Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

KÍ LÓ mú kí obìnrin kan tó máa ń ṣépè, tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ọtí, tó máa ń mu ọtí lámujù, tó sì ń lo oògùn olóró yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà. Kí nìdí tí olóṣèlú tẹ́lẹ̀rí kan tó kórìíra ìsìn fi wá di ẹlẹ́sìn? Àwọn ìṣòro wo ni olùkọ́ kan tó ń kọ́ àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Rọ́ṣíà bí wọ́n ṣe máa bá àwọn arúfin wọ ìjàkadì ní láti borí kó tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Kà nípa ohun táwọn èèyàn náà sọ.

“Àjọse àárín èmi àti màmá mi ti wá pa dà dára.”—NATALIE HAM

ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1965

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: ỌSIRÉLÍÀ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MÒ Ń LO OÒGÙN OLÓRÓ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Robe, ní ìpínlẹ̀ South Australia ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, ẹja ni wọ́n ń pa níbẹ̀. Òtẹ́ẹ̀lì tó wà ládùúgbò yìí làwọn onírúurú èèyàn ti máa ń wá gbafẹ́. Àwọn òbí máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò ní òtẹ́ẹ̀lì yìí, nítorí náà, ibi tí ọtí àmujù, sìgá mímú àti ọ̀rọ̀ èébú ti wọ́pọ̀ làwọn ọmọ wọn dàgbà sí.

Nígbà tí mo fi máa pé ọmọ ọdún méjìlá, mo ti ń mu sìgá, mo ti di ẹlẹ́kẹ̀ẹ́ èébú, mo sì máa ń bá màmá mi fa wàhálà. Nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, àwọn òbí mi pínyà, ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn náà, mo fi ilé sílẹ̀. Mò ń mu ọtí ní àmupara, mò ń lo oògùn olóró, mo sì di oníṣekúṣe. Inú máa ń bí mi, mi ò sì mọ ohun tó yẹ kí n ṣe. Àmọ́ ṣá o, mo ti fi ọdún márùn-ún kọ́ ìjà kọnfú àti bí obìnrin ṣe lè gbèjà ara rẹ̀, nítorí náà, mo gbà pé mo lè dáàbò bo ara mi. Síbẹ̀ náà, nígbà tí mo bá dá wà, tí mò ń ronú, ìbànújẹ́ máa ń dorí mi kodò, màá sì gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́. Mo máa ń sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ má sọ pé kí n lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì o.”

Nígbà tó yá, ọ̀rẹ́ mi kan tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀sìn àmọ́ tí kò fára mọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kankan fún mi ní Bíbélì kan. Òun náà máa ń lo oògùn olóró bíi tàwọn ọ̀rẹ́ wa yòókù. Síbẹ̀, ó sọ pé òun nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó sì jẹ́ kó dá mi lójú pé ó yẹ kí n ṣèrìbọmi. Ó mú mi lọ sí adágún omi kan ládùúgbò náà, ó sì ṣèrìbọmi fún mi. Láti ìgbà yẹn lọ, mo gbà pé mo ti ní àjọṣe pàtàkì pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́, mi ò wá àyè láti ka Bíbélì.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Lọ́dún1988, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì wá kan ilẹ̀kùn mi. Ọ̀kan lára wọn bi mí pé, “Ǹjẹ́ o mọ orúkọ Ọlọ́run?” Ẹlẹ́rìí náà ka Sáàmù 83:18 látinú Bíbélì rẹ̀, ó ní: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Ẹnú yà mí gan-an! Nígbà tí wọ́n lọ, mo wakọ̀ lọ sí kìlómítà mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56] láti wo àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì míì ní ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta ìwé àwọn Kristẹni àti láti wo orúkọ náà nínú ìwé atúmọ̀ èdè. Nígbà tó ti dá mi lójú pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, mo bi ara mi pé, kí ló kù tó yẹ kí n mọ̀.

Ìyá mi ti sọ fún mi tẹ́lẹ̀ pé, ìṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ sí ti gbogbo ayé. Látinú ohun tí èmi fúnra mi mọ̀ nípa wọn, èrò mi ni pé, wọn kò lajú, wọn kì í sì í gbádùn ara wọn. Nítorí náà, mo ronú pé, màá ṣe bíi pé mi ò sí nílé nígbà tí wọ́n bá tún wá sílé mi. Àmọ́ nígbà tí wọ́n wá, mo yí èrò mi pa dà, mo ní kí wọ́n wọlé, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Lẹ́yìn tá a bá ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, mo máa ń sọ ohun tí mo kọ́ fún Craig, ọ̀rẹ́kùnrin mi. Níkẹyìn, ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ fún un yẹn bí i nínú, ló bá gba ìwé náà lọ́wọ́ mi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Kí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tó pé, ó gbà pé òun ti rí òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Nígbà tó yá, èmi àti Craig jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró àti ọtí àmujù, mo sì fi iṣẹ́ ilé ọtí tí mo ń ṣe sílẹ̀. Kí á bàa lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nígbèésí ayé wa, a pinnu láti ṣègbéyàwó.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Èmi àti Craig ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tú ká nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lónìí, ọkọ àtàtà ni Craig jẹ́ fún mi, a sì ní ìbejì, ọkùnrin ni wọ́n, wọ́n sì rẹwà. A tún láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tá a jọ gba ohun kan náà gbọ́.

Lákọ̀ọ́kọ́, inú bí màmá mi gan-an nígbà tó gbọ́ pé mò ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, èrò òdì tó ní nípa wọn ló mú kó bínú. Ní báyìí, àjọse àárín èmi àti màmá mi ti wá pa dà dára. Mi ò kì í ronú mọ́ pé ìgbésí ayé mi kò jámọ́ nǹkan kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbésí ayé mi nítumọ̀, mo sì ti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run.—Mátíù 5:3.

“Mo ti kọ́ ọ̀pọ̀ ohun àgbàyanu látinú Bíbélì.”—ISAKALA PAENIU

ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1939

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: TUVALU

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: OLÓṢÈLÚ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Wọ́n bí mi ní Nukulaelae, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn erékùṣù Pàsífíìkì, èyí tó jẹ́ apá kan orílẹ̀-èdè Tuvalu nísinsìnyí, erékùṣù yìí rẹwà gan-an. Àwọn pásítọ̀ tó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn ní ilé ẹ̀kọ́ ìsìn ní erékùṣù Samoa ló ń darí àwọn èèyàn ibẹ̀. Ojúṣe àwọn èèyàn erékùṣù náà ni láti máa bọ́ àwọn pásítọ̀ àti ìdílé wọn, láti fún wọn ní ibi tí wọ́n á máa gbé, kódà àwọn nǹkan tó bá dára jù lọ ni wọ́n ń fún àwọn pásítọ̀ náà. Àní bí àwọn èèyàn erékùṣù náà kò bá ní oúnjẹ tó tó fún ìdílé tiwọn alára, ó di dandan kí wọ́n pèsè oúnjẹ fún àwọn pásítọ̀ náà.

Pásítọ̀ tó wà ní erékùṣù tí à ń gbé ló ń bójú tó ilé ẹ̀kọ́ abúlé náà, òun ló ń kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ ìsìn, ìṣirò àti àwọn ẹ̀kọ́ jọ́gíráfì kan. Mo rántí ọjọ́ kan tí pásítọ̀ yìí na àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà nínàkunà débi pé ẹ̀jẹ̀ bò wọ́n. Àmọ́, kò sẹ́ni tó sọ pé ohun tó ṣe kò dáa, àwọn òbí wọn pàápàá kò sọ nǹkan kan. Ńṣe ni wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún pásítọ̀ náà bíi pé Ọlọ́run ni.

Nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́wàá, mo kúrò nílé, mo sì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ìjọba tó wà fún àgbègbè yẹn, erékùṣù míì ni wọ́n kọ́ ọ sí. Nígbà tí mo jáde ní ilé ẹ̀kọ́ náà, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìjọba. Lákòókò yẹn, abẹ́ àkóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tí wọ́n ń pè ní Erékùṣù Gilbert àti Ellice làwọn erékùṣù náà wà. Mo ṣiṣẹ́ ní oríṣiríṣi ẹ̀ka iṣẹ́ kí n tó wá di olóòtú àgbà fún ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tó jẹ́ ti ìjọba. Gbogbo rẹ̀ ń dáa bọ̀, títí dìgbà tí mo tẹ lẹ́tà òǹkàwé wa kan jáde. Lẹ́tà náà ṣàríwísí owó kan tí wọ́n ná sórí ìmúrasílẹ̀ fún ìbẹ̀wò Ọmọ Ọba Wales. Orúkọ míì lẹ́ni tó kọ lẹ́tà náà lò, àmọ́ ọ̀gá mi sọ pé òun fẹ́ mọ orúkọ ẹni náà gan-an tó kọ lẹ́tà náà. Mo kọ̀ láti sọ orúkọ náà fún un, èdèkòyédè èmi àti ọ̀gá yìí di ọ̀rọ̀ tí gbogbo èèyàn mọ̀ nípa rẹ̀.

Láìpẹ́ sígbà tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, mo fi iṣẹ́ ìjọba náà sílẹ̀, mo sì di olóṣèlú. Èmi ni mo jáwé olúborí nínú ìbò ní erékùṣù Nukulaelae, wọ́n sì fi mí jẹ Mínísítà Ọrọ̀ Ajé àti Ohun Àmúṣọrọ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí àwọn èèyàn láti erékùṣù Kiribati (ìyẹn Gilbert tẹ́lẹ̀) àti Tuvalu (ìyẹn Ellice tẹ́lẹ̀) gba òmìnira látọ̀dọ̀ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, gómìnà wa ní kí n wá jẹ olórí ìjọba Tuvalu. Àmọ́, mi ò fẹ́ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìjọba agbókèèrè ṣàkóso. Nítorí náà, mi ò gba ohun tó fi lọ̀ mí náà, èyí kò sì jẹ́ kí n ní alátìlẹyìn nígbà tí mo díje nínú ìbò gbogbo gbòò fún ipò mínísítà. Mo pàdánù nínú ìbò náà. Lẹ́yìn náà, èmi àti ìyàwó mi pa dà sílé ní erékùṣù wa, mo sì pinnu láti máa gbé ní ìgbèríko.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Ọjọ́ Sunday jẹ́ ọjọ́ Sábáàtì ní gbogbo àwọn erékùṣù náà, nítorí náà, gbogbo èèyàn ló ka ọjọ́ yìí sí ọjọ́ mímọ́, àyàfi èmi nìkan. Ọjọ́ yẹn ni mo máa ń fi ọkọ̀ ojú omi gbafẹ́, tí mo sì máa ń pẹja. Mi ò fẹ́ kí wọ́n mọ̀ mí sí onísìn. Bàbá mi sọ fún mi pé, ohun tí mò ń ṣe yìí ń kó ìbànújẹ́ bá òun àti àwọn ẹlòmíì. Àmọ́ mo ti pinnu pé ṣọ́ọ̀ṣì kò ní tú mi jẹ.

Mo máa ń lọ sí Funafuti tó jẹ́ olú ìlú Tuvalu dáadáa, àmọ́ lọ́jọ́ kan tí mo lọ síbẹ̀, àbúrò mi ọkùnrin ní kí n ká lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn ìyẹn, ni Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì kó ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! rẹpẹtẹ fún mi pé kí n lọ kà wọ́n. Ó tún fún mi ní ìwé kan tó túdìí àṣírí pé àwọn ẹ̀kọ́ tí ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni ló wá látọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà. Mo ka ìwé yẹn ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Mo kọ́ ọ̀pọ̀ ohun àgbàyanu látinú Bíbélì, títí kan òtítọ́ náà pé a kò ní kí àwọn Kristẹni máa ṣe Sábáàtì. * Mo sọ àwọn kókó yìí fún ìyàwó mi, lòun náà kò bá lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́.

Àmọ́, mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé mi ò ní ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó nǹkan bí ọdún méjì, àmọ́ mi ò lè gbàgbé ohun tí mo ti kọ́. Níkẹyìn, mo kọ̀wé sí míṣọ́nnárì yẹn ní Funafuti, mo sọ fún un pé mo múra tán láti ṣe ìyípadà. Lójú ẹsẹ̀, ó wọ ọkọ̀ ojú omi tó fẹ́ wá sí àdúgbò wa, ó sì wá kọ́ mi ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nínú Bíbélì. Inú bí bàbá mi gan-an nígbà tó mọ̀ pé mo fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, mo sọ fún un pé mo ti kọ́ ohun tó pọ̀ gan-an nípa Bíbélì látọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì ti pinnu ohun tí mo fẹ́ ṣe.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Lọ́dún 1986, mo ṣèrìbọmi, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lọdún kan lẹ́yìn náà, ìyàwó mi ṣèrìbọmi. Àwọn ọmọbìnrin wa méjèèjì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì pinnu láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Nísinsìnyí, inú mi dùn pé mo jẹ́ ara àwùjọ ẹ̀sìn kan tó rí bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n kò ní ẹgbẹ́ àlùfáà àti ti ọmọ ìjọ. (Mátíù 23:8-12) Àwùjọ ẹ̀sìn yìí tún ń fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, wọ́n sì ń wàásù fún àwọn èèyàn nípa ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 4:17) Mo dúpẹ́ mo tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ kí n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa òun àtàwọn èèyàn rẹ̀!

“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fipá mú mi láti gba ohun kan gbọ́.”—ALEXANDER SOSKOV

ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1971

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: RỌ́ṢÍÀ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: OLÙKỌ́ ÀWỌN TÓ Ń JA ÌJÀKADÌ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Wọ́n bí mi ní ìlú Moscow, ìlú yìí sì ni olú ìlú ìjọba Soviet Union nígbà yẹn. Ìdílé wa ń gbé nínú ilé ńlá kan, ọ̀pọ̀ àwọn aládùúgbò wa ló sì ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ kan náà. Mo rántí ohun tí wọ́n máa ń sọ pé, ìpáǹle ọmọ ni mí, tí wọ́n sì máa ń sọ pé, mi ò lè pẹ́ kí ń tó kú tàbí kí n dèrò ẹ̀wọ̀n. Lóòótọ́, nígbà tí mo fi máa di ọmọ ọdún mẹ́wàá, orúkọ mi ti wà nínú àkọsílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá.

Nígbà tí mo di ọmọ ọdún méjìdínlógún, ìjọba mú mi wọnú iṣẹ́ ológún, mo sì jẹ́ ẹ̀ṣọ́ ẹnubodè. Mo pa dà sílé lẹ́yìn ọdún méjì, mó sì ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ kan, àmọ́ iṣẹ́ náà sú mi. Nítorí náà, mo dara pọ̀ mọ́ àwọn ọlọ́pàá Moscow tó máa ń kó àwọn tó ń ja ìjà ìgboro, èmi sì ni mò ń kọ́ àwọn ọlọ́pàá bí wọ́n ṣe máa bá àwọn arúfin wọ ìjàkadì. Mo ṣèrànwọ́ láti kó àwọn arúfin nílùú Moscow, mo sì lọ sí àwọn ibi tí yánpọnyánrin wà káàkiri orílẹ̀-èdè wa. Ńṣe ní ìjà ń gbé mi nínú. Nígbà tí mo bá pa dà délé, ìgbà míì wà tí mi ò kì í sùn síbi tí ìyàwó bá sùn sí, nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé mo lè ṣe é léṣe nígbà tí mo bá ń ṣèrànrán lójú oorun.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo rí i pé ìwà ipá tí mò ń hù kò bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. Mo tún rí i pé ó yẹ kí n jáwọ́ nínú sìgá mímú kí n sì dín ọtí tí mò ń mu kù. Àmọ́ mo ronú pé mi ò lè fi iṣẹ́ mi sílẹ̀, nítorí pé mi ò mọ iṣẹ́ ọwọ́ kankan tí mo lè fi wáṣẹ́ tí màá fi gbọ́ bùkátà ìdílé mi. Mo tún rò pé mi ò lè máa wàásù bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Síbẹ̀, ó dá mi lójú pé ohun tó wà nínú Bíbélì péye. Mo rí ìtùnú gbà nínú ohun tó wà ní Ísíkíẹ́lì 18:21, 22. Àyọkà yẹn sọ pé: “Ní ti ẹni burúkú, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó yí padà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti dá . . . , gbogbo ìrélànàkọjá rẹ̀ tí ó ti ṣe—a kì yóò rántí wọn lòdì sí i.”

Inú mi dùn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fipá mú mi láti gba ohun kan gbọ́, àmọ́ wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti ronú lórí ohun tí mò ń kọ́. Mo kó ogójì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára ìwé ìròyìn wọn, mo sì kà wọ́n tán kí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tó pé. Ohun tí mo kọ́ mú kí n gbà pé mo ti rí ẹ̀sìn tòótọ́.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èmi àti ìyàwó mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kọ ara wa sílẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, àárín wa ti dára sí i. Ìyàwó mi náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí mò ń kẹ́kọ̀ọ́, a sì pinnu láti jọ máa sin Jèhófà. Ìdílé wa ti túbọ̀ ń láyọ̀ nísinsìnyí. Mo tún ti rí iṣẹ́ tí kò ta ko àwọn ìlànà Bíbélì.

Nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé, ara mi kì í balẹ̀ rárá, ńṣe ló máa ń ṣe mí bíi ti ìgbà tí mo máa ń lọ kó àwọn arúfin nínú ìlú. Nísinsìnyí ọkàn mi balẹ̀ pé mo lè ṣàkóso ara mi, kódà tí ẹnì kan bá tiẹ̀ fẹ́ múnú bí mi pàápàá. Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, mo ti kọ́ bá a ṣe ń ní sùúrù fún àwọn èèyàn. Ó dùn mí pé mo ti lo ọ̀pọ̀ lára ìgbésí ayé mi dà nù, àmọ́ nísinsìnyí mo rí i pé ìgbésí ayé mi nítumọ̀. Mò ń gbádùn bí mo ṣe ń lo okun mi fún ìjọsìn Jèhófà Ọlọ́run, tí mo sì ń lò ó láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka àpilẹ̀kọ náà, “Ṣé Ó Yẹ Kó O Máa Pa Sábáàtì Mọ́?” èyí tó wà nínu Ilé Ìṣọ́, February 1, 2010, ojú ìwé 11 sí 15.