Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .
Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Gba Ìtọ́jú Lọ́dọ̀ Àwọn Dókítà?
Jésù sọ pé, “àwọn ẹni tí ó ní ìlera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀.” (Mátíù 9:12) Ohun tí Jésù sọ yìí fi hàn pé, Ìwé Mímọ́ kò lòdì sí gbígba ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn dókítà. Nítorí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gba ìtọ́jú àti oògùn nílé ìwòsàn. Wọ́n fẹ́ kí ara wọ́n le, wọ́n sì ń fẹ́ kí ẹ̀mí àwọn gùn. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, Kristẹni kan wà tó ń jẹ́ Lúùkù, dókítà ni, bákan náà lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wà tí wọ́n jẹ́ dókítà.—Kólósè 4:14.
Àmọ́ ṣá o, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba ìtọ́jú tó bá ta ko àwọn ìlànà Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í gba ẹ̀jẹ̀ sára nítorí Bíbélì sọ pé, a kò gbọ́dọ̀ lo ẹ̀jẹ̀ láti gbé ẹ̀mí wa ró. (Jẹ́nẹ́sísì 9:4; Léfítíkù 17:1-14; Ìṣe 15:28, 29) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún sọ pé ká má ṣe gba ìtọ́jú tàbí lo ọ̀nà ìtọ́jú tó jẹ mọ́ “agbára abàmì,” tàbí agbára ẹ̀mí èṣù.—Aísáyà 1:13; Gálátíà 5:19-21.
Ọ̀pọ̀ àwọn dókítà ló ń lo àwọn ọ̀nà tí kò ta ko àwọn ìlànà Bíbélì láti gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là. Lọ́pọ̀ ìgbà irú àwọn ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ ojúlówó, wọ́n sì dára ju ìtọ́jú tó ta ko àwọn ìlànà Ọlọ́run lọ. Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló sì máa ń gba irú àwọn ìtọ́jú tó dára yẹn.
Àmọ́ ṣá o, èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn ní tó bá di ọ̀ràn ìlera. Ohun tó ṣe ẹnì kan láǹfààní lè máà wúlò fún ẹlòmíì. Nítorí náà, kò burú tí àwọn tó ń wá àyẹ̀wò tó péye nípa ohun tó ń ṣe wọ́n tàbí ìtọ́jú àìsàn kan bá wá àmọ̀ràn lọ sọ́dọ̀ dókítà tó ju ẹyọ kan lọ.—Òwe 14:15.
Kì í ṣe ìpinnu kan náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe tó bá di ọ̀ràn ìtọ́jú ara. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fàyè gba Kristẹni kọ̀ọ̀kan láti lo ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ lórí ọ̀ràn tí Bíbélì kò bá ti ṣe òfin. (Róòmù 14:2-4) Nítorí náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan ní láti ṣèwádìí nípa ìtọ́jú èyíkéyìí tó bá fẹ́ gbà, kí ó sì rí i dájú pé kò ta ko ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́.—Gálátíà 6:5; Hébérù 5:14.
Ẹlẹ́rìí kan máa wo ìpinnu kọ̀ọ̀kàn tó fẹ́ ṣe bí ìgbà tí awakọ̀ kan fẹ́ gba oríta ọ̀nà kan tí ọkọ̀ tó pọ̀ ti ń kọjá. Tó bá tẹ̀ lé àwọn ọkọ̀ tó ń lọ níwájú tó sì sáré kọjá ní oríta náà, ó lè fa jàǹbá ńlá. Àmọ́, awakọ̀ tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n á dúró, a wo ọ̀tún, a wo òsì títí ọ̀nà yóò fi dára, kó tó kọjá. Bákan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí kì í kánjú ṣe ìpinnu nípa ìtọ́jú ara, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í tẹ̀ lé èrò àwọn èèyàn láìronú. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń gbé àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yẹ̀ wò dáadáa, wọ́n á sì tún gbé àwọn ìlànà Bíbélì yẹ̀ wò kí wọ́n tó ṣe ìpinnu.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọyì iṣẹ́ bàǹtàbanta táwọn dókítà ń ṣe láti tọ́jú àwọn èèyàn. Wọ́n sì tún ń fi ìmoore hàn fún bí wọ́n ṣe ń mú ìtura bá àwọn aláìsàn.