Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Rí Ará Ìlà Oòrùn Éṣíà Kan Ní Ítálì Àtijọ́

Wọ́n Rí Ará Ìlà Oòrùn Éṣíà Kan Ní Ítálì Àtijọ́

Wọ́n Rí Ará Ìlà Oòrùn Éṣíà Kan Ní Ítálì Àtijọ́

BÁWO ni ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Ìlà Oòrùn Éṣíà ṣe dé Ilẹ̀ Ọba Róòmù àtijọ́ ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] sẹ́yìn? Ìbéèrè yìí ló wá sọ́kàn àwọn awalẹ̀pìtàn lẹ́yìn tí wọ́n ti rí ohun kan tó gbàfiyèsí ní gúúsù orílẹ̀-èdè Ítálì lọ́dún 2009.

Itẹ́ òkú àwọn ará Róòmù ní ìlú Vagnari, tó wà ní ọgọ́ta [60] kìlómítà ní gúúsù ìlú Bari ni wọ́n ti ṣàwárí náà. Egungun òkú èèyàn márùn-ún lé ní àádọ́rin [75] ni wọ́n hú níbẹ̀. Àyẹ̀wò àwọn egungun òkú náà fi hàn pé itòsí ibẹ̀ ni wọ́n ti bí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn. Àmọ́ egungun òkú ọkùnrin kan mú ìyàlẹ́nu bá àwọn tó ṣe ìwádìí náà. Àyẹ̀wò kínníkínní tí wọ́n ṣe lórí apilẹ̀ àbùdá ọkùnrin náà fi hàn pé Ìlà Oòrùn Éṣíà ni ìyá rẹ̀ ti wá. * Egungun rẹ̀ yìí ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tàbí ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ti wí, “ó jọ pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí wọ́n máa rí egungun ẹnì kan ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù tí ìyà rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ìlà Oòrùn Éṣíà.” Nítorí náà, ta ni ọkùnrin yìí?

Ìròyìn kan náà yìí sọ pé, “Téèyàn bá kọ́kọ́ wo ọ̀rọ̀ yìí, èèyàn á rò pé ẹni yìí wà lára àwọn tó ń ṣòwò sílíìkì tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ láàárín ilẹ̀ Ṣáínà àti ilẹ̀ Róòmù.” Àmọ́, ohun tí wọ́n sọ nípa àwọn tó ń ṣòwò yìí ni pé, àwọn kan ló máa rà á, wọ́n á sì tún un tà fún àwọn míì, èyí ló fi jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo kọ́ ló ń rin gbogbo ìrìn àjò náà láti gbé ọjà yìí lọ sí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] kìlómítà, ìyẹn láti Ṣáínà sí Ítálì.

Kí ni ibi tí wọ́n ti rí egungun náà fi hàn? Nígbà àtijọ́, ìlú Vagnari jẹ́ ìgbèríko èyí tí olú ọba ń ṣàkóso, àwọn lébìrà máa ń yọ́ irin níbẹ̀, wọ́n sì tún ń ṣe àwo ìbolé níbẹ̀. Ẹrú ni ọ̀pọ̀ lára àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kí ará Ìlà Oòrùn Éṣíà náà jẹ́ ẹrú. Kódà, bí wọ́n ṣe sin ín fi hàn pé kì í ṣe ọlọ́rọ̀. Ìkòkò kan ṣoṣo ni ohun ìní tó ní, wọ́n sin ín pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì tún ti sin òkú míì sí orí ọkùnrin náà.

Kí nìdí tí ohun tí wọ́n rí yìí fi jọni lójú tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, ibi tí àwọn tó ń rìnrìn àjò bá dé nígbà yẹn ni ìhìn rere tí àwọn Kristẹni ń wàásù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni máa tàn dé. Bíbélì sọ pé, lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn àlejò ilẹ̀ òkèèrè tó wá sí Jerúsálẹ́mù, mú ìhìn rere tí wọ́n gbọ́ pa dà lọ sí ibi tó jìnnà rere. (Ìṣe 2:1-12, 37-41) Ó kéré tán, egungun òkú ọkùnrin náà fi hàn pé, ní àkókò yẹn àwọn èèyàn kan ń rìnrìn àjò láti Ìlà Oòrùn Éṣíà wá sí àgbègbè Mẹditaréníà. *

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Àyẹ̀wò apilẹ̀ àbùdá ọkùnrin náà kò fi ibi tí baba rẹ̀ ti wá hàn.

^ Ẹ̀rí tún wà pé àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé máa ń rìnrìn àjò lọ sí Ìlà Oòrùn Éṣíà. Ka àpilẹ̀kọ náà, “Ṣáwọn Míṣọ́nnárì Dé Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn Ayé?,” èyí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2009.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 29]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

RÓÒMÙ

Vagnari

Òkun Mẹditaréníà

ÌLÀ OÒRÙN ÉṢÍÀ

ÒKUN PÀSÍFÍÌKÌ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Egungun òkú ọkùnrin ará Ìlà Oòrùn Éṣíà kan tí wọ́n hú jáde nínú itẹ́ òkú àwọn ará Róòmù àtijọ́

[Credit Line]

© Su concessione del Ministero per i Beni e le Attività Culturali-Direzione Regionale per i Beni Culturali e Paesaggistici della Puglia - Soprintendenza per i Beni Archeologici della Puglia