lì kan tó ń fẹ́ kí àwọn èèyàn máa jọ́sìn òun ta ko Jèhófà, ó sì sọ ara rẹ̀ di Sátánì, èyí tó túmọ̀ sí “Alátakò.” Sátánì ni olórí aṣebi, ó sì ń ta ko
Jèhófà tó jẹ́ ìfẹ́. Àwọn áńgẹ́lì míì náà dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀. Bíbélì pe àwọn áńgẹ́lì náà ní ẹ̀mí èṣù. Bíi Sátánì, àwọn ẹ̀mí èṣù náà di ọ̀tá àwọn èèyàn, wọ́n sì rorò gan-an. Àwọn ló wà nídìí ọ̀pọ̀ ìnilára, àìṣẹ̀tọ́, àìsàn, ipò òṣì àti ogun tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ oníṣọ́ọ̀ṣì kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Sátánì mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ ìwé Jóòbù inú Bíbélì jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́ àti èrò tó wà lọ́kàn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí. Ó ní: “Wàyí o, ó wá di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ wọlé láti mú ìdúró wọn níwájú Jèhófà, Sátánì pàápàá sì wọlé sáàárín wọn gan-an.” Nínú ọ̀rọ̀ tí Sátánì àti Ọlọ́run sọ lẹ́yìn náà, Sátánì fi ọ̀yájú sọ pé, nítorí ohun tí Jóòbù rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ló ṣe ń sìn ín. Kí Sátánì lè fìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí múlẹ̀, ó mú ìpọ́njú bá Jóòbù, ó pa gbogbo ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Lẹ́yìn ìyẹn, ó tún fi oówo afòòró-ẹ̀mí kọlu Jóòbù láti orí títí dé àtẹ́lẹsẹ̀. Àmọ́ gbogbo ìkọlù Sátánì láti fìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ ló já sí pàbó.—Jóòbù 1:6-19; 2:7.
Ìdí wà tí Jèhófà fi fàyè gba Sátánì fún àkókò tó gùn gan-an, àmọ́ kò ní fàyè gbà á títí láé. Láìpẹ́, Ọlọ́run máa pa Èṣù run. Ọlọ́run ti gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ lórí ọ̀ràn yìí, ìwé Ìṣípayá sì ṣàlàyé rẹ̀. Nínú ìwé ọ̀hún, wọ́n ṣí ìbòjú lójú ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan tó wáyé ní ọ̀run, èyí tó jẹ́ pé a kì bá mọ̀ nípa rẹ̀. A kà níbẹ̀ pé: “Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì [Jésù Kristi tó ti jíǹde] àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì [Sátánì] náà jagun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jagun ṣùgbọ́n kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”—Ìṣípayá 12:7-9.
Kíyè sí i pé Bíbélì sọ pé Sátánì “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” Ó ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà àti kúrò nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ èké. Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ èké bẹ́ẹ̀ ni pé ọ̀run ni gbogbo ẹni tó bá ti kú ń lọ. Oríṣiríṣi èrò làwọn èèyàn sì ní nípa èyí. Bí àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Áfíríkà àti Éṣíà, ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé tí èèyàn bá ti kú, á máa lọ gbé ní ọ̀run níbi tí àwọn alálẹ̀ ń gbé, ìyẹn àwọn èèyàn wọn tó ti kú tipẹ́. Látinú èrò pé èèyàn máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú ni ẹ̀kọ́ pọ́gátórì àti iná ọ̀run àpáàdì ti wá.
Ṣé Ọ̀run Ni Èèyàn Ń Lọ Lẹ́yìn Ikú?
Àmọ́ ṣá o, ìgbàgbọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé pé gbogbo èèyàn rere ló ń lọ sí ọ̀run ńkọ́? Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn rere kan ń lọ sí ọ̀run, àmọ́ iye wọn kéré gan-an sí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ti kú. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] èèyàn ni a máa “rà láti ilẹ̀ ayé wá,” wọ́n sì máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí “àlùfáà” àti “ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1, 3) Àwọn pẹ̀lú Jésù Kristi tó jẹ́ Ọmọ èèyàn, ló máa para pọ̀ jẹ́ ìjọba ọ̀run, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba yẹn máa pa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù run, ó sì máa sọ ayé di Párádísè. Ọ̀pọ̀ àwọn òkú ló máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú, tí wọ́n sì máa ní ìrètí láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.—Lúùkù 23:43.
Ní kúkúrú, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹni ẹ̀mí ló ń gbé ní ọ̀run. Ẹni Gíga Jù Lọ láàárín wọn ni Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ sì ń jọ́sìn rẹ̀. Àwọn áńgẹ́lì míì náà wà tí Sátánì ń darí, tí wọ́n ń ta ko Jèhófà, tí wọ́n sì ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Ní àfikún sí i, a ti “ra” tàbí yan ìwọ̀nba àwọn èèyàn kan láti ayé kí wọ́n lè lọ bójú tó àwọn ojúṣe pàtàkì kan ní ọ̀run. Pẹ̀lú èyí lọ́kàn wa, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn tá a lè bá sọ̀rọ̀ ní ọ̀run àti bá a ṣe lè bá wọn sọ̀rọ̀.