Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí ni àṣà pípèéṣẹ́, àwọn wo ló sì ń jàǹfààní rẹ̀?
▪ Òfin Mósè sọ pé àwọn àgbẹ̀ kò gbọ́dọ̀ kórè gbogbo èso oko wọn. Ó sọ pé kí àwọn tó lọ kórè má ṣe kó gbogbo irè tó wà ní eteetí pápá. Àwọn tó lọ kórè èso àjàrà kò gbọ́dọ̀ ṣa àwọn èso tó fọ́n ká sórí ilẹ̀, wọn kò sì gbọ́dọ̀ pa dà lọ kórè àwọn èso tí kò tíì gbó. Àwọn tó lọ gbọn èso igi ólífì bọ́ sórí ilẹ̀ gbọ́dọ̀ fi àwọn èso tí kò jábọ́ látorí igi náà sílẹ̀. (Léfítíkù 19:9, 10; Diutarónómì 24:19-21) Ìyẹn á jẹ́ kí àwọn òtòṣì, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn opó àtàwọn àtìpó tó ń gbé níbẹ̀ lè lọ pèéṣẹ́ tàbí ṣa àwọn èso tó ṣẹ́ kù náà.
Gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì ló ń jàǹfààní òfin pípèéṣẹ́. Ó fún àgbẹ̀ láǹfààní láti jẹ́ ọ̀làwọ́, ẹni tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan àti láti jẹ́ ẹni tó ń wojú Ọlọ́run fún ìbùkún. Ó fún àwọn tó ń pèéṣẹ́ láǹfààní láti jẹ́ òṣìṣẹ́, nítorí iṣẹ́ àṣekára ni iṣẹ́ pípèéṣẹ́. (Rúùtù 2:2-17) Ètò pípèéṣẹ́ ń fi àwọn tálákà lọ́kàn balẹ̀ pé ebi kò ní pa wọ́n, wọn ò sì ní di ìnira sọ́rùn àwọn ará ìlú. Kò tún ní jẹ́ kí wọ́n di ẹni yẹ̀yẹ́ tó ń ṣagbe tàbí kí wọ́n di ẹni tó ń gbà-níbí gbà-lọ́hùn-ún.
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Lẹ́bánónì lọ́hùn-ún-lọ́hùn-ún ni Sólómọ́nì ti kó igi gẹdú tí wọ́n fi kọ́ tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù wá?
▪ Ohun tó wà nínú ìwé 1 Àwọn Ọba 5:1-10 sọ nípa àdéhùn kan tó wà láàárín Sólómọ́nì àti Hírámù ọba Tírè. Àdéhùn yẹn sọ pé, wọ́n á gbé àwọn igi kédárì àti igi júnípà láti Lẹ́bánónì gba ojú òkun wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n á sì lò wọ́n láti fi kọ́ tẹ́ńpìlì.
Òwò pàtàkì làwọn ará Ìlà Oòrùn ayé àtijọ́ ka òwò igi kédárì sí. Wọ́n sábà máa ń fi igi yìí ṣe àwọn òpó àti ara inú tẹ́ńpìlì àtàwọn ààfin ọba ní ilẹ̀ Íjíbítì àti ní Mesopotámíà. Àwọn àkọsílẹ̀ nípa ọba, àwọn ìwé ìtàn àtàwọn àkọlé jẹ́rìí sí i pé wọ́n máa ń fi àwọn igi yìí ránṣẹ́ sí àwọn ìlú tó wà ní gúúsù Mesopotámíà, nígbà míì, wọ́n máa ń kó o bọ̀ látojú ogun tàbí kí wọ́n fi san owó òde. Ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n máa ń fi igi yìí ṣe ọkọ̀ ojú omi ti ọba, pósí àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n fi ń sìnkú.
Àwọn èèyàn káàkiri mọ igi kédárì ti Lẹ́bánónì dáadáa, nítorí pé kì í tètè bà jẹ́, ó lẹ́wà, ó sì ní òórùn dídùn, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn kòkòrò kò lè bà á jẹ́. Èyí fi hàn pé, ohun èlò tó dára jù lọ ni Sólómọ́nì fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà. Àmọ́ lónìí, àwọn igi kédárì díẹ̀ ló ṣẹ́ kù sórí àwọn òkè Lẹ́bánónì tó ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ igi náà nígbà kan rí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Bí wọ́n ṣe ń fi àwọn igi kédárì ti Lẹ́bánónì ránṣẹ́, àwòrán yìí jẹ́ ère ilẹ̀ Ásíríà tó wá láti ààfin Ságónì
[Credit Line]
Erich Lessing/Art Resource, NY