Ṣé Ọlọ́run Ló Dá Èṣù?
Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .
Ṣé Ọlọ́run Ló Dá Èṣù?
▪ Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run ló dá Èṣù, nítorí pé Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ló “dá ohun gbogbo.” (Éfésù 3:9; Ìṣípayá 4:11) Àmọ́, Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run kọ́ ló dá a.
Jèhófà ló dá ẹni tí ó di Èṣù. Nítorí náà, tó bá jẹ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá ohun rere gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ, á jẹ́ pé òun kọ́ ló dá ẹni burúkú tó jẹ́ olórí alátakò rẹ̀. Ìwé Mímọ́ sọ nípa Jèhófà pé: “Pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:3-5) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé Sátánì ti fìgbà kan rí jẹ́ ẹni pípé àti olódodo, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Nínú ìwé Jòhánù 8:44, Jésù sọ pé Èṣù ‘kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́,’ tó túmọ̀ sí pé Sátánì ti fìgbà kan rí jẹ́ olóòótọ́ àti aláìlẹ́bi.
Àmọ́, bíi ti àwọn áńgẹ́lì olóye yòókù tí Jèhófà dá, áńgẹ́lì tó di Sátánì yìí ní òmìnira láti yan ohun tó tọ́ tàbí ohun tí kò tọ́. Ó sọ ara rẹ̀ di Sátánì, èyí tó túmọ̀ sí “Alátakò” nígbà tí ó yàn láti ṣe ohun tí ó ta ko Ọlọ́run tí ó sì tún mú kí tọkọtaya àkọ́kọ́ dára pọ̀ mọ́ òun nínú ìwà ọ̀tẹ̀ náà.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5.
Áńgẹ́lì burúkú yẹn tún sọ ara rẹ̀ di Èṣù, tó túmọ̀ sí “Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.” Sátánì ni ẹlẹ́tàn téèyàn kò lè fojú rí tó lo ejò yẹn, tó sì fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ pa irọ́ láti tan Éfà jẹ kó lè ṣàìgbọràn sí òfin tó ṣe kedere tí Ẹlẹ́dàá fún wọn. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi pe Sátánì ni “baba irọ́.”—Jòhánù 8:44.
Àmọ́, báwo ni áńgẹ́lì tó jẹ́ ẹni pípé tí kò ní kùdìẹ̀-kudiẹ tàbí tí ẹnì kankan kò mú ṣìnà ṣe di oníwà burúkú? Ó ṣe kedere pé, ńṣe ló fẹ́ kí àwọn ẹ̀dá èèyàn máa jọ́sìn òun dípò Ọlọ́run, ó sì fẹ́ máa ṣàkóso gbogbo èèyàn dípò kí Jèhófà máa ṣàkóso wọn. Nígbà tó ń bá a nìṣó láti máa ronú lórí ìjọsìn tó fẹ́ gbà yìí, kàkà kí ó mú èrò burúkú náà kúrò lọ́kàn, ńṣe ni ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ yìí wá lágbára sí i, títí tó fi wá ṣe nǹkan ọ̀hún. Bíbélì ṣàlàyé bí ọ̀ràn náà ṣe rí nínú ìwé Jákọ́bù, ó ní: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.”—Jákọ́bù 1:14, 15; 1 Tímótì 3:6.
Wo àpèjúwe yìí: Ká sọ pé òṣìṣẹ́ báńkì kan ní àǹfààní láti yí àkọsílẹ̀ owó kó bàa lè jí owó gbé ní báńkì. Bí kò bá tètè mú èrò burúkú yìí kúrò lọ́kàn, á wù ú láti gbé owó náà. Tó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó sọ ara rẹ̀ di olè nìyẹn. Tó bá tún purọ́ pé òun kọ́ lòun jí owó náà, ó di òpùrọ́ nìyẹn. Bí ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì tí Ọlọ́run dá yìí ṣe rí gan-an nìyẹn. Ó fẹ́ ohun tí kò tọ́, ó sì ṣe é. Ó lo òmìnira tó ní láti ṣe ohun tó wù ú láti fi hùwà ẹ̀tàn, ó ṣọ̀tẹ̀ sí Bàbá rẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara rẹ̀ di Sátánì Èṣù.
A dúpẹ́ pé, Ọlọ́run yóò pa Sátánì Èṣù run tí àkókò bá tó. (Róòmù 16:20) Kí ìyẹn tó wáyé, Jèhófà Ọlọ́run tí jẹ́ kí àwọn olùjọ́sìn òun mọ àwọn ètekéte Sátánì, ó sì ti dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ètekéte náà. (2 Kọ́ríńtì 2:11; Éfésù 6:11) Nítorí náà, ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti “kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ [rẹ].”—Jákọ́bù 4:7.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]
Áńgẹ́lì pípé tí Ọlọ́run dá sọ ara rẹ̀ di Sátánì nígbà tí ó yàn láti ṣe ohun tí ó ta ko Ọlọ́run