Gbèjà Ìjọsìn Tòótọ́!
Abala Àwọn Ọ̀dọ́
Gbèjà Ìjọsìn Tòótọ́!
Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Èlíjà, Áhábù àti nǹkan bí àádọ́ta lé nírínwó [450] àwọn wòlíì Báálì
Àkópọ̀: Èlíjà fi hàn pé Jèhófà lágbára ju Báálì lọ.
1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA 1 ÀWỌN ỌBA 18:17-40.
Mú abala ìwé kan, kó o sì ya àwòrán ibi tó o rò pé àwọn èèyàn àtàwọn nǹkan yìí wà síra wọn, ìyẹn ibi tí Èlíjà wà, ibi táwọn wòlíì Báálì wà àti ibi tí àwọn pẹpẹ náà wà.
Ìró wo lò ń “gbọ́” nígbà tí yánpọnyánrin tá a ṣàpèjúwe ní ẹsẹ 26 sí 29 ṣẹlẹ̀?
․․․․․
Kí lo kíyè sí nínú ohùn Èlíjà nígbà tó ń bá àwọn wòlíì Báálì sọ̀rọ̀?
․․․․․
2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.
Kí nìdí tí Èlíjà fi nílò ìgboyà láti bá Áhábù sọ̀rọ̀ àti láti lọ ṣe ìdánwò kan tó máa dójú ti ọgọ́rùn-ún mélòó kan àwọn wòlíì Báálì? (Ojútùú: Ka 1 Àwọn Ọba 18:4, 13, 14.)
․․․․․
Lo àwọn ìwé ìwádìí tó o mọ̀ láti fi ṣèwádìí ohun kan nípa ìjọsìn Báálì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan wo ni wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Báálì? Àkóbá wo ni ìjọsìn Báálì ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì?
․․․․․
Kí lo rò pé ó mú kí Èlíjà wa kòtò yí ká pẹpẹ Jèhófà, tó sì pọn omi kún inú rẹ̀?
․․․․․
3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .
Ìgboyà téèyàn gbọ́dọ̀ ní kéèyàn tó lè gbèjà ìjọsìn tòótọ́.
․․․․․
Àǹfààní tó wà fún àwọn tó ní irú ìgboyà náà.
․․․․․
ÀWỌN OHUN MÍÌ TÓ O LÈ FI ṢÈWÀ HÙ.
Àwọn apá ibo nínú ìgbésí ayé rẹ lo ti lè túbọ̀ fi ìgboyà gbèjà ìjọsìn tòótọ́?
․․․․․
4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?
․․․․․
Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Bíbélì, lórí ìkànnì wa www.watchtower.org ÀTI www.pr418.com