Ṣé Inú Ọkàn Ni Ìjọba Ọlọ́run Wà?
Ṣé Inú Ọkàn Ni Ìjọba Ọlọ́run Wà?
Póòpù Benedict Kẹrìndínlógún sọ nínú ìwé kan tó kọ nípa Jésù, ìyẹn Jesus of Nazareth, ó ní “Ìjọba Ọlọ́run dé sínú ayé ẹnì tó bá gba Jésù tó sì ní ìgbàgbọ́.” Lójú àwọn kan, Ìjọba Ọlọ́run ni àyípadà tó máa ń wáyé ní inú èèyàn lọ́hùn-ún tí ẹni náà bá ti gba Jésù Kristi sínú ayé rẹ̀, tó sì ń mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára. Ṣé àyípadà tí ẹnì kan ṣe ni Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba tó wà ‘nínú ọkàn èèyàn’?
ỌWỌ́ tó ṣe pàtàkì gan-an ni Jésù fi mú ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà. Póòpù Benedict pàápàá gbà pé, Ìjọba yìí ni “ìwàásù Jésù dá lé.” Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àkókò kúkúrú tí Jésù fi ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ló fi rìnrìn àjò káàkiri, tó ń “wàásù ìhìn rere ìjọba náà.” (Mátíù 4:23) Jésù fi hàn kedere nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtàwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe pé, ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà kọjá kéèyàn gba Ọlọ́run gbọ́, kéèyàn sì máa ṣègbọràn sí i. Ó kan ọ̀ràn ìṣàkóso, ìdájọ́ àti ìbùkún tó máa wà títí láé.
Ìṣàkóso àti Ìdájọ́
Lọ́jọ́ kan láàárín àkókò tí Jésù lò kẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, màmá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n sún mọ́ ọn gan-an, ìyẹn Jákọ́bù àti Jòhánù wá sọ́dọ̀ Jésù, ó sọ fún Jésù pé: “Sọ ọ̀rọ̀ náà kí àwọn ọmọkùnrin mi méjì wọ̀nyí lè jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ, nínú ìjọba rẹ.” (Mátíù 20:21) Ó dájú pé, kì í ṣe ohun kan tó wà lọ́kàn àwọn ọmọ rẹ̀ ni obìnrin yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó mọ̀ pé, agbára ìṣàkóso Ìjọba náà wà ní ìkáwọ́ Jésù, ó sì fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ní ìpín nínú rẹ̀. Kódà, Jésù pàápàá ṣèlérí fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ mọ́kànlá pé, wọ́n máa wà nínú Ìjọba òun, tí wọ́n á “jókòó lórí ìtẹ́” wọ́n á sì “ṣèdájọ́” pẹ̀lú òun. (Lúùkù 22:30) Nítorí náà, ó yé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé, Ìjọba Jésù jẹ́ ìṣàkóso gidi, ìyẹn ìjọba kan.
Kí ni òye àwọn èèyàn lórí ọ̀ràn yìí nígbà ayé Jésù? Ǹjẹ́ àyípadà tẹ́nì kan ṣe ni wọ́n lóye pé Ìjọba náà jẹ́ ni àbí wọ́n ń retí ohun míì tó ju ìyẹn lọ? Kété ṣáájú Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jésù gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù, ogunlọ́gọ̀ èèyàn kí i káàbọ̀, àwọn kan sì ń pariwo pé: “Gba Ọmọkùnrin Dáfídì là, ni àwa bẹ̀bẹ̀!” (Mátíù 21:9) Kí nìdí tí wọ́n fi ń pariwo lọ́nà yẹn? Kò sí àní-àní pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n ti mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí àti pé Ọlọ́run máa fún un ní Ìjọba tí kò ní ìpẹ̀kun, ìyẹn “ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀.” Wọ́n ń fẹ́ ìgbàlà, àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo tí Ìjọba yẹn máa mú wá.—Lúùkù 1:32; Sekaráyà 9:9.
Ìbùkún Tó Máa Wà Títí Láé
Àwọn tí kò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù pàápàá gba ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ gbọ́. Nígbà tí wọ́n kan Jésù mọ́gi, ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ bẹ Jésù, ó ní: “Jésù, rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Kí ni ìdáhùn Jésù? Ó ní, “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè,” ó fi ọkùnrin tó ń kú lọ náà lọ́kàn balẹ̀.—Lúùkù 23:42, 43.
Ó dájú pé ọ̀daràn yẹn gbà gbọ́ pé, tí Jésù bá ti jíǹde, ó máa gba Ìjọba kan tàbí wọnú Ìjọba kan. Yàtọ̀ sí pé Jésù láṣẹ láti jí ọkùnrin yìí dìde kó sì tún ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe, pa pọ̀ pẹ̀lú ti ọ̀kẹ́ àìmọye Jòhánù 5:28, 29.
àwọn òkú tó jíǹde, Jésù tún fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí Alákòóso ní ọ̀run, Jésù máa mú ìbùkún tó máa wà títí láé wá fún àwọn èèyàn kárí ayé nípasẹ̀ Ìjọba náà.—Ìjọba Náà Wà Láàárín Wọn
Ṣebí Jésù sọ pé: “Ìjọba Ọlọ́run wà ní àárín yín”? Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí wà nínú Lúùkù 17:21. Kódà, ohun tí Bíbélì míì sọ ni pé, “ijọba Ọlọrun mbẹ ninu nyin.” (Bí àpẹẹrẹ, wo Bibeli Mimọ.) Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ yẹn?
Àyíká ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé, àwùjọ àwọn Farisí alátakò tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ẹ̀sìn Júù ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀. Wọ́n ní èrò tiwọn nípa bí Mèsáyà ṣe máa dé àti Ìjọba rẹ̀. Èrò wọn ni pé, Mèsáyà máa dé “pẹ̀lú àwọsánmà ọ̀run” gẹ́gẹ́ bí Ọba tá a ṣe lógo, láti dá àwọn Júù nídè lọ́wọ́ àwọn ará Róòmù, tó sì máa fìdí ìjọba Ísírẹ́lì múlẹ̀ pa dà. (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Àmọ́, Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ àṣìṣe wọn, ó sọ fún wọn pé: “Ìjọba Ọlọ́run kì yóò wá pẹ̀lú ṣíṣeérí tí ń pàfiyèsí.” Lẹ́yìn náà ló wá sọ ọ̀rọ̀ náà fún wọn pé: “Wò ó! ìjọba Ọlọ́run wà ní àárín yín.”—Lúùkù 17:20, 21.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn nǹkan tí Jésù kọ́ni àtàwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe fi hàn ní kedere pé òun ni Ọba Ìjọba náà, síbẹ̀, ńṣe làwọn Farisí ń ta kò ó nítorí pé wọn kò ní ojúlówó ìgbàgbọ́, èrò wọn kò sì dáa. Wọn kò gbà pé Jésù ni Mèsáyà náà. Ìyẹn ló mú kí Jésù la ọ̀rọ̀ náà mọ́lẹ̀ fún wọn pé: Ìjọba náà ‘wà ní àárín wọn’ nítorí pé, Ọba tí Ọlọ́run yàn láti ṣàkóso ìjọba yẹn wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn. Kò sọ pé kí wọ́n wo inú ọkàn wọn lọ́hùn-ún. * Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dúró níwájú wọn. Ohun tó sọ ni pé, “Ìjọba Ọlọ́run wà níbí pẹ̀lú yín.”—Lúùkù 17:21, Bíbélì Contemporary English Version.
Ìjọba Tó Ṣe Pàtàkì sí Wa
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe ohun tó wà nínú ọkàn àwọn ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀, ó ní láti jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì sí wa. Jésù tipasẹ̀ ẹ̀kọ́ àtàwọn iṣẹ́ agbára tó ṣe mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ní ìgbàgbọ́ àtọkànwá nínú ìṣàkóso òdodo tó máa mú ojúlówó àlàáfíà àti ààbò wá. Ó fẹ́ kí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó máa mú kí ìgbésí ayé wọn túbọ̀ dára sí i. Kódà, ó kọ́ wọn láti máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Ọ̀rọ̀ Jésù wọ ọ̀pọ̀ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ́kàn, wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ tó mú kí wọ́n tẹ̀ lé Jésù tí wọ́n sì ń lépa àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá.
Ṣé o fẹ́ ní irú ìgbàgbọ́ yìí? Kí ló yẹ kó o ṣe kó o lè ní irú ìgbàgbọ́ yìí? Ṣé o rántí ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ Ìwàásù Jésù Lórí Òkè, èyí táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa yẹn? Ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mátíù 5:3) O ò ṣe jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n mú ìwé ìròyìn yìí wá fún ẹ kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe àyípadà tó o ti ṣe nígbèésí ayé rẹ, àmọ́ ó jẹ́ ìṣàkóso òdodo, ìyẹn Ìjọba kan tó máa mú àlàáfíà àti ààbò wá fún gbogbo èèyàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà, “yín” tó wà nínú gbólóhùn náà, “ní àárín yín” jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni púpọ̀ nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, ohun táwọn Bíbélì kan lò nìyẹn, ó sì tọ́ka sí àwọn Farisí tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀. Ó dájú pé, kì í ṣe àyípadà tí àwọn Farisí yẹn ṣe tàbí bí ọkàn wọn ṣe rí ni Jésù ń sọ.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
Ṣé Ìjọba Ọlọ́run wà lọ́kàn àwọn olórí kunkun àti apààyàn tí wọ́n ń ta ko Jésù yẹn?