Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ṣe Pàtàkì Gan-an

Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ṣe Pàtàkì Gan-an

Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ṣe Pàtàkì Gan-an

“A ó . . . wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—MÁTÍÙ 24:14.

ÀWỌN ọ̀mọ̀wé tí wọ́n ń ṣèwádìí Bíbélì fara mọ́ ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ, wọ́n sì gbà pé ó ṣe pàtàkì gan-an. Wọ́n gbà pé ó ṣe pàtàkì nítorí ó sọ pé iṣẹ́ náà máa kárí ayé. Ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe pàtàkì nítorí pé, ó sọ iṣẹ́ tí àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣe, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù tó máa ṣáájú tó sì máa fi hàn pé ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan ń bọ̀ tó máa dé ibi gbogbo, èyí tí Jésù pè ní “òpin.”

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí ń ní ìmúṣẹ lóde òní. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni ọ̀ràn náà kàn, nítorí pé, alápá méjì ni, ó ń rọni pé ká sún mọ Ọlọ́run, ó sì tún ń kìlọ̀ fún wa. Ó ń fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wá láǹfààní láti fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run tàbí kí ó ta kò ó. Ohun tó o bá ṣe lórí ọ̀ràn yìí máa nípa lórí ìgbésí ayé rẹ.

Ẹ jẹ́ ká gbé àyíká ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò. Láwọn ọjọ́ mélòó kan kí wọ́n tó kan Jésù mọ́gi, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í ní ìbéèrè nípa ọjọ́ iwájú. Wọ́n fẹ́ mọ̀ nípa bí Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù ti máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ṣe máa bẹ̀rẹ̀. Wọ́n tún fẹ́ mọ̀ nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan,” èyí tí àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì míì tún pè ní, “òpin ayé.”—Mátíù 24:3, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀ àti Bibeli Mimọ.

Nínú èsì tí Jésù fún wọn, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, ogun tó kárí ayé, àìtó oúnjẹ, àjàkálẹ̀ àrùn àtàwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára máa ṣẹlẹ̀. Ó tún sọ pé, ìwà àìlófin máa di púpọ̀, pé àwọn olùkọ́ ẹ̀sìn èké máa ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà, àti pé, àwọn èèyàn á kórìíra àwọn Kristẹni tòótọ́, wọ́n á sì ṣe inúnibíni sí wọn. Gbogbo nǹkan yìí pátá ló jẹ́ ìhìn búburú.—Mátíù 24:4-13; Lúùkù 21:11.

Àmọ́ ìhìn rere tún wà. Lẹ́yìn náà ni Jésù sọ ọ̀rọ̀ tá a fà yọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀rọ̀ yìí ti fi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn balẹ̀, ó tún ń fún wọn níṣìírí, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ló ń ronú ohun tó lè túmọ̀ sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn gbà pé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí ṣe pàtàkì, síbẹ̀, èrò wọn kò ṣọ̀kan lórí ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí. Kí ni ìhìn rere? Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí máa ní ìmúṣẹ, àwọn wo ló sì máa mú un ṣẹ? Kí sì ni òpin náà? Ẹ jẹ́ ká gbé wọn yẹ̀ wò.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2, 3]

Ẹ̀dà ìwé àfọwọ́kọ ìwé ìhìn rere mẹ́rin ti ìlú Washington. Wọ́n kọ Mátíù 24:14 lọ́nà tó dúdú yàtọ̀

[Credit Line]

Látinú ẹ̀dà ìwé àfọwọ́kọ ìwé ìhìn rere mẹ́rin ti ìlú Washington látinú Àkójọ Ọ̀gbẹ́ni Freer ti ọdún 1912