Ǹjẹ́ Ọlọ́run Bìkítà Nípa Rẹ?
Ǹjẹ́ Ọlọ́run Bìkítà Nípa Rẹ?
ǸJẸ́ o mọ̀ ọ́n lára pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ rẹ? Àbí ó máa ń ṣe ẹ́ nígbà míì bíi pé kò sí ẹni tó bìkítà nípa rẹ? Nínú ayé tí kòókòó jàn-ánjàn-án pọ̀, tó sì jẹ́ pé tara wọn nìkan làwọn èèyàn mọ̀ yìí, ó rọrùn fún ẹ láti máa rò pé, o kò já mọ́ nǹkan kan, pé àwọn èèyàn kò kà ọ́ sí. Òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa àkókò wa, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló jẹ́ pé ti ara wọn nìkan ni wọ́n gbájú mọ́, èyí mú káwọn èèyàn níbi púpọ̀ má ṣe bìkítà nípa àwọn ẹlòmíì.—2 Tímótì 3:1, 2.
Láìka ọjọ́ orí, àṣà ìbílẹ̀, èdè, tàbí ìran tí a ti wá sí, gbogbo èèyàn ló fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn, kí àwọn náà sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Àwọn ìwádìí kan fi hàn pé, Ọlọ́run ṣe iṣan tó ń bá ọpọlọ wa ṣiṣẹ́ lọ́nà tí a fi máa mọ̀ téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì ń gba tiwa rò. Lórí ọ̀ràn yìí, Jèhófà Ọlọ́run tó dá wa lóye wa ju ẹnikẹ́ni lọ, ó mọ̀ pé à ń fẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ wa, kí wọ́n sì mọyì wa. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tí Ọlọ́run bá fi dá ọ lójú pé o ṣeyebíye lójú òun? Ó dájú pé wàá mọrírì rẹ̀ ju ọ̀nà èyíkéyìí míì tí èèyàn lè gbà bìkítà nípa rẹ. Ṣé ó dá wa lójú pé Jèhófà lè nífẹ̀ẹ́ sí àwa èèyàn aláìpé? Ṣé ó bìkítà nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan wa? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ló ń mú kí ẹnì kan ṣeyebíye lójú Ọlọ́run?
Jèhófà Bìkítà Nípa Wa
Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn, onísáàmù kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run wo ẹwà ojú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀ lálẹ́, èyí sì mú kó ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ gan-an fún Ọlọ́run. Kò sí iyè méjì kankan ní ọkàn rẹ̀ pé Atóbijù ni ẹni tó dá àwọn ìràwọ̀ tí kò lóǹkà náà. Nígbà tí onísáàmù náà ronú lórí bí Jèhófà ti tóbi tó àti bí èèyàn ti kéré tó, ó sọ bí ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún wa ṣe jọ òun lójú tó, ó ní: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn, àti ọmọ ará ayé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?” (Sáàmù 8:3, 4) Ó rọrùn láti rò pé Onípò Àjùlọ yìí ti jìnnà sí wa jù tàbí pé ọwọ́ rẹ̀ ti dí jù láti gbọ́ ti àwa èèyàn aláìpé. Àmọ́, onísáàmù náà mọ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí wa kì í gùn, tí a kò sì tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, síbẹ̀ èèyàn ṣeyebíye lójú rẹ̀.
Onísáàmù míì tún fi dá wa lójú pé: “Jèhófà ní ìdùnnú sí Sáàmù 147:11) Ohun tí sáàmù méjèèjì yìí sọ wọni lọ́kàn gan-an ni. Yàtọ̀ sí pé Jèhófà ń kíyè sí àwa èèyàn, Ọlọ́run gíga lọ́lá yìí tún bìkítà nípa wa, inú rẹ̀ sì dùn sí wa.
àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, sí àwọn tí ń dúró de inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́.” (Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan tó sọ nípa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò wa yìí túbọ̀ sọ bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe jẹ́ òótọ́ tó. Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ nípasẹ̀ wòlíì Hágáì pé, a ó wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Kí ló sì máa jẹ́ àbájáde rẹ̀? Ọ̀kan lára àwọn àbájáde rẹ̀ ni pé: “Àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá; èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí.”—Hágáì 2:7.
Kí ni “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” tó máa jáde wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè? Àwọn nǹkan náà kò lè jẹ́ ohun ìní. (Hágáì 2:8) Kì í ṣe fàdákà àti wúrà ló ń mú ọkàn Jèhófà yọ̀. Àwọn èèyàn tó ń fìfẹ́ jọ́sìn rẹ̀ bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ aláìpé ló ń mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. (Òwe 27:11) Àwọn wọ̀nyí ni “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” tí ń mú ògo bá Jèhófà, ìfọkànsìn wọn àti iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń fìtara ṣe sì ṣeyebíye lójú rẹ̀. Ṣé o wà lára àwọn èèyàn náà?
Ó dà bí ohun tí kò ṣeé gbà gbọ́ pé ẹ̀dá èèyàn aláìpé lè jẹ́ ẹni fífani lọ́kàn mọ́ra lójú Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run. Ní tòótọ́, ó yẹ kí èyí mú ká tẹ́wọ́ gba ìkésíni rẹ̀ pé ká sún mọ́ òun.—Aísáyà 55:6; Jákọ́bù 4:8.
“O Jẹ́ Ẹnì Kan Tí Ó Fani Lọ́kàn Mọ́ra Gidigidi”
Nígbà tí wòlíì Dáníẹ́lì ti darúgbó, ó rí ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lọ́jọ́ kan nígbà tí ilẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣú. Bí Dáníẹ́lì ṣe ń gbàdúrà, àlejò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ dé bá a lójijì. Gébúrẹ́lì ni orúkọ rẹ̀. Dáníẹ́lì ti bá a pàdé rí, ó sì mọ̀ pé áńgẹ́lì Jèhófà ni. Gébúrẹ́lì sọ ìdí tí òun fi dé lójijì, ó ní: “Ìwọ Dáníẹ́lì, nísinsìnyí mo wá láti mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye pẹ̀lú ìmọ̀ . . . nítorí o jẹ́ ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi.”—Dáníẹ́lì 9:21-23.
Ní àkókò míì, ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì Jèhófà bá Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀, ó ní: “Dáníẹ́lì, ìwọ ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.” Lẹ́yìn náà, áńgẹ́lì náà fún Dáníẹ́lì lókun pé: “Má fòyà, ìwọ ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi. Kí o ní àlàáfíà.” (Dáníẹ́lì 10:11, 19) Ìgbà mẹ́ta làwọn áńgẹ́lì tó bá Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ pè é ní ẹni “fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.” Gbólóhùn yìí tún lè túmọ̀ sí “olùfẹ́ ọ̀wọ́n,” “ẹni tí a gbé ga gidigidi,” àti “àyànfẹ́.”
Ó dájú pé Dáníẹ́lì mọ̀ ọ́n lára pé òun sún mọ́ Ọlọ́run, kò sì sí iyè méjì pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tó ń ṣe látọkànwá. Àmọ́, ó dájú pé ohun tí Ọlọ́run tipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì sọ fún Dáníẹ́lì pé òun fẹ́ràn rẹ̀ túbọ̀ mú kó dá Dáníẹ́lì lójú pé Ọlọ́run bìkítà Dáníẹ́lì 10:19.
nípa òun. Abájọ tí Dáníẹ́lì fi dáhùn pé: “Ìwọ ti fún mi lókun.”—Jèhófà mú kí wọ́n kọ ìtàn amọ́kànyọ̀ nípa bí òun ṣe fìfẹ́ hàn sí wòlíì òun olóòótọ́ yìí sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún àǹfààní wa. (Róòmù 15:4) Tá a bá ronú lórí àpẹẹrẹ Dáníẹ́lì, èyí á jẹ́ ká lóye ohun tó ń mú kẹ́nì kan jẹ́ ẹni fífani lọ́kàn mọ́ra lójú Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́.
Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Déédéé
Dáníẹ́lì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ dáadáa. A mọ̀ bẹ́ẹ̀ nítorí ó kọ̀wé pé: “Èmi . . . fi òye mọ̀ láti inú [àwọn] ìwé, iye ọdún . . . láti mú ìparundahoro Jerúsálẹ́mù ṣẹ.” (Dáníẹ́lì 9:2) Àwọn ìwé tí Mósè, Dáfídì, Sólómọ́nì, Aísáyà, Jeremáyà, Ìsíkíẹ́lì àti àwọn wòlíì yòókù kọ lè wà lára àwọn ìwé tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ̀ nígbà yẹn. A lè fojú inú wo bí Dáníẹ́lì ṣe kó ọ̀pọ̀ àkájọ ìwé sọ́dọ̀, tó ń kà wọ́n tọkàntọkàn, tó sì ń ṣe ìfiwéra àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìmúbọ̀sípò ìjọsìn tòótọ́ ní Jerúsálẹ́mù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ inú yàrá rẹ̀ tó wà lórí òrùlé ló wà níbi tí kò sí ìdílọ́wọ́, ó sì dájú pé àṣàrò tó jinlẹ̀ lórí ìtumọ̀ àwọn àyọkà yẹn ló ń ṣe. Ìkẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀ tó ṣe yìí, fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun, ó sì mú kó sún mọ́ Jèhófà.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún mú kí ìwà Dáníẹ́lì dára, ó sì mú kó gbé ìgbé ayé tó dára. Kò sí àní-àní pé, ẹ̀kọ́ tó kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ nígbà tó wà lọ́mọdé ràn án lọ́wọ́ nígbà tó dàgbà láti pa Òfin tí Ọlọ́run ṣe nígbà yẹn lórí oúnjẹ mọ́. (Dáníẹ́lì 1:8) Nígbà tó yá, ó fi ìgboyà kéde iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an sí àwọn alákòóso Bábílónì. (Òwe 29:25; Dáníẹ́lì 4:19-25; 5:22-28) Àwọn èèyàn mọ Dáníẹ́lì dáadáa sí òṣìṣẹ́, olóòótọ́ àti ẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. (Dáníẹ́lì 6:4) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kàkà kí Dáníẹ́lì jáwọ́ nínú ìjọsìn tòótọ́ kó bàa lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, ńṣe ló gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. (Òwe 3:5, 6; Dáníẹ́lì 6:23) Abájọ tó fi jẹ́ ẹni tó “fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi” lójú Ọlọ́run!
Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rọrùn fún wa lónìí ju bó ṣe rí fún Dáníẹ́lì lọ. Wọ́n ti ṣe àwọn ìwé tó rọrùn láti gbé káàkiri láti fi rọ́pò àwọn àkájọ ìwé gbẹ̀ǹgbẹ̀ ti ìgbà yẹn. A ní odindi Bíbélì nísinsìnyí, a sì tún ní àkọsílẹ̀ tó ṣàlàyé bí àwọn kan lára àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ṣe ní ìmúṣẹ. A sì ní ọ̀pọ̀ ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ohun tí a fi ń ṣe ìwádìí. * Ṣé o máa ń lò wọ́n? Ǹjẹ́ o ti ṣètò àkókò fún kíka Bíbélì déédéé àti ṣíṣàsàrò lórí rẹ̀? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ yóò rí bíi ti Dáníẹ́lì. Wàá lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run yóò sì jinlẹ̀ gan-an. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á máa tọ́ ẹ sọ́nà ní ìgbésí ayé rẹ, á sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run ń fìfẹ́ bìkítà nípa rẹ.
Ní Ìforítì Nínú Àdúrà
Dáníẹ́lì máa ń gbàdúrà gan-an. Ó máa ń béèrè ohun tó yẹ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Nígbà tí Dáníẹ́lì ti dàgbà, Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lá àlá kan, tí Dáníẹ́lì kò bá sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ọba máa pa á. Nítorí náà, Dáníẹ́lì tètè bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ kó sì dáàbò bo òun. (Dáníẹ́lì 2:17, 18) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, wòlíì olóòótọ́ yìí fìrẹ̀lẹ̀ sọ bí àìpé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn ti pọ̀ tó, ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti ti àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Jèhófà. (Dáníẹ́lì 9:3-6, 20) Nígbà tí Dáníẹ́lì kò lóye àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fi hàn án nínú ìran, ó béèrè pé kí Ọlọ́run la òun lóye. Nígbà kan, Ọlọ́run rán áńgẹ́lì kan sí Dáníẹ́lì kó lè jẹ́ kó túbọ̀ lóye kíkún, áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “A ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.”—Dáníẹ́lì 10:12.
Yàtọ̀ sí pé Dáníẹ́lì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run, ó tún ṣe nǹkan míì. Dáníẹ́lì 6:10 sọ pé: “Àní ní ìgbà mẹ́ta lójúmọ́ . . . ó ń gbàdúrà, ó sì ń bu ìyìn níwájú Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe.” Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú kí Dáníẹ́lì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà kó sì máa yìn ín. Ó sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Bẹ́ẹ̀ ni, àdúrà jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn rẹ̀ tó fi jẹ́ pé kò lè ṣe kó má gbàdúrà, àní ó tún gbàdúrà nígbà tó mọ̀ pé ó lè yọrí sí ikú fún òun. Ó dájú pé ìdúróṣinṣin rẹ̀ yìí mú kó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n lójú Jèhófà.
Ẹ ò rí i pé ẹ̀bùn àgbàyanu ni àǹfààní téèyàn ní láti gbàdúrà! Má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ kan kọjá láì bá Bàbá rẹ ọ̀run sọ̀rọ̀. Rántí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ kó o sì yìn ín nítorí gbogbo oore rẹ̀ lórí rẹ. Máa sọ àníyàn àti ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún un fàlàlà. Ronú lórí bí Ọlọ́run ṣe dáhùn ìbéèrè àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ, kó o sì máa dúpẹ́. Máa lo àkókò tó gùn láti fi gbàdúrà. Nígbà tá a bá sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún Jèhófà nínu àdúrà, a ó rí ìfẹ́ rẹ̀ lára wa lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ẹ ò rí i pé ó yẹ kí èyí mú ká máa “ní ìforítì nínú àdúrà”!—Róòmù 12:12.
Fi Ògo fún Orúkọ Jèhófà
Àwọn méjì kò lè ṣọ̀rẹ́ pẹ́ bí ẹnì kan lára wọn bá jẹ́ onímọtara ẹni nìkan. Àwa náà kò gbọ́dọ̀ jẹ́ onímọtara ẹni nìkan nínú àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Dáníẹ́lì mọ̀ nípa èyí dáadáa. Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe fi ọwọ́ pàtàkì mú fífi ògo fún orúkọ Jèhófà.
Nígbà tí Ọlọ́run dáhùn àdúrà Dáníẹ́lì nípa fífi ohun tí àlá Nebukadinésárì àti ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ hàn án, Dáníẹ́lì sọ pé: “Kí a fi ìbùkún fún orúkọ Ọlọ́run láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, nítorí ọgbọ́n àti agbára ńlá—wọ́n jẹ́ tirẹ̀.” Nígbà tí Dáníẹ́lì ń sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún Nebukadinésárì, léraléra ni Dáníẹ́lì ń fi ògo fún Jèhófà, tó sì ń tẹnu mọ̀ ọ́n pé, Jèhófà nìkan ni “Olùṣí àwọn àṣírí payá.” Bákan náà, nígbà tí Dáníẹ́lì gbàdúrà fún ìdáríjì àti ìdáǹdè, ó sọ pé: “Ọlọ́run mi, nítorí orúkọ rẹ ni a fi pe ìlú ńlá rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ.”—Dáníẹ́lì 2:20, 28; 9:19.
A ní àǹfààní tó pọ̀ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáníẹ́lì lórí ọ̀ràn yìí. Nígbà tá a bá ń gbàdúrà, a lè bẹ̀bẹ̀ pé kí “orúkọ” Ọlọ́run “di mímọ́.” (Mátíù 6:9, 10) A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìwà wa kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ Jèhófà. Bákan náà, ká máa fi ògo fún Jèhófà nígbà gbogbo nípa wíwàásù ìhìn rere àwọn ohun tá a mọ̀ nípa Ìjọba rẹ̀ fún àwọn èèyàn.
Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìfẹ́ nínú ayé yìí, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ bìkítà nípa àwọn èèyàn. Àmọ́, mímọ̀ tá a mọ̀ pé Jèhófà bìkítà nípa àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìtùnú fún wa. Onísáàmù kan sì jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Jèhófà ní ìdùnnú sí àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó ń fi ìgbàlà ṣe àwọn ọlọ́kàn tútù lẹ́wà.”—Sáàmù 149:4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ohun ìṣèwádìí tó lè mú kí Bíbélì kíkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ṣe ẹ́ láǹfààní. Tó o bá fẹ́ gba àwọn ohun tó ń ranni lọ́wọ́ yìí, béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]
Ọlọ́run fìfẹ́ hàn sí Dáníẹ́lì nípa rírán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì pé kó lọ fún un lókun
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]
Nítorí pé Dáníẹ́lì máa ń kẹ́kọ̀ọ́, tó sì máa ń gbàdúrà gan-an, ìyẹn mú kí ìwà rẹ̀ dára, ó sì mú kó di ẹni ọ̀wọ́n lójú Ọlọ́run